Add parallel Print Page Options

Àwọn alákòóso Edomu

43 Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Edomu, kí ó tó di pé ọba kankan jẹ lórí Israẹli:

Bela ọmọ Beori, orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba.

44 Nígbà tí Bela kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

45 Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu láti ilẹ̀ Temani sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

46 Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi tí ó kọlu Midiani ní ìgbẹ́ Moabu, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti.

47 Nígbà tí Hadadi sì kú, Samla láti Masreka, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

48 Samla sì kú, Saulu ti Rehoboti létí odò sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀

49 Nígbà tí Saulu kú, Baali-Hanani, ọmọ Akbori jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

50 Nígbà tí Baali-Hanani kú, Hadadi ni ó jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Pau; orúkọ ìyàwó sì ni Mehetabeeli ọmọbìnrin Matiredi, ọmọbìnrin Mesahabu. 51 Hadadi sì kú pẹ̀lú.

Àwọn baálẹ̀ Edomu ni:

baálẹ̀ Timna, baálẹ̀ Alfa, baálẹ̀ Jeteti 52 baálẹ̀ Oholibama, baálẹ̀ Ela, baálẹ̀ Pinoni. 53 baálẹ̀ Kenasi, baálẹ̀ Temani, baálẹ̀ Mibsari,

Read full chapter