Add parallel Print Page Options

Dafidi pàṣẹ fún Solomoni

Nígbà tí ọjọ́ ikú Dafidi súnmọ́ etílé, ó pàṣẹ fún Solomoni ọmọ rẹ̀.

Ó sì wí pé, “Èmi ti fẹ́ lọ sí ọ̀nà gbogbo ayé, nítorí náà jẹ́ alágbára kí o sì fi ara rẹ hàn bí ọkùnrin, kí o sì wòye ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè, rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí o sì pa àṣẹ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti ìdájọ́ rẹ, àti ẹ̀rí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé òfin Mose, nítorí kí ìwọ kí ó le è máa ṣe rere ní ohun gbogbo tí ìwọ ṣe, àti ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, Olúwa kí ó lè pa ìlérí rẹ̀ tí ó sọ nípa tèmi mọ́ pé: ‘Bí àwọn ọmọ rẹ bá kíyèsi ọ̀nà wọn, tí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà wọn àti ọkàn wọn rìn níwájú mi ní òtítọ́, o kì yóò sì kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Israẹli.’

“Ìwọ pẹ̀lú sì mọ ohun tí Joabu ọmọ Seruiah ṣe sí mi àti ohun tí ó ṣe sí Balógun méjì nínú àwọn ológun Israẹli, sí Abneri ọmọ Neri àti sí Amasa ọmọ Jeteri. Ó sì pa wọ́n, ó sì ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ ní ìgbà àlàáfíà bí í ti ojú ogun ó sì fi ẹ̀jẹ̀ náà sí ara àmùrè rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àti sí ara Sálúbàtà rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹsẹ̀ rẹ̀. Ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n rẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú ní àlàáfíà.

“Ṣùgbọ́n fi inú rere hàn sí àwọn ọmọ Barsillai, ti Gileadi, jẹ́ kí wọn wà lára àwọn tí ó ń jẹun lórí tábìlì rẹ̀. Wọ́n dúró tì mí nígbà tí mo sá kúrò níwájú Absalomu arákùnrin rẹ.

“Àti kí o rántí, Ṣimei ọmọ Gera ẹ̀yà Benjamini tí Bahurimu wà pẹ̀lú rẹ̀, tí ó bú mi ní èébú tí ó korò ní ọjọ́ tí mo lọ sí Mahanaimu. Nígbà tí ó sọ̀kalẹ̀ wá pàdé mi ní Jordani, mo fi Olúwa búra fún un pé: ‘Èmi kì yóò fi idà pa ọ́.’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, má ṣe kíyèsi í gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin ọlọ́gbọ́n ni ìwọ ṣe; ìwọ yóò mọ ohun tí ìwọ yóò ṣe sí i. Mú ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sínú isà òkú pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.”

10 Nígbà náà ni Dafidi sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi. 11 Dafidi ti jẹ ọba lórí Israẹli ní ogójì ọdún (40), ọdún méje (7) ni Hebroni àti ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) ní Jerusalẹmu. 12 (A)Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì fi ìdí múlẹ̀ gidigidi.

Ìtẹ́ ọba Solomoni fìdímúlẹ̀

13 Wàyí, Adonijah ọmọ Haggiti tọ Batṣeba, ìyá Solomoni wá. Batṣeba sì bi í pé, “Àlàáfíà ni o bá wa bí?”

Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni.” 14 Nígbà náà ni ó sì fi kún un pé, “Mo ní ohun kan láti sọ fún ọ.”

Batṣeba sì wí pé, “Máa wí.”

15 Ó wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀, ti tèmi ni ìjọba náà. Gbogbo Israẹli ti wò mí bí ọba wọn. Ṣùgbọ́n nǹkan yípadà, ìjọba náà sì ti lọ sí ọ̀dọ̀ arákùnrin mi, nítorí ó ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọwọ́ Olúwa wá. 16 Nísinsin yìí mo ní ìbéèrè kan láti bi ọ́, má ṣe kọ̀ fún mi.”

Ó wí pé, “O lè wí.”

17 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ̀síwájú pé, “Mo bẹ̀ ọ́, jọ̀wọ́ sọ fún Solomoni ọba (Òun kì yóò kọ̀ fún ọ́) kí ó fún mi ní Abiṣagi ará Ṣunemu ní aya.”

18 Batṣeba sì dáhùn pé, “Ó dára èmi yóò bá ọba sọ̀rọ̀ nítorí rẹ̀.”

19 Nígbà tí Batṣeba sì tọ Solomoni ọba lọ láti bá a sọ̀rọ̀ nítorí Adonijah, ọba sì dìde láti pàdé rẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó sì tẹ́ ìtẹ́ kan fún ìyá ọba, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀.

20 Ó sì wí pé, “Mo ní ìbéèrè kékeré kan láti béèrè lọ́wọ́ rẹ, má ṣe kọ̀ fún mi.”

Ọba sì dáhùn wí pé, “Béèrè, ìyá mi; Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.”

21 Nígbà náà ni ó wí pé, “Jẹ́ kí a fi Abiṣagi ará Ṣunemu fún Adonijah arákùnrin rẹ ní aya.”

22 Solomoni ọba sì dá ìyá rẹ̀ lóhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ fi béèrè Abiṣagi ará Ṣunemu fún Adonijah! Ìwọ ìbá sì béèrè ìjọba fún un pẹ̀lú nítorí ẹ̀gbọ́n mi ní í ṣe, fún òun pàápàá àti fún Abiatari àlùfáà àti fun Joabu ọmọ Seruiah!”

23 Nígbà náà ni Solomoni ọba fi Olúwa búra pé: “Kí Ọlọ́run ki ó jẹ mí ní yà, àti jù bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, bí Adonijah kò bá ní fi ẹ̀mí rẹ̀ san ìbéèrè yìí! 24 Àti nísinsin yìí, bí ó ti dájú pé Olúwa wà láààyè, ẹni tí ó ti mú mi jókòó lórí ìtẹ́ baba mi Dafidi, àti tí ó sì ti kọ́ ilé fún mi bí ó ti ṣèlérí, lónìí ni a ó pa Adonijah!” 25 Solomoni ọba sì pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada, ó sì kọlu Adonijah, ó sì kú.

26 Ọba sì wí fún Abiatari àlùfáà pé, “Padà lọ sí pápá rẹ ni Anatoti, ó yẹ fún ọ láti kú, ṣùgbọ́n èmi kì yóò pa ọ́ nísinsin yìí, nítorí o ti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa Olódùmarè níwájú Dafidi baba mi, o sì ti ní ìpín nínú gbogbo ìyà tí baba mi jẹ.” 27 Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni yọ Abiatari kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà Olúwa, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípa ilé Eli ní Ṣilo ṣẹ.

28 Nígbà tí ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Joabu, ẹni tí ó ti dìtẹ̀ pẹ̀lú Adonijah bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wà pẹ̀lú Absalomu, ó sì sálọ sínú àgọ́ Olúwa, ó sì di ìwo pẹpẹ mú. 29 A sì sọ fún Solomoni ọba pé Joabu ti sálọ sínú àgọ́ Olúwa àti pé ó wà ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. Nígbà náà ni Solomoni pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada pé, “Lọ, kí o sì kọlù ú.”

30 Benaiah sì wọ inú àgọ́ Olúwa, ó sì wí fún Joabu pé, “ọba sọ wí pé, Jáde wá.”

Ṣùgbọ́n ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Èmi yóò kú níhìn-ín.”

Benaiah sì mú èsì fún ọba, “Báyìí ni Joabu ṣe dá mi lóhùn.”

31 Ọba sì pàṣẹ fún Benaiah pé, “Ṣe bí ó ti wí. Kọlù ú, kí o sì sin ín, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi àti kúrò lọ́dọ̀ ilé baba mi, tí Joabu ti ta sílẹ̀. 32 Olúwa yóò sì san ẹ̀jẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀ padà fún un, nítorí tí ó kọlu ọkùnrin méjì, ó sì fi idà rẹ̀ pa wọ́n, Dafidi baba mi kò sì mọ̀. Àwọn méjèèjì ni Abneri ọmọ Neri olórí ogun Israẹli, àti Amasa ọmọ Jeteri olórí ogun Juda, wọ́n jẹ́ olódodo, wọ́n sì sàn ju òun fúnrarẹ̀ lọ. 33 Kí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn wá sórí Joabu àti sórí irú-ọmọ rẹ̀ títí láé. Ṣùgbọ́n sórí Dafidi àti irú-ọmọ rẹ̀, sí ilé rẹ̀ àti sí ìtẹ́ rẹ̀, ni kí àlàáfíà Olúwa wà títí láé.”

34 Bẹ́ẹ̀ ni Benaiah ọmọ Jehoiada sì gòkè lọ, ó sì kọlu Joabu, ó sì pa á, a sì sin ín ní ilẹ̀ ibojì ara rẹ̀ ní aginjù. 35 Ọba sì fi Benaiah ọmọ Jehoiada jẹ olórí ogun ní ipò Joabu àti Sadoku àlùfáà ní ipò Abiatari.

36 Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ sí Ṣimei, ó sì wí fún un pé, “Kọ́ ilé fún ara rẹ ní Jerusalẹmu, kí o sì máa gbé ibẹ̀, ṣùgbọ́n kí o má sì ṣe lọ sí ibòmíràn. 37 Ọjọ́ tí ìwọ bá jáde, tí o sì kọjá Àfonífojì Kidironi, kí ìwọ kí ó mọ̀ dájúdájú pé ìwọ yóò kú; ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wà lórí ara rẹ.”

38 Ṣimei sì dá ọba lóhùn pé, “Ohun tí ìwọ sọ dára. Ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe bí olúwa mi ọba ti wí.” Ṣimei sì gbé ní Jerusalẹmu fún ìgbà pípẹ́.

39 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Ṣimei méjì sì sálọ sọ́dọ̀ Akiṣi ọmọ Maaka, ọba Gati, a sì sọ fún Ṣimei pé, “Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ méjì wà ní Gati.” 40 Fún ìdí èyí, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi ní Gati láti wá àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Ṣimei sì lọ, ó sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ padà bọ̀ láti Gati.

41 Nígbà tí a sì sọ fún Solomoni pé Ṣimei ti lọ láti Jerusalẹmu sí Gati, ó sì ti padà, 42 Ọba pe Ṣimei lẹ́jọ́, ó wí fún un pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ti mú ọ búra ní ti Olúwa, èmi sì ti kìlọ̀ fún ọ pé, ‘Ní ọjọ́ tí ìwọ bá kúrò láti lọ sí ibikíbi, kí o mọ̀ dájú pé ìwọ yóò kú’ Nígbà náà ni ìwọ sì sọ fún mi pé, ‘Ohun tí ìwọ sọ dára. Èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn.’ 43 Èéṣe, nígbà náà tí ìwọ kò pa ìbúra Olúwa mọ́, àti kí o sì ṣe ìgbọ́ràn sí àṣẹ tí mo pa fún ọ?”

44 Ọba sì tún wí fún Ṣimei pé, “Ìwọ mọ̀ ní ọkàn rẹ gbogbo búburú tí ìwọ ti ṣe sí Dafidi baba mi. Báyìí, Olúwa yóò san gbogbo ìṣe búburú rẹ padà fún ọ. 45 Ṣùgbọ́n a ó sì bùkún fún Solomoni ọba, ìtẹ́ Dafidi yóò sì wà láìfòyà níwájú Olúwa títí láéláé.”

46 Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada, ó sì jáde lọ, ó sì kọlu Ṣimei, ó sì pa á.

Ìjọba náà sì wá fi ìdí múlẹ̀ ní ọwọ́ Solomoni.

David’s Charge to Solomon(A)

When the time drew near for David to die,(B) he gave a charge to Solomon his son.

“I am about to go the way of all the earth,”(C) he said. “So be strong,(D) act like a man, and observe(E) what the Lord your God requires: Walk in obedience to him, and keep his decrees and commands, his laws and regulations, as written in the Law of Moses. Do this so that you may prosper(F) in all you do and wherever you go and that the Lord may keep his promise(G) to me: ‘If your descendants watch how they live, and if they walk faithfully(H) before me with all their heart and soul, you will never fail to have a successor on the throne of Israel.’

“Now you yourself know what Joab(I) son of Zeruiah did to me—what he did to the two commanders of Israel’s armies, Abner(J) son of Ner and Amasa(K) son of Jether. He killed them, shedding their blood in peacetime as if in battle, and with that blood he stained the belt around his waist and the sandals on his feet. Deal with him according to your wisdom,(L) but do not let his gray head go down to the grave in peace.

“But show kindness(M) to the sons of Barzillai(N) of Gilead and let them be among those who eat at your table.(O) They stood by me when I fled from your brother Absalom.

“And remember, you have with you Shimei(P) son of Gera, the Benjamite from Bahurim, who called down bitter curses on me the day I went to Mahanaim.(Q) When he came down to meet me at the Jordan, I swore(R) to him by the Lord: ‘I will not put you to death by the sword.’ But now, do not consider him innocent. You are a man of wisdom;(S) you will know what to do to him. Bring his gray head down to the grave in blood.”

10 Then David rested with his ancestors and was buried(T) in the City of David.(U) 11 He had reigned(V) forty years over Israel—seven years in Hebron and thirty-three in Jerusalem. 12 So Solomon sat on the throne(W) of his father David, and his rule was firmly established.(X)

Solomon’s Throne Established

13 Now Adonijah,(Y) the son of Haggith, went to Bathsheba, Solomon’s mother. Bathsheba asked him, “Do you come peacefully?”(Z)

He answered, “Yes, peacefully.” 14 Then he added, “I have something to say to you.”

“You may say it,” she replied.

15 “As you know,” he said, “the kingdom was mine. All Israel looked to me as their king. But things changed, and the kingdom has gone to my brother; for it has come to him from the Lord. 16 Now I have one request to make of you. Do not refuse me.”

“You may make it,” she said.

17 So he continued, “Please ask King Solomon—he will not refuse you—to give me Abishag(AA) the Shunammite as my wife.”

18 “Very well,” Bathsheba replied, “I will speak to the king for you.”

19 When Bathsheba went to King Solomon to speak to him for Adonijah, the king stood up to meet her, bowed down to her and sat down on his throne. He had a throne brought for the king’s mother,(AB) and she sat down at his right hand.(AC)

20 “I have one small request to make of you,” she said. “Do not refuse me.”

The king replied, “Make it, my mother; I will not refuse you.”

21 So she said, “Let Abishag(AD) the Shunammite be given in marriage to your brother Adonijah.”

22 King Solomon answered his mother, “Why do you request Abishag(AE) the Shunammite for Adonijah? You might as well request the kingdom for him—after all, he is my older brother(AF)—yes, for him and for Abiathar(AG) the priest and Joab son of Zeruiah!”

23 Then King Solomon swore by the Lord: “May God deal with me, be it ever so severely,(AH) if Adonijah does not pay with his life for this request! 24 And now, as surely as the Lord lives—he who has established me securely on the throne of my father David and has founded a dynasty for me as he promised(AI)—Adonijah shall be put to death today!” 25 So King Solomon gave orders to Benaiah(AJ) son of Jehoiada, and he struck down Adonijah and he died.(AK)

26 To Abiathar(AL) the priest the king said, “Go back to your fields in Anathoth.(AM) You deserve to die, but I will not put you to death now, because you carried the ark(AN) of the Sovereign Lord before my father David and shared all my father’s hardships.”(AO) 27 So Solomon removed Abiathar from the priesthood of the Lord, fulfilling(AP) the word the Lord had spoken at Shiloh about the house of Eli.

28 When the news reached Joab, who had conspired with Adonijah though not with Absalom, he fled to the tent of the Lord and took hold of the horns(AQ) of the altar. 29 King Solomon was told that Joab had fled to the tent of the Lord and was beside the altar.(AR) Then Solomon ordered Benaiah(AS) son of Jehoiada, “Go, strike him down!”

30 So Benaiah entered the tent(AT) of the Lord and said to Joab, “The king says, ‘Come out!(AU)’”

But he answered, “No, I will die here.”

Benaiah reported to the king, “This is how Joab answered me.”

31 Then the king commanded Benaiah, “Do as he says. Strike him down and bury him, and so clear me and my whole family of the guilt of the innocent blood(AV) that Joab shed. 32 The Lord will repay(AW) him for the blood he shed,(AX) because without my father David knowing it he attacked two men and killed them with the sword. Both of them—Abner son of Ner, commander of Israel’s army, and Amasa(AY) son of Jether, commander of Judah’s army—were better(AZ) men and more upright than he. 33 May the guilt of their blood rest on the head of Joab and his descendants forever. But on David and his descendants, his house and his throne, may there be the Lord’s peace forever.”

34 So Benaiah(BA) son of Jehoiada went up and struck down Joab(BB) and killed him, and he was buried at his home out in the country. 35 The king put Benaiah(BC) son of Jehoiada over the army in Joab’s position and replaced Abiathar with Zadok(BD) the priest.

36 Then the king sent for Shimei(BE) and said to him, “Build yourself a house in Jerusalem and live there, but do not go anywhere else. 37 The day you leave and cross the Kidron Valley,(BF) you can be sure you will die; your blood will be on your own head.”(BG)

38 Shimei answered the king, “What you say is good. Your servant will do as my lord the king has said.” And Shimei stayed in Jerusalem for a long time.

39 But three years later, two of Shimei’s slaves ran off to Achish(BH) son of Maakah, king of Gath, and Shimei was told, “Your slaves are in Gath.” 40 At this, he saddled his donkey and went to Achish at Gath in search of his slaves. So Shimei went away and brought the slaves back from Gath.

41 When Solomon was told that Shimei had gone from Jerusalem to Gath and had returned, 42 the king summoned Shimei and said to him, “Did I not make you swear by the Lord and warn(BI) you, ‘On the day you leave to go anywhere else, you can be sure you will die’? At that time you said to me, ‘What you say is good. I will obey.’ 43 Why then did you not keep your oath to the Lord and obey the command I gave you?”

44 The king also said to Shimei, “You know in your heart all the wrong(BJ) you did to my father David. Now the Lord will repay you for your wrongdoing. 45 But King Solomon will be blessed, and David’s throne will remain secure(BK) before the Lord forever.”

46 Then the king gave the order to Benaiah(BL) son of Jehoiada, and he went out and struck Shimei(BM) down and he died.

The kingdom was now established(BN) in Solomon’s hands.