Add parallel Print Page Options

11 Olúwa kórìíra òṣùwọ̀n èké,
    ṣùgbọ́n òṣùwọ̀n òtítọ́ jẹ́ inú dídùn un rẹ̀.

Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì dé
    ṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá.

Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀
    ṣùgbọ́n aláìṣòótọ́ yóò parun nípasẹ̀ àìṣòótọ́ wọn.

Ọ̀rọ̀ kò níláárí ní ọjọ́ ìbínú
    ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.

Òdodo aláìlẹ́gàn ṣe ọ̀nà tààrà fún wọn
    ṣùgbọ́n ìwà búburú ènìyàn búburú yóò fà á lulẹ̀.

Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n là
    ṣùgbọ́n ìdẹ̀kùn ètè búburú mú aláìṣòótọ́.

Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parun
    gbogbo ohun tó ń fojú ṣọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já ṣófo.

A gba olódodo kúrò lọ́wọ́ ibi
    dípò o rẹ̀, ibi wá sórí ènìyàn búburú.

Aláìmọ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́,
    ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ olódodo sá àsálà.

10 Nígbà tí olódodo ń gbèrú, ìlú a yọ̀
    nígbà tí ènìyàn búburú parun, ariwo ayọ̀ gba ìlú kan.

11 Nípasẹ̀ ìbùkún, olódodo a gbé ìlú ga:
    ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run.

12 Ẹni tí kò gbọ́n fojú kékeré wo aládùúgbò rẹ̀
    ṣùgbọ́n ẹni tí ó ní òye pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

13 Olófòófó tú àṣírí ìkọ̀kọ̀
    ṣùgbọ́n ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a pa àṣírí mọ́.

14 Nítorí àìní ìtọ́sọ́nà orílẹ̀-èdè ṣubú
    ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn ìṣẹ́gun dájú.

15 Ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ fún àlejò yóò rí ìyọnu,
    ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kọ̀ láti ṣe onígbọ̀wọ́ yóò wà láìléwu.

16 Obìnrin oníwà rere gba ìyìn
    ṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan.

17 Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóore
    ṣùgbọ́n ènìyàn ìkà ń mú ìyọnu wá sórí ara rẹ̀.

18 Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹ
    ṣùgbọ́n ẹni tó fúnrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.

19 Olódodo tòótọ́ rí ìyè
    ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ibi lé e sí ibi ikú ara rẹ̀.

20 Olúwa kórìíra àwọn ènìyàn ọlọ́kàn búburú
    ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn tí ọ̀nà wọn kò lábùkù.

21 Mọ èyí dájú pé: ènìyàn búburú kì yóò lọ láìjìyà,
    ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò lọ láìjìyà.

22 Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀
    ni arẹwà obìnrin tí kò lọ́gbọ́n.

23 Ìfẹ́ inú olódodo yóò yọrí sí ohun rere
    ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú yóò yọrí sí ìbínú.

24 Ènìyàn kan ń fún ni lọ́fẹ̀ẹ́, síbẹ̀ ó ń ní sí i;
    òmíràn ń háwọ́ ju bí ó ti yẹ ṣùgbọ́n ó di aláìní.

25 Ẹni tí ń ṣoore yóò máa gbèrú sí i;
    ẹni tí ó tu ẹlòmíràn lára yóò ní ìtura.

26 Àwọn ènìyàn a ṣẹ́ èpè lé ènìyàn tí ń kó oúnjẹ pamọ́
    ṣùgbọ́n ìbùkún a máa wá sórí ẹni tí ó ṣetán láti tà.

27 Ẹni tí ń lépa ohun rere yóò rí ohun rere
    ṣùgbọ́n ibi yóò dé bá ẹni tí ń lépa ibi.

28 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóò ṣubú;
    ṣùgbọ́n olódodo yóò gbilẹ̀ bí i koríko tútù.

29 Ẹni tí ó ń mú ìdààmú dé bá ìdílé rẹ̀ yóò jogún afẹ́fẹ́ lásán
    aláìgbọ́n yóò sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọlọ́gbọ́n.

30 Èso òdodo ni igi ìyè
    ẹni tí ó sì jèrè ọkàn jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

31 (A)Bí àwọn olódodo bá gba ìpín wọn lórí ilẹ̀ ayé
    mélòó mélòó ni ènìyàn búburú àti àwọn tó dẹ́ṣẹ̀!