Add parallel Print Page Options

Àwọn òwe Solomoni

10 Àwọn òwe Solomoni:

    ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùn
    ṣùgbọ́n aṣiwèrè ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́.

Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè
    ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.

Olúwa kì í jẹ́ kí ebi máa pa olódodo
    ṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́.

Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di tálákà,
    ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra ṣíṣẹ́ a máa sọ ni di ọlọ́rọ̀.

Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ,
    ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ.

Ìbùkún ní ó máa ń kún orí olódodo
    ṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú.

Ìrántí olódodo yóò jẹ́ ìbùkún
    ṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà.

Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹ,
    ṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun.

Ẹni tí ó ń rìn déédé, ń rìn láìléwu
    ṣùgbọ́n àṣírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú.

10 Ẹni tí ń ṣẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkàn
    aláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun.

11 Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè
    ṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú.

12 Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀,
    ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.

13 Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóye
    ṣùgbọ́n kùmọ̀ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye.

14 Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọ
    ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun.

15 Ọrọ̀ àwọn olódodo ni ìlú olódi wọn,
    ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní.

16 Èrè olódodo ń mú ìyè wá fún wọn
    ṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn.

17 Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hàn
    ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn ṣìnà.

18 Ẹni tí ó pa ìkórìíra rẹ̀ mọ́ jẹ́ òpùrọ́
    ẹni tí ó sì ń ba ni jẹ́ jẹ́ aláìgbọ́n.

19 Nínú ọ̀rọ̀ púpọ̀ a kò le fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kù
    ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

20 Ètè olódodo jẹ́ ààyò fàdákà
    ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú kò níye lórí.

21 Ètè olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀
    ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ń kú nítorí àìlóye.

22 Ìbùkún Olúwa ń mú ọrọ̀ wá,
    kì í sì í fi ìdààmú sí i.

23 Aláìgbọ́n a máa ní inú dídùn sí ìwà búburú
    ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa ní inú dídùn sí ọgbọ́n.

24 Ohun tí ènìyàn búburú bẹ̀rù yóò dé bá a;
    Olódodo yóò rí ohun tí ó fẹ́ gbà.

25 Nígbà tí ìjì bá ti jà kọjá, ènìyàn búburú a kọjá lọ,
    ṣùgbọ́n Olódodo yóò dúró ṣinṣin láéláé.

26 Bí ọtí kíkan sí eyín, àti èéfín sí ojú
    bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ sí ẹni tí ó rán an níṣẹ́.

27 Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá,
    ṣùgbọ́n a gé ọjọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú.

28 Ìrètí olódodo ni ayọ̀
    ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú jásí òfo.

29 Ọ̀nà Olúwa jẹ́ ààbò fún olódodo,
    ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń ṣe ibi.

30 A kì yóò fa olódodo tu láéláé
    ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kì yóò dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.

31 Ẹnu olódodo ń mú ọgbọ́n jáde wá,
    ṣùgbọ́n ètè àyípadà ni a ó gé kúrò.

32 Ètè olódodo mọ ohun ìtẹ́wọ́gbà,
    ṣùgbọ́n ètè ènìyàn búburú kò mọ̀ ju èké lọ.