Add parallel Print Page Options

17 (A)Ní déédé àkókò yìí, Hasaeli ọba Siria gòkè lọ láti dojúkọ Gati àti láti fi agbára mú un. Nígbà náà, ó yípadà láti dojúkọ Jerusalẹmu.

Read full chapter

18 Ṣùgbọ́n Jehoaṣi ọba Juda mú gbogbo ohun mímọ́ tí a gbé ka iwájú tí a yà sọ́tọ̀ nípasẹ̀ baba rẹ̀—Jehoṣafati, Jehoramu àti Ahasiah, àwọn ọba Juda, àti àwọn ẹ̀bùn tí òun tìkára rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ àti gbogbo wúrà, tí ó rí nínú ibi ìfowópamọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa àti ní ti ààfin ọba, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Hasaeli; ọba Siria, tí ó sì fà padà kúrò ní Jerusalẹmu.

Read full chapter

20 Àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ sí i wọ́n sì lù ú pa ní Beti-Milo ní ọ̀nà sí Silla.

Read full chapter

21 Àwọn oníṣẹ́ tí ó pa á jẹ́ Josabadi ọmọ Ṣimeati àti Jehosabadi ọmọ Ṣomeri. Ó kú, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú baba rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dafidi. Amasiah ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Read full chapter