Saamu 148
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
148 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá,
Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.
2 Ẹ fi ìyìn fún un,
gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀
3 Ẹ fi ìyìn fún un,
oòrùn àti òṣùpá
Ẹ fi ìyìn fún un,
gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.
4 Ẹ fi ìyìn fún un,
ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga
àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.
5 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn
6 Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé
ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.
7 Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá
ẹ̀yin ẹ̀dá inú Òkun títóbi
àti ẹ̀yin ibú Òkun
8 Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín
ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,
ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ;
9 Òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèkéé,
igi eléso àti gbogbo igi kedari,
10 Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn
gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́:
11 Àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo
àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,
12 Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin
àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.
13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá
ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run
14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀,
ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli,
àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.