Add parallel Print Page Options

Pínpín àwọn àlùfáà

24 Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Aaroni:

Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari. Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; bẹ́ẹ̀ ni Eleasari àti Itamari sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Sadoku ọmọ Eleasari àti Ahimeleki ọmọ Itamari, Dafidi sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn. A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Eleasari ju lára àwọn ọmọ Itamari lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ: mẹ́rìn-dínlógún olórí láti ìdílé ọmọ Eleasari ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Itamari. Wọ́n sì pín wọn láìṣègbè nípa yíya ìpín, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run wà láàrín àwọn ọmọ méjèèjì Eleasari àti Itamari.

Ṣemaiah ọmọ Netaneli, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Lefi sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Sadoku àlùfáà, Ahimeleki ọmọ Abiatari àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Eleasari àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Itamari.

Ìpín èkínní jáde sí Jehoiaribu,

èkejì sí Jedaiah,

Ẹlẹ́kẹta sì ni Harimu,

ẹ̀kẹrin sì ní Ṣeorimu,

Ẹ̀karùnún sì ni Malkiah,

ẹlẹ́kẹfà sì ni Mijamini,

10 Èkeje sì ni Hakosi,

ẹlẹ́kẹjọ sí ni Abijah,

11 Ẹ̀kẹsànán sì ni Jeṣua,

ẹ̀kẹwàá sì ni Ṣekaniah,

12 Ẹ̀kọkànlá sì ni Eliaṣibu,

ẹlẹ́kẹjìlá sì ni Jakimu,

13 Ẹ̀kẹtàlá sì ni Hupa,

ẹlẹ́kẹrìnlá sì ni Jeṣebeabu,

14 Ẹ̀kẹdógún sì ni Bilgah,

ẹ̀kẹrìn-dínlógún sì ni Immeri

15 Ẹ̀kẹtà-dínlógún sì ni Hesiri,

èkejì-dínlógún sì ni Hafisesi,

16 Ẹ̀kọkàndínlógún sì ni Petahiah,

ogún sì ni Jeheskeli,

17 Ẹ̀kọkànlélógún sì ni Jakini,

ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Gamuli,

18 Ẹ̀kẹtàlélógún sì ni Delaiah,

ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Maasiah.

19 Àwọn wọ̀nyí ni a yàn fún iṣẹ́ ìsìn nígbà tí wọ́n wọ ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìlànà àti àṣẹ tí a ti fi fún wọn láti ọwọ́ baba ńlá wọn Aaroni gẹ́gẹ́ bí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tí pàṣẹ fun un.

Ìyókù nínú àwọn ọmọ Lefi

20 Ìyókù àwọn ọmọ Lefi:

Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Amramu: Ṣubaeli

láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣubueli; Jehdeiah.

21 Àti gẹ́gẹ́ bí Rehabiah, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Rehabiah, Iṣiah sì ni alákọ́kọ́.

22 Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Isari: Ṣelomiti;

láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣelomoti: Jahati.

23 Àwọn ọmọ Hebroni:

Jeriah alákọ́kọ́, Amariah ẹlẹ́kejì, Jahasieli ẹlẹ́kẹta àti Jekameamu ẹlẹ́kẹrin.

24 Àwọn ọmọ Usieli: Mika;

nínú àwọn ọmọ Mika: Ṣamiri.

25 Àwọn arákùnrin Mika: Iṣi;

nínú àwọn ọmọ Iṣiah: Sekariah.

26 Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi.

Àwọn ọmọ Jaasiah: Beno.

27 Àwọn ọmọ Merari:

Láti Jaasiah: Beno, Ṣohamu, Sakkuri àti Ibri.

28 Láti Mahili: Eleasari, ẹni tí kò ni àwọn ọmọ.

29 Láti Kiṣi: Àwọn ọmọ Kiṣi: Jerahmeeli.

30 Àti àwọn ọmọ Muṣi: Mahili, Ederi àti Jerimoti.

Èyí ni àwọn ọmọ Lefi, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.

31 Wọ́n sì ṣé kèké gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Aaroni ṣe ṣẹ́, níwájú ọba Dafidi àti Sadoku, Ahimeleki, àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi. Àwọn ìdílé àgbàgbà arákùnrin wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lórí àwọn arákùnrin wọn kéékèèkéé.

The Divisions of Priests

24 These were the divisions(A) of the descendants of Aaron:(B)

The sons of Aaron were Nadab, Abihu, Eleazar and Ithamar.(C) But Nadab and Abihu died before their father did,(D) and they had no sons; so Eleazar and Ithamar served as the priests. With the help of Zadok(E) a descendant of Eleazar and Ahimelek a descendant of Ithamar, David separated them into divisions for their appointed order of ministering. A larger number of leaders were found among Eleazar’s descendants than among Ithamar’s, and they were divided accordingly: sixteen heads of families from Eleazar’s descendants and eight heads of families from Ithamar’s descendants. They divided them impartially by casting lots,(F) for there were officials of the sanctuary and officials of God among the descendants of both Eleazar and Ithamar.

The scribe Shemaiah son of Nethanel, a Levite, recorded their names in the presence of the king and of the officials: Zadok the priest, Ahimelek(G) son of Abiathar and the heads of families of the priests and of the Levites—one family being taken from Eleazar and then one from Ithamar.

The first lot fell to Jehoiarib,

the second to Jedaiah,(H)

the third to Harim,(I)

the fourth to Seorim,

the fifth to Malkijah,

the sixth to Mijamin,

10 the seventh to Hakkoz,

the eighth to Abijah,(J)

11 the ninth to Jeshua,

the tenth to Shekaniah,

12 the eleventh to Eliashib,

the twelfth to Jakim,

13 the thirteenth to Huppah,

the fourteenth to Jeshebeab,

14 the fifteenth to Bilgah,

the sixteenth to Immer,(K)

15 the seventeenth to Hezir,(L)

the eighteenth to Happizzez,

16 the nineteenth to Pethahiah,

the twentieth to Jehezkel,

17 the twenty-first to Jakin,

the twenty-second to Gamul,

18 the twenty-third to Delaiah

and the twenty-fourth to Maaziah.

19 This was their appointed order of ministering when they entered the temple of the Lord, according to the regulations prescribed for them by their ancestor Aaron, as the Lord, the God of Israel, had commanded him.

The Rest of the Levites

20 As for the rest of the descendants of Levi:(M)

from the sons of Amram: Shubael;

from the sons of Shubael: Jehdeiah.

21 As for Rehabiah,(N) from his sons:

Ishiah was the first.

22 From the Izharites: Shelomoth;

from the sons of Shelomoth: Jahath.

23 The sons of Hebron:(O) Jeriah the first,[a] Amariah the second, Jahaziel the third and Jekameam the fourth.

24 The son of Uzziel: Micah;

from the sons of Micah: Shamir.

25 The brother of Micah: Ishiah;

from the sons of Ishiah: Zechariah.

26 The sons of Merari:(P) Mahli and Mushi.

The son of Jaaziah: Beno.

27 The sons of Merari:

from Jaaziah: Beno, Shoham, Zakkur and Ibri.

28 From Mahli: Eleazar, who had no sons.

29 From Kish: the son of Kish:

Jerahmeel.

30 And the sons of Mushi: Mahli, Eder and Jerimoth.

These were the Levites, according to their families. 31 They also cast lots,(Q) just as their relatives the descendants of Aaron did, in the presence of King David and of Zadok, Ahimelek, and the heads of families of the priests and of the Levites. The families of the oldest brother were treated the same as those of the youngest.

Footnotes

  1. 1 Chronicles 24:23 Two Hebrew manuscripts and some Septuagint manuscripts (see also 23:19); most Hebrew manuscripts The sons of Jeriah: