Ìṣe àwọn Aposteli 12:12
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
12 Nígbà tó sì rò ó, ó lọ sí ilé Maria ìyá Johanu, tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku; níbi tí àwọn ènìyàn púpọ̀ péjọ sí, tí wọn ń gbàdúrà.
Read full chapter
Ìṣe àwọn Aposteli 12:25
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
25 Barnaba àti Saulu sì padà wá láti Jerusalẹmu, nígbà ti wọ́n sì parí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn, wọn sì mú Johanu ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku wá pẹ̀lú wọn.
Read full chapter
Ìṣe àwọn Aposteli 13:13
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ní Pisidia ti Antioku
13 Nígbà tí Paulu àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ si ṣíkọ̀ ni Pafosi wọ́n wá sí Perga ni pamfilia: Johanu sì fi wọ́n sílẹ̀, ó sì padà lọ sí Jerusalẹmu.
Read full chapter
Ìṣe àwọn Aposteli 15:37-39
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
37 Barnaba sì pinnu rẹ̀ láti mú Johanu lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku. 38 Ṣùgbọ́n Paulu rò pé, kò yẹ láti mú un lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí ó fi wọn sílẹ̀ ni pamfilia, tí kò sì bá wọn lọ sí iṣẹ́ náà. 39 Ìjà náà sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí wọn ya ara wọn sì méjì: Barnaba sì mu Marku ó tẹ ọkọ́ létí lọ sí Saipurọsi.
Read full chapter
Kolose 4:10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
10 (A)Aristarku, ẹlẹgbẹ́ mí nínú túbú kí i yín, àti Marku, ọmọ arábìnrin Barnaba (Nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ti gba àṣẹ; bí ó bá sì wá sí ọ̀dọ̀ yín, ẹ gbà á).
Read full chapter
Ìṣe àwọn Aposteli 19:29
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
29 Gbogbo ìlú náà sì kún fún ìrúkèrúdò: wọ́n sì fi ọkàn kan rọ́ wọn sí inú ilé ìṣeré, wọ́n sì mú Gaiu àti Aristarku ara Makedonia, àwọn ẹlẹgbẹ́ Paulu nínú ìrìnàjò.
Read full chapter
Ìṣe àwọn Aposteli 27:2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 Nígbà tí a sì wọ ọkọ̀-òkun Adramittiu kan, tí a fẹ́ lọ sí àwọn ìlú ti ó wà létí Òkun Asia, a ṣíkọ̀: Aristarku, ará Makedonia láti Tẹsalonika wà pẹ̀lú wa.
Read full chapter
Kolose 4:10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
10 (A)Aristarku, ẹlẹgbẹ́ mí nínú túbú kí i yín, àti Marku, ọmọ arábìnrin Barnaba (Nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ti gba àṣẹ; bí ó bá sì wá sí ọ̀dọ̀ yín, ẹ gbà á).
Read full chapter
Kolose 4:14
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
14 (A)Luku, arákùnrin wa ọ̀wọ́n, oníṣègùn, àti Dema ki í yín.
Read full chapter
2 Timotiu 4:10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
10 (A)Nítorí Dema ti kọ̀ mí sílẹ̀, nítorí ó ń fẹ́ ayé yìí, ó sì lọ sí Tẹsalonika; Kreskeni sí Galatia, Titu sí Dalimatia.
Read full chapter
Kolose 4:14
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
14 (A)Luku, arákùnrin wa ọ̀wọ́n, oníṣègùn, àti Dema ki í yín.
Read full chapter
2 Timotiu 4:11
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
11 Luku nìkan ni ó wà pẹ̀lú mi, mú Marku wá pẹ̀lú rẹ: nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́ ìránṣẹ́.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.