Add parallel Print Page Options

19 Ó sàn kí ènìyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà.

Kò dára láti ní ìtara láìní ìmọ̀ tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì ṣìnà.

Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnrarẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run;
    síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí Olúwa.

Ọrọ̀ máa ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀;
    ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ tálákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà, ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́.

Ọ̀pọ̀ ń wá ojúrere olórí;
    gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́.

Gbogbo ará ilé e tálákà ni ó pa á tì
    mélòó mélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un!
    Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀,
    kò tilẹ̀ le rí wọn rárá.

Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀;
    ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú.

Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyà
    ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun.

10 Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọláńlá,
    mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jẹ ọba lórí ọmọ-aládé.

11 Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní sùúrù;
    fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.

12 Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún,
    ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko.

13 Aṣiwèrè ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀,
    Aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò.

14 A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbí
    ṣùgbọ́n aya olóye láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni.

15 Ọ̀lẹ ṣíṣe máa ń fa oorun sísùn fọnfọn,
    ebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra.

16 Ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́
    ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.

17 Ẹni tí ó ṣàánú tálákà, Olúwa ní ó yá
    yóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe.

18 Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà;
    àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú ìparun un rẹ̀.

19 Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀
    bí ìwọ bá gbà á là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i.

20 Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́
    ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.

21 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyàn
    ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa ní ó máa ń borí.

22 Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀;
    ó sàn láti jẹ́ tálákà ju òpùrọ́ lọ.

23 Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ìyè wá:
    nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láìsí ewu.

24 Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ;
    kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.

25 Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n;
    bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ sí i.

26 Ẹni tí ó ṣìkà sí baba rẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde
òun ni ọmọ tí ń ṣe ìtìjú, tí ó sì mú ẹ̀gàn wá.

27 Ọmọ mi, dẹ́kun láti tẹ́tí sí ẹ̀kọ́,
    tí í mú ni ṣìnà kúrò nínú ọ̀rọ̀-ìmọ̀.

28 Ẹlẹ́rìí búburú fi ìdájọ́ ṣẹ̀sín,
    ẹnu ènìyàn búburú sì ń gbé ibi mì.

29 A ti pèsè ìjìyà sílẹ̀ fún ẹlẹ́gàn;
    àti pàṣán fún ẹ̀yìn àwọn aṣiwèrè.