Add parallel Print Page Options

Solomoni kọ́ ilé náà

(A)Ní ìgbà tí ó pe ọ̀rìnlénírinwó ọdún (480) lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ní ọdún kẹrin ìjọba Solomoni lórí Israẹli, ní oṣù Sifi, tí ń ṣe oṣù kejì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé Olúwa.

Ilé náà tí Solomoni ọba kọ́ fún Olúwa sì jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gíga. Ìloro níwájú tẹmpili ilé náà, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rẹ̀, ìbú ilé náà, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti iwájú ilé náà. Ó sì ṣe fèrèsé tí kò fẹ̀ fún ilé náà. Lára ògiri ilé náà ni ó bu yàrá yíká; àti tẹmpili àti ibi mímọ́ jùlọ ni ó sì ṣe yàrá yíká. Yàrá ìsàlẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ìbú, ti àárín sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní ìbú, àti ẹ̀kẹta ìgbọ̀nwọ́ méje sì ni ìbú rẹ̀. Nítorí lóde ilé náà ni ó dín ìgbọ̀nwọ́ kọ̀ọ̀kan káàkiri, kí igi àjà kí ó má ba à wọ inú ògiri ilé náà.

Ní kíkọ́ ilé náà, òkúta tí a ti gbẹ́ sílẹ̀ kí a tó mú un wá ibẹ̀ nìkan ni a lò, a kò sì gbúròó òòlù tàbí àáké tàbí ohun èlò irin kan nígbà tí a ń kọ́ ọ lọ́wọ́.

Ẹnu-ọ̀nà yàrá ìsàlẹ̀ sì wà ní ìhà gúúsù ilé náà; wọ́n sì fi àtẹ̀gùn tí ó lórí gòkè sínú yàrá àárín, àti láti yàrá àárín bọ́ sínú ẹ̀kẹta. Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ́ ilé náà, ó sì parí rẹ̀, ó sì bo ilé náà pẹ̀lú àwọn ìtí igi àti pákó kedari. 10 Ó sì kọ́ yàrá ẹ̀gbẹ́ sí gbogbo ilé náà. Gígùn ọ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, ó sì so wọ́n mọ́ ilé náà pẹ̀lú ìtì igi kedari.

11 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Solomoni wá wí pé: 12 “Ní ti ilé yìí tí ìwọ ń kọ́ lọ́wọ́, bí ìwọ bá tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ìwọ sì ṣe ìdájọ́ mi, tí o sì pa òfin mi mọ́ láti máa ṣe wọ́n, Èmi yóò mú ìlérí tí mo ti ṣe fún Dafidi baba rẹ̀ ṣẹ nípa rẹ̀. 13 Èmi yóò sì máa gbé àárín àwọn ọmọ Israẹli, èmi kì ó sì kọ Israẹli ènìyàn mi.”

14 Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni kọ́ ilé náà, ó sì parí rẹ̀. 15 Ó sì fi pákó kedari tẹ́ ògiri ilé náà nínú, láti ilẹ̀ ilé náà dé àjà rẹ̀, ó fi igi bò wọ́n nínú, ó sì fi pákó firi tẹ́ ilẹ̀ ilé náà. 16 Ó pín ogún ìgbọ̀nwọ́ sí ẹ̀yìn ilé náà, láti ilẹ̀ dé àjà ilé ni ó fi pákó kedari kọ́, èyí ni ó kọ sínú, fún ibi tí a yà sí mímọ́ àní ibi mímọ́ jùlọ. 17 Ní iwájú ilé náà, ogójì (40) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn rẹ̀ jẹ́. 18 Inú ilé náà sì jẹ́ kedari, wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà rẹ̀ pẹ̀lú ìrudí àti ìtànná. Gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ kedari; a kò sì rí òkúta kan níbẹ̀.

19 Ó sì múra ibi mímọ́ jùlọ sílẹ̀ nínú ilé náà láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa ka ibẹ̀. 20 Inú ibi mímọ́ náà sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú, àti ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gíga. Ó sì fi kìkì wúrà bo inú rẹ̀ ó sì fi igi kedari bo pẹpẹ rẹ̀. 21 Solomoni sì fi kìkì wúrà bo inú ilé náà, ó sì tan ẹ̀wọ̀n wúrà dé ojú ibi mímọ́ jùlọ, ó sì fi wúrà bò ó. 22 Gbogbo ilé náà ni ó fi wúrà bò títí ó fi parí gbogbo ilé náà, àti gbogbo pẹpẹ tí ó wà níhà ibi mímọ́ jùlọ, ni ó fi wúrà bò.

23 Ní inú ibi mímọ́ jùlọ ni ó fi igi olifi ṣe kérúbù méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gíga. 24 Apá kérúbù kìn-ín-ní sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga, àti apá kérúbù kejì ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún; ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti ṣóńṣó apá kan dé ṣóńṣó apá kejì. 25 Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá sì ni kérúbù kejì pẹ̀lú, nítorí kérúbù méjèèjì jọ ara wọn ní ìwọ̀n ní títóbi àti títẹ̀wọ̀n bákan náà. 26 Gíga kérúbù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá. 27 Ó sì gbé àwọn kérúbù náà sínú ilé ti inú lọ́hùn ún, pẹ̀lú ìyẹ́ apá wọn ní nínà jáde. Ìyẹ́ apá kérúbù kan sì kan ògiri kan, nígbà tí ìyẹ́ apá èkejì sì kan ògiri kejì, ìyẹ́ apá wọn sì kan ara wọn láàrín yàrá náà. 28 Ó sì fi wúrà bo àwọn kérúbù náà.

29 Lára àwọn ògiri tí ó yí ilé náà ká, nínú àti lóde, ó sì ya àwòrán àwọn kérúbù sí i àti ti igi ọ̀pẹ, àti ti ìtànná ewéko. 30 Ó sì tún fi wúrà tẹ́ ilẹ̀ ilé náà nínú àti lóde.

31 Nítorí ojú ọ̀nà ibi mímọ́ jùlọ ni ó ṣe ìlẹ̀kùn igi olifi sí pẹ̀lú àtẹ́rígbà àti òpó ìhà jẹ́ ìdámárùn-ún ògiri. 32 Àti lára ìlẹ̀kùn igi olifi náà ni ó ya àwòrán àwọn kérúbù, igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí, ó sì fi wúrà bò wọ́n, ó sì tan wúrà sí ara àwọn kérúbù àti sí ara igi ọ̀pẹ. 33 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe òpó igi olifi onígun mẹ́rin fún ìlẹ̀kùn ilé náà. 34 Ó sì tún fi igi firi ṣe ìlẹ̀kùn méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ewé méjì tí ó yí sí ihò ìtẹ̀bọ̀. 35 Ó sì ya àwòrán kérúbù, àti ti igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí ara wọn, ó sì fi wúrà bò ó, èyí tí ó tẹ́ sórí ibi tí ó gbẹ́.

36 Ó sì fi ẹsẹẹsẹ òkúta mẹ́ta gbígbẹ, àti ẹsẹ̀ kan ìtí kedari kọ́ àgbàlá ti inú lọ́hùn ún.

37 Ní ọdún kẹrin ni a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lé ilẹ̀, ní oṣù Sifi. 38 Ní ọdún kọkànlá ní oṣù Bulu, oṣù kẹjọ, a sì parí ilé náà jálẹ̀ jálẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìpín rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó yẹ. Ó sì lo ọdún méje ní kíkọ́ ilé náà.

Solomoni kọ́ ààfin rẹ̀

Solomoni sì lo ọdún mẹ́tàlá láti fi kọ́ ààfin rẹ̀, ó sì parí gbogbo iṣẹ́ ààfin rẹ̀. Ó kọ́ ilé igbó Lebanoni pẹ̀lú; gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́, àti àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú rẹ̀ àti gíga rẹ̀ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́; pẹ̀lú ọwọ́ mẹ́rin igi kedari, àti ìdábùú igi kedari lórí òpó náà. A sì fi igi kedari tẹ́ ẹ lókè lórí yàrá tí ó jókòó lórí ọ̀wọ́n márùnlélógójì, mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní ọ̀wọ́. Fèrèsé rẹ̀ ni a gbé sókè ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, kọjú sí ara wọn. Gbogbo ìlẹ̀kùn àti òpó sì dọ́gba ní igun mẹ́rin: wọ́n sì wà ní apá iwájú ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, wọ́n kọjú sí ara wọn.

Ó sì fi ọ̀wọ́n ṣe gbàngàn ìdájọ́: àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn rẹ̀, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́. Ìloro kan sì wà níwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ́n àti ìbòrí ìgúnwà níwájú wọn.

Ó sì ṣe gbàngàn ìtẹ́, gbàngàn ìdájọ́, níbi tí yóò ti ṣe ìdájọ́, ó sì fi igi kedari bò ó láti ilẹ̀ dé àjà ilé. Ààfin rẹ̀ níbi tí yóò sì gbé wà ní àgbàlá lẹ́yìn ààfin, irú kan náà ni wọ́n. Solomoni sì kọ́ ààfin tí ó rí bí gbàngàn yìí fún ọmọbìnrin Farao tí ó ní ní aya.

Gbogbo wọ̀nyí láti òde dé apá àgbàlá ńlá, àti láti ìpìlẹ̀ dé ìbòrí òkè ilé, wọ́n sì jẹ́ òkúta iyebíye gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n òkúta gbígbẹ, tí a fi ayùn rẹ́ nínú àti lóde. 10 Ìpìlẹ̀ náà jẹ́ òkúta iyebíye, àní òkúta ńláńlá, àwọn mìíràn wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, àwọn mìíràn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ. 11 Lókè ni òkúta iyebíye wà nípa ìwọ̀n òkúta tí a gbẹ́ àti igi kedari. 12 Àgbàlá ńlá náà yíkákiri ògiri pẹ̀lú ọ̀wọ́ mẹ́ta òkúta gbígbẹ́ àti ọ̀wọ́n kan igi ìdábùú ti kedari, bí ti inú lọ́hùn ún àgbàlá ilé Olúwa pẹ̀lú ìloro rẹ̀.

Ọ̀ṣọ́ tẹmpili

13 Solomoni ọba ránṣẹ́ sí Tire, ó sì mú Hiramu wá, 14 ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ opó láti inú ẹ̀yà Naftali àti tí baba rẹ̀ sì ṣe ará Tire, alágbẹ̀dẹ idẹ. Hiramu sì kún fún ọgbọ́n àti òye, àti ìmọ̀ láti ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ idẹ. Ó wá sọ́dọ̀ Solomoni ọba, ó sì ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un.

15 (B)Ó sì dá ọ̀wọ́n idẹ méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì-dínlógún ní gíga okùn ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ni ó sì yí wọn ká. 16 Ó sì túnṣe ìparí méjì ti idẹ dídá láti fi sókè àwọn ọ̀wọ́n náà, ìparí kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga. 17 Onírúurú iṣẹ́, àti ohun híhun ẹ̀wọ̀n fún àwọn ìparí tí ń bẹ lórí àwọn ọ̀wọ́n náà, méje fún ìparí kọ̀ọ̀kan. 18 Ó sì ṣe àwọn pomegiranate ní ọ̀wọ́ méjì yíkákiri lára iṣẹ́ ọ̀wọ́n náà, láti fi bo àwọn ìparí ti ń bẹ lókè, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìparí kejì. 19 Àwọn ìparí tí ń bẹ ní òkè àwọn ọ̀wọ́n náà tí ń bẹ ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ náà dàbí àwòrán lílì, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gíga. 20 Lórí àwọn ìparí ọ̀wọ́n méjì náà lókè, wọ́n sì súnmọ́ ibi tí ó yẹ lára ọ̀wọ́n tí ó wà níbi iṣẹ́ ọ̀wọ́n, wọ́n sì jẹ́ igba (200) pomegiranate ní ọ̀wọ́ yíkákiri. 21 Ó sì gbé àwọn ọ̀wọn náà ró ní ìloro tẹmpili, ó sì pe orúkọ ọ̀wọ́n tí ó wà ní gúúsù ní Jakini àti èyí tí ó wà ní àríwá ní Boasi. 22 Àwọn ìparí lókè sì jẹ́ àwòrán lílì. Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ ti àwọn ọ̀wọ́n sì parí.

23 (C)Ó sì ṣe agbádá dídá, ó ṣe bíríkítí, ó wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti etí kan dé èkejì àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga rẹ̀. Ó sì gba okùn ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ láti wọ́n yí i ká. 24 Ní ìsàlẹ̀ etí rẹ̀, kókó wá yí i ká, mẹ́wàá nínú ìgbọ̀nwọ́ kan. Ó yí agbádá náà káàkiri, a dá kókó náà ní ọ̀wọ́ méjì, nígbà tí a dá a.

25 Ó sì dúró lórí màlúù méjìlá, mẹ́ta kọjú sí àríwá, mẹ́ta sì kọjú sí ìwọ̀-oòrùn, mẹ́ta kọjú sí gúúsù, mẹ́ta sì kọjú sí ìlà-oòrùn. Agbada náà sì jókòó lórí wọn, gbogbo apá ẹ̀yìn wọn sì ń bẹ nínú. 26 Ó sì nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dàbí etí ago, bí ìtànná lílì. Ó sì gba ẹgbàá (2,000) ìwọ̀n bati.

27 Ó sì túnṣe ẹsẹ̀ idẹ tí a lè gbé mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní ìbú àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gíga. 28 Báyìí ni a sì ṣe ẹsẹ̀ náà: Wọ́n ní àlàfo ọnà àárín tí a so mọ́ agbede-méjì ìpàdé etí. 29 Lórí àlàfo ọnà àárín tí ó wà lágbedeméjì ni àwòrán kìnnìún, màlúù, àti àwọn kérúbù wà, àti lórí ìpàdé etí bákan náà. Lókè àti nísàlẹ̀ àwọn kìnnìún, màlúù sì ni iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ wà. 30 Ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì ni kẹ̀kẹ́ idẹ mẹ́rin pẹ̀lú ọ̀pá kẹ̀kẹ́ idẹ, ọ̀kọ̀ọ̀kan ni ó ní ìfẹsẹ̀tẹ̀ lábẹ́, tí a gbẹ́, iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ wà ní ìhà gbogbo rẹ̀. 31 Nínú ẹsẹ̀ náà ẹnu kan wà tí ó kọ bíríkítí tí ó jìn ní ìgbọ̀nwọ́ kan. Ẹnu yìí ṣe róbótó àti pẹ̀lú iṣẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀. Ní àyíká ẹnu rẹ̀ ni ohun ọnà gbígbẹ́ wà. Àlàfo ọ̀nà àárín ẹsẹ̀ náà sì ní igun mẹ́rin, wọn kò yíká. 32 Kẹ̀kẹ́ mẹ́rin sì wà nísàlẹ̀ àlàfo ọ̀nà àárín, a sì so ọ̀pá àyíká kẹ̀kẹ́ náà mọ́ ẹsẹ̀ náà. Gíga àyíká kẹ̀kẹ́ kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀. 33 A sì ṣe àyíká kẹ̀kẹ́ náà bí i iṣẹ́ kẹ̀kẹ́; igi ìdálu, ibi ihò, ibi ìpàdé, àti ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn, gbogbo wọn sì jẹ́ irin dídà.

34 Ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì ní ìfẹsẹ̀tẹ̀ mẹ́rin, ọ̀kan ní igun kọ̀ọ̀kan, tí ó yọrí jáde láti ẹsẹ̀. 35 Lókè ẹsẹ̀ náà ni àyíká kan wà tí ó jẹ́ ààbọ̀ ìgbọ̀nwọ́ ní jíjìn. Ẹ̀gbẹ́ etí rẹ̀ àti àlàfo ọ̀nà àárín rẹ̀ ni a so mọ́ òkè ẹsẹ̀ náà. 36 Ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù, kìnnìún àti igi ọ̀pẹ, sára ìgbátí rẹ̀ àti sára pákó tí ó gbé ró, ní gbogbo ibi tí ààyè wà, pẹ̀lú iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ yíkákiri. 37 Báyìí ni ó ṣe ṣe àwọn ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá. Wọ́n sì gbẹ́ gbogbo wọn bákan náà, ìwọ̀n kan náà àti títóbi kan náà.

38 (D)Nígbà náà ni ó ṣe agbádá idẹ mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan gbà tó ogójì ìwọ̀n bati, ó sì wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà ni agbádá kọ̀ọ̀kan wà. 39 Ó sì fi ẹsẹ̀ márùn-ún sí apá ọ̀tún ìhà gúúsù ilé náà àti márùn-ún sí apá òsì ìhà àríwá. Ó sì gbé agbádá ńlá ka apá ọ̀tún, ní apá ìlà-oòrùn sí ìdojúkọ gúúsù ilé náà. 40 Ó sì túnṣe ìkòkò, àti ọkọ́ àti àwokòtò.

Bẹ́ẹ̀ ni Huramu sì parí gbogbo iṣẹ́ tí ó ṣe fún ilé Olúwa fún Solomoni ọba:

41 Àwọn ọ̀wọ́n méjì;

Ọpọ́n méjì ìparí tí ó wà lókè àwọn ọ̀wọ́n iṣẹ́;

àwọn méjì ní láti bo ọpọ́n méjì ìparí tí ń bẹ lókè àwọn ọ̀wọ́n;

42 Irínwó (400) pomegiranate fún iṣẹ́ àwọn méjì, ọ̀wọ́ méjì pomegiranate fún iṣẹ́ àwọn kan láti bo àwọn ọpọ́n méjì ìparí tí ń bẹ lókè àwọn ọ̀wọ́n;

43 Ẹsẹ̀ mẹ́wàá pẹ̀lú agbádá mẹ́wàá wọn;

44 Agbada ńlá náà, àti màlúù méjìlá tí ó wà lábẹ́ rẹ̀;

45 Ìkòkò, ọkọ́ àti àwokòtò.

Gbogbo ohun èlò wọ̀nyí tí Hiramu ṣe fún Solomoni ọba nítorí iṣẹ́ Olúwa sì jẹ́ idẹ dídán. 46 Ọba sì dá wọn ní ilẹ̀ amọ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani lágbedeméjì Sukkoti àti Saretani. 47 Solomoni sì jọ̀wọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí láìwọ́n, nítorí tí wọ́n pọ̀jù; bẹ́ẹ̀ ni a kò sì mọ ìwọ̀n idẹ.

48 Solomoni sì túnṣe gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ tí ń ṣe ti ilé Olúwa pẹ̀lú:

pẹpẹ wúrà;

tábìlì wúrà lórí èyí tí àkàrà ìfihàn gbé wà;

49 Ọ̀pá fìtílà kìkì wúrà, márùn-ún ní apá ọ̀tún àti márùn-ún ní apá òsì, níwájú ibi mímọ́ jùlọ; ìtànná ewéko;

fìtílà àti ẹ̀mú wúrà;

50 Ọpọ́n kìkì wúrà, alumagaji fìtílà, àti àwokòtò, àti ṣíbí àti àwo tùràrí ti wúrà dáradára;

àti àgbékọ́ wúrà fún ìlẹ̀kùn inú ilé ibi mímọ́ jùlọ àti fún ìlẹ̀kùn ilé náà, àní ti tẹmpili.

51 Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí Solomoni ọba ṣe fún ilé Olúwa parí, ó mú gbogbo nǹkan tí Dafidi baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá; fàdákà, wúrà àti ohun èlò, ó sì fi wọ́n sínú ìṣúra ilé Olúwa.

Solomoni kọ́ ilé Olúwa

(A)Nígbà náà, Solomoni bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu lórí òkè Moriah, níbi tí Olúwa ti farahan baba a rẹ̀ Dafidi. Ní orí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi, ibi tí Dafidi pèsè. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kíkọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kejì oṣù kejì ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀.

Ìpìlẹ̀ tí Solomoni gbé kalẹ̀ fún kíkọ́ ilé Ọlọ́run jẹ́ ọgọ́ta gígùn ìgbọ̀nwọ́ àti ogún fífẹ̀ ìgbọ̀nwọ́ Ìloro tí ó wà níwájú ilé Olúwa náà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́.

Ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú kìkì wúrà. Ó fi igi firi bo ilé yàrá ńlá náà ó sì bò ó pẹ̀lú kìkì wúrà, ó sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú igi ọ̀pẹ àti àwòrán ẹ̀wọ̀n. Ó ṣe ilé Olúwa náà lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú òkúta iyebíye. Wúrà tí ó lò jẹ́ wúrà parifaimu. Ó tẹ́ àjà ilé náà pẹ̀lú ìtí igi àti ìlẹ̀kùn ògiri àti àwọn ìlẹ̀kùn ilé Olúwa Pẹ̀lú wúrà, ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù sára ògiri.

Ó kọ́ ibi mímọ́ jùlọ, gígùn rẹ̀ bá fífẹ̀ ilé Olúwa mu, ogún ìgbọ̀nwọ́ fún gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú ọgọ́rin mẹ́fà tálẹ́ǹtì ti wúrà dáradára. Ìwọ̀n àwọn ìṣó náà jẹ́ àádọ́ta ṣékélì. Ó tẹ́ àwọn apẹ òkè pẹ̀lú wúrà.

10 Ní ibi mímọ́ jùlọ, ó gbẹ́ àwòrán igi kérúbù kan, ó sì tẹ́ wọn pẹ̀lú wúrà. 11 Iye ìyẹ́ apá ìbú àtẹ́lẹwọ́ lápapọ̀ ní ti kérúbù, jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ọ̀kan nínú ìyẹ́ apá ti kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé Olúwa. Nígbà tí ìyẹ́ apá kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn ó sì, farakan ìyẹ́ apá kérúbù mìíràn. 12 Ní ìjọra, ìyẹ́ apá kan ti kérúbù kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé Olúwa mìíràn; ìyẹ́ apá rẹ̀ mìíràn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ní gígùn pẹ̀lú tí ó farakan ìyẹ́ apá kérúbù àkọ́kọ́. 13 Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù wọ̀nyí gbà tó ogún ìgbọ̀nwọ́. Wọ́n dúró ní ẹsẹ̀ wọn, wọ́n kọjú sí yàrá pàtàkì ńlá naà.

14 (B)Ó ṣe aṣọ títa ní àwọ̀ ojú ọ̀run, àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ pẹ̀lú kérúbù tí a ṣe sórí i rẹ̀.

15 (C)Níwájú ilé Olúwa náà ó ṣe òpó méjì tí lápapọ̀ jẹ́ márùn-ún dín lógójì ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, olúkúlùkù pẹ̀lú olórí lórí rẹ̀ tí o ń wọn ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. 16 Ó ṣe ẹ̀wọ̀n tí a hun wọ inú ara wọn, ó gbé wọn ká orí òpó náà. Ó ṣe ọgọ́rin pomegiranate (orúkọ èso igi) ó sì so wọ́n mọ́ àwọn ẹ̀wọ̀n náà 17 Ó gbe òpó náà dúró níwájú ilé Olúwa, ọ̀kan sí gúúsù, pẹ̀lú ọ̀kan sí àríwá. Èyí ti gúúsù, ó sọ ní Jakini àti èyí ti àríwá, ó sọ ní Boasi.

Àwọn ìpèsè fún ilé Olúwa

Ó ṣe pẹpẹ idẹ, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá fún gíga. (D)Ó ṣe agbada dídà ńlá tí ó rí róbótó tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti etí kan dé etí èkejì ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún sì ni gíga rẹ̀. Lábẹ́ etí, àwòrán àwọn akọ màlúù yíká mẹ́wàá sí ìgbọ̀nwọ́ kan. Àwọn akọ màlúù náà ni á dá ní ọ̀nà méjì ní àwòrán kan pẹ̀lú okùn.

Okùn náà dúró lórí akọ màlúù méjìlá, mẹ́ta kọjú sí àríwá, mẹ́ta kọjú sí ìwọ̀-oòrùn, mẹ́ta kọjú sí gúúsù mẹ́ta kọjú sí ìlà-oòrùn. Òkun náà sì sinmi lórí wọn àti gbogbo ìhà ẹ̀yìn wọn sì wà ní apá àárín. Ó nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dàbí etí ife ìmumi, bí i ìtànná lílì ó sì dá ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dógún bati dúró.

(E)Ó ṣe ọpọ́n mẹ́wàá fún fífọ nǹkan, ó sì gbé márùn-ún ka ìhà gúúsù àti márùn-ún ní àríwá. Nínú wọn ni ó ti ń fọ àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò fún ẹbọ sísun ṣùgbọ́n, àwọn àlùfáà ní ó ń lo Òkun fún fífọ nǹkan.

Ó ṣe ìgbé fìtílà dúró mẹ́wàá ti wúrà gẹ́gẹ́ bí èyí tí a yàn fún wọn. A sì gbé wọn kalẹ̀ sínú ilé Olúwa márùn un ní ìhà gúúsù àti márùn-ún ní ìhà àríwá.

Ó ṣé tábìlì mẹ́wàá, ó sì gbé wọn sí inú ilé Olúwa, márùn un ní gúúsù àti márùn-ún ní ìhà àríwá. Ó ṣé ọgọ́ọ̀rún ọpọ́n ìbùwọ́n wúrà.

Ó ṣe àgbàlá àwọn àlùfáà àti ààfin ńlá àti àwọn ìlẹ̀kùn fún ààfin, ó sì tẹ́ àwọn ìlẹ̀kùn náà pẹ̀lú idẹ. 10 Ó gbé Òkun náà ka orí ìhà gúúsù ní ẹ̀bá Igun gúúsù àríwá.

11 Huramu ṣe àwọn ìkòkò pẹ̀lú, àti ọkọ́ àti àwọn ọpọ́n ìbùwọ́n.

Bẹ́ẹ̀ ni Huramu parí iṣẹ́ tí ó ti dáwọ́lé fún ọba Solomoni ní ilé Ọlọ́run:

12 Àwọn òpó méje;

àwọn ọpọ́n méjì rìbìtì tí ó wà lórí òpó méjèèje náà;

àti iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n méjì láti bo ọpọ́n rìbìtì náà tí ó wà lórí àwọn òpó naà;

13 Ọgọ́rùn-ún mẹ́rin pomegiranate fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n méjì naà, ẹsẹ̀ méjì pomegiranate ni fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n kan, láti bo ọpọ́n rìbìtì méjì náà tí ó wà lórí àwọn òpó náà;

14 Ó sì ṣe àgbéró ó sì ṣe agbada sí orí wọn;

15 Agbada ńlá kan àti màlúù méjìlá lábẹ́ rẹ̀;

16 Àwọn ìkòkò àti ọ̀kọ̀ àti àmúga ẹran àti gbogbo ohun èlò tí ó fi ara pẹ́ ẹ.

Gbogbo ohun èlò ti Huramu-Abi fi idẹ dídán ṣe fún Solomoni ọba, fún ilé Olúwa jẹ́ idẹ dídán. 17 Ọba dà wọ́n ní ilẹ̀ amọ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ní àárín méjì Sukkoti àti Sereda. 18 Gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí Solomoni ṣe ní iye lórí púpọ̀ tí a kò le mọ ìwọ̀n iye idẹ tí ó wọ́n.

19 Solomoni pẹ̀lú ṣe gbogbo ohun èlò tí ó wà ní ilé Ọlọ́run:

pẹpẹ wúrà

tábìlì èyí tí àkàrà ìfihàn wà lórí rẹ̀;

20 Àwọn ọ̀pá fìtílà tí a fi ojúlówó wúrà ṣe pẹ̀lú fìtílà wọn kí wọn lè máa jó gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ní iwájú ibi mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi lélẹ̀;

21 Pẹ̀lú ìtànná wúrà àti fìtílà àti ẹ̀mú ni ó jẹ́ kìkìdá wúrà tí ó gbópọn;

22 Pẹ̀lú ọ̀pá fìtílà, àti àwokòtò àti ṣíbí àti àwokòtò tùràrí àti àwọn ìlẹ̀kùn wúrà ti inú tẹmpili: àwọn ìlẹ̀kùn ibi mímọ́ sí ibi mímọ́ jùlọ àti àwọn ìlẹ̀kùn à bá wọ inú gbọ̀ngàn ńlá.