Add parallel Print Page Options

13 Ọlọ́gbọ́n ọmọ gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀,
    ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò gbọ́ ìbáwí.

Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ènìyàn ń gbádùn ohun rere
    ṣùgbọ́n, ìfẹ́ ọkàn aláìṣòótọ́ ní ìwà ipá.

Ẹnikẹ́ni tí ó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ pa ẹnu ara rẹ̀ mọ́,
    ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ gbàù gbàù yóò parun.

Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́, ṣùgbọ́n kò rí nǹkan kan,
    ṣùgbọ́n ọkàn àwọn ti kì í ṣe ọ̀lẹ rí ìtẹ́lọ́rùn.

Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́
    Ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú.

Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòtítọ́ inú,
    ṣùgbọ́n ìwà búburú ṣí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ipò.

Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkan kan
    ẹlòmíràn díbọ́n bí i tálákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀
    ṣùgbọ́n tálákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà.

Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro,
    ṣùgbọ́n fìtílà ènìyàn búburú ni a pa kú.

10 Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ ni
    ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.

11 Owó tí a fi ọ̀nà èrú kójọ yóò ṣí lọ,
    ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀díẹ̀ yóò pọ̀ sí i.

12 Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀
    ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè.

13 Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀
    ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀.

14 Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè,
    tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹ̀kùn ikú.

15 Òye pípé ń mú ni rí ojúrere
    Ṣùgbọ́n ọ̀nà aláìṣòótọ́ kì í tọ́jọ́.

16 Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀
    Ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.

17 Ìránṣẹ́ búburú bọ́ sínú ìdààmú
    ṣùgbọ́n aṣojú olóòtítọ́ mú ìwòsàn wá.

18 Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di tálákà yóò sì rí ìtìjú,
    ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá.

19 Ìfẹ́ tí a mú ṣẹ dùn mọ́ ọkàn
    ṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi.

20 Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n
    ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára.

21 Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀,
    ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo.

22 Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,
    ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.

23 Ilẹ̀ ẹ tálákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìre oko wá
    ṣùgbọ́n àìṣòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ.

24 Ẹni tí ó fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀
    ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóò máa bá a wí.

25 Olódodo jẹ́wọ́ títí ó fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn
    ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ikùn ènìyàn búburú.