Add parallel Print Page Options

Ìrìn àrè ní aginjù

(A)Nígbà náà ni a yípadà, tí a sì mú ọ̀nà wa pọ̀n lọ sí aginjù, a gba ọ̀nà Òkun pupa, bí Olúwa ti darí mi. Ìgbà pípẹ́ ni a fi ń rìn kiri yíká agbègbè àwọn ìlú olókè Seiri.

Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé, “Ẹ ti rìn yí agbègbè ilẹ̀ olókè yìí pẹ́ tó, nísinsin yìí, ẹ yípadà sí ìhà àríwá. (B)Fún àwọn ènìyàn náà ní àwọn òfin wọ̀nyí: ‘Ẹ ti fẹ́ la ilẹ̀ àwọn arákùnrin yín kọjá, àwọn ọmọ Esau; àwọn ará Edomu tí ń gbé ní Seiri. Ẹ̀rù yín yóò bà wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi. Ẹ má ṣe wá wọn níjà torí pé èmi kò ní fún un yín ní èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn. Bí ó ti wù kí ó kéré mọ èmi kò ní fún un yín. Mo ti fi ilẹ̀ òkè Seiri fún Esau gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀. Ẹ san owó oúnjẹ tí ẹ bá jẹ fún wọn àti omi tí ẹ bá mu.’ ”

Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún un yín nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín. Ó ti mójútó ìrìnàjò yín nínú aginjù ńlá yìí. Olúwa Ọlọ́run yín wà pẹ̀lú u yín ní ogójì ọdún wọ̀nyí, dé bi pé ẹ̀yin kò ṣaláìní ohunkóhun.

Bẹ́ẹ̀ ni a kọjá ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wa, àwọn ọmọ Esau tí ń gbé ní Seiri. A yà kúrò ní ọ̀nà Arabah èyí tí ó wá láti Elati àti Esioni-Geberi, a sì rìn gba ọ̀nà aginjù Moabu.

Olúwa sì sọ fún mi pé, “Ẹ má ṣe dẹ́rùba àwọn ará Moabu bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe bá wọn jagun torí pé n kò ní fi èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn fún un yín. Mo ti fi Ari fún àwọn ọmọ Lọti bí i ìní.”

10 Àwọn Emimu ti gbé ibẹ̀ rí: Àwọn ènìyàn tó síngbọnlẹ̀ tó sì pọ̀, wọ́n ga bí àwọn Anaki. 11 Gẹ́gẹ́ bí Anaki àwọn ènìyàn náà pè wọ́n ní ará Refaimu ṣùgbọ́n àwọn ará Moabu pè wọ́n ní Emimu. 12 Àwọn ará Hori gbé ní Seiri kí àwọn ọmọ Esau tó lé wọn kúrò níwájú wọn, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, (wọ́n tẹ̀dó sí ààyè wọn) gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli tí ṣe ní ilẹ̀ tí Olúwa yóò fún wọn ní ìní wọn.

13 Olúwa sì wí pé, “Ẹ dìde, kí ẹ sì la Àfonífojì Seredi kọjá.” Bẹ́ẹ̀ ni a la àfonífojì náà kọjá.

14 (C)Ó gbà wá ní ọdún méjì-dínlógójì (38) kí ó tó di wí pé a la Àfonífojì Seredi kọjá láti ìgbà tí a ti kúrò ní Kadeṣi-Barnea. Nígbà náà gbogbo ìran àwọn tí ó jẹ́ jagunjagun láàrín àwọn ènìyàn náà ti ṣègbé kúrò láàrín àwọn ènìyàn náà ní àsìkò yìí bí Olúwa ti búra fún wọn. 15 Ọwọ́ Olúwa sì wà lòdì sí wọn nítòótọ́, láti run wọn kúrò nínú ibùdó, títí gbogbo wọn fi run tan.

16 Lẹ́yìn tí ẹni tí ó gbẹ̀yìn pátápátá nínú àwọn jagunjagun àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti kú, 17 Olúwa sọ fún mi pé, 18 “Lónìí ni ẹ̀yin yóò la agbègbè Moabu kọjá ní Ari. 19 Bí ẹ bá dé ọ̀dọ̀ àwọn ará Ammoni, ẹ má ṣe halẹ̀ mọ́ wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ bá wọn jagun, torí pé èmi kì yóò fi àwọn ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ará Ammoni fún un yín ní ìní. Mo ti fi fún àwọn ọmọ Lọti ní ìní.”

20 (A ka ilẹ̀ yìí sí ilẹ̀ àwọn Refaimu, tí wọ́n ti gbé níbẹ̀ rí, ṣùgbọ́n àwọn ará Ammoni ń pè wọ́n ní ará Samsummimu. 21 Wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tó lágbára, wọ́n sì pọ̀, wọ́n sì ga gògòrò bí àwọn ará Anaki. Olúwa run wọn kúrò níwájú àwọn ará Ammoni, tí wọ́n lé wọn jáde tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn. 22 Bákan náà ni Olúwa ṣe fún àwọn ọmọ Esau, tí wọ́n ń gbé ní Seiri, nígbà tí ó pa àwọn ará Hori run níwájú wọn. Wọ́n lé wọn jáde wọ́n sì ń gbé ní ilẹ̀ wọn títí di òní. 23 Nípa ti àwọn ará Affimu, tí wọ́n ń gbé ní àwọn ìlú kéékèèkéé dé Gasa, àwọn ará Kaftorimu, tí wọ́n jáde láti Krete wá ni ó pa wọ́n run, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn.)

Israẹli ṣẹ́gun Sioni ọba Heṣboni

24 “Ẹ gbáradì, kí ẹ sì kọjá odò Arnoni. Kíyèsi, Mo ti fi Sihoni ará Amori, ọba Heṣboni àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Ẹ bá ilẹ̀ náà jagun kí ẹ sì gbà á. 25 Èmi bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ìbẹ̀rù àti ìfòyà yín sára gbogbo orílẹ̀-èdè lábẹ́ ọ̀run láti òní lọ. Wọn yóò gbọ́ ìròyìn in yín, wọn yóò sì wárìrì, wọn yóò sì wà nínú ìdààmú ọkàn torí i tiyín.”

26 Mo rán àwọn ìránṣẹ́ láti aginjù Kedemoti lọ́ sọ́dọ̀ Sihoni ọba Heṣboni pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àlàáfíà wí pé, 27 “Jẹ́ kí a la ilẹ̀ ẹ yín kọjá. Àwa yóò gba ti òpópónà nìkan. A kò ní yà sọ́tùn tàbí sósì. 28 Ẹ ta oúnjẹ tí a ó jẹ àti omi tí a ó mu fún wa ní iye owó wọn. Kìkì kí ẹ sá à jẹ́ kí a rìn kọjá: 29 gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Esau tí ó ń gbé ní Seiri àti àwọn ará Moabu tí ó ń gbé ní Ari, ti gbà wá láààyè títí a fi la Jordani já dé ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò fún wa.” 30 Ṣùgbọ́n Sihoni ọba Heṣboni kò gbà fún wa láti kọjá. Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ti mú ọkàn rẹ̀ yigbì, àyà rẹ̀ sì kún fún agídí kí ó ba à le fi lé e yín lọ́wọ́, bí ó ti ṣe báyìí.

31 Olúwa sì bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kíyèsi i, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi Sihoni àti ilẹ̀ rẹ̀ lé e yín lọ́wọ́. Báyìí, ẹ máa ṣẹ́gun rẹ̀, kí ẹ sì gba ilẹ̀ rẹ̀.”

32 Nígbà tí Sihoni àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ̀ jáde wá láti bá wa jagun ní Jahasi, 33 Olúwa Ọlọ́run wa fi lé wa lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ni a ṣẹ́gun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ológun rẹ̀. 34 Nígbà náà, gbogbo ìlú wọn ni a kó tí a sì pa wọ́n run pátápátá tọkùnrin, tobìnrin àti gbogbo ọmọ wọn. A kò sì dá ẹnikẹ́ni sí. 35 Ṣùgbọ́n a kó gbogbo ohun ọ̀sìn àti ìkógun àwọn ìlú tí a ṣẹ́gun fún ara wa. 36 Láti Aroeri, létí odò Arnoni àti láti àwọn ìlú tí ó wà lẹ́bàá odò náà títí ó fi dé Gileadi, kò sí ìlú tí ó lágbára jù fún wa, Olúwa Ọlọ́run wa fi gbogbo wọn fún wa. 37 Ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa Ọlọ́run wa, ẹ kò súnmọ́ ọ̀kan nínú ilẹ̀ àwọn ará Ammoni, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò dé ilẹ̀ tí ó lọ sí Jabbok, tàbí ilẹ̀ tí ó yí àwọn ìlú òkè e nì ká.

Wanderings in the Wilderness

Then we turned back and set out toward the wilderness along the route to the Red Sea,[a](A) as the Lord had directed me. For a long time we made our way around the hill country of Seir.(B)

Then the Lord said to me, “You have made your way around this hill country long enough;(C) now turn north. Give the people these orders:(D) ‘You are about to pass through the territory of your relatives the descendants of Esau,(E) who live in Seir.(F) They will be afraid(G) of you, but be very careful. Do not provoke them to war, for I will not give you any of their land, not even enough to put your foot on. I have given Esau the hill country of Seir as his own.(H) You are to pay them in silver for the food you eat and the water you drink.’”

The Lord your God has blessed you in all the work of your hands. He has watched(I) over your journey through this vast wilderness.(J) These forty years(K) the Lord your God has been with you, and you have not lacked anything.(L)

So we went on past our relatives the descendants of Esau, who live in Seir. We turned from(M) the Arabah(N) road, which comes up from Elath and Ezion Geber,(O) and traveled along the desert road of Moab.(P)

Then the Lord said to me, “Do not harass the Moabites or provoke them to war, for I will not give you any part of their land. I have given Ar(Q) to the descendants of Lot(R) as a possession.”

10 (The Emites(S) used to live there—a people strong and numerous, and as tall as the Anakites.(T) 11 Like the Anakites, they too were considered Rephaites,(U) but the Moabites called them Emites. 12 Horites(V) used to live in Seir, but the descendants of Esau drove them out. They destroyed the Horites from before them and settled in their place, just as Israel did(W) in the land the Lord gave them as their possession.)

13 And the Lord said, “Now get up and cross the Zered Valley.(X)” So we crossed the valley.

14 Thirty-eight years(Y) passed from the time we left Kadesh Barnea(Z) until we crossed the Zered Valley. By then, that entire generation(AA) of fighting men had perished from the camp, as the Lord had sworn to them.(AB) 15 The Lord’s hand was against them until he had completely eliminated(AC) them from the camp.

16 Now when the last of these fighting men among the people had died, 17 the Lord said to me, 18 “Today you are to pass by the region of Moab at Ar.(AD) 19 When you come to the Ammonites,(AE) do not harass them or provoke them to war,(AF) for I will not give you possession of any land belonging to the Ammonites. I have given it as a possession to the descendants of Lot.(AG)

20 (That too was considered a land of the Rephaites,(AH) who used to live there; but the Ammonites called them Zamzummites. 21 They were a people strong and numerous, and as tall as the Anakites.(AI) The Lord destroyed them from before the Ammonites, who drove them out and settled in their place. 22 The Lord had done the same for the descendants of Esau, who lived in Seir,(AJ) when he destroyed the Horites from before them. They drove them out and have lived in their place to this day. 23 And as for the Avvites(AK) who lived in villages as far as Gaza,(AL) the Caphtorites(AM) coming out from Caphtor[b](AN) destroyed them and settled in their place.)

Defeat of Sihon King of Heshbon

24 “Set out now and cross the Arnon Gorge.(AO) See, I have given into your hand Sihon the Amorite,(AP) king of Heshbon, and his country. Begin to take possession of it and engage(AQ) him in battle. 25 This very day I will begin to put the terror(AR) and fear(AS) of you on all the nations under heaven. They will hear reports of you and will tremble(AT) and be in anguish because of you.”

26 From the Desert of Kedemoth(AU) I sent messengers to Sihon(AV) king of Heshbon offering peace(AW) and saying, 27 “Let us pass through your country. We will stay on the main road; we will not turn aside to the right or to the left.(AX) 28 Sell us food to eat(AY) and water to drink for their price in silver. Only let us pass through on foot(AZ) 29 as the descendants of Esau, who live in Seir, and the Moabites, who live in Ar, did for us—until we cross the Jordan into the land the Lord our God is giving us.” 30 But Sihon king of Heshbon refused to let us pass through. For the Lord(BA) your God had made his spirit stubborn(BB) and his heart obstinate(BC) in order to give him into your hands,(BD) as he has now done.

31 The Lord said to me, “See, I have begun to deliver Sihon and his country over to you. Now begin to conquer and possess his land.”(BE)

32 When Sihon and all his army came out to meet us in battle(BF) at Jahaz, 33 the Lord our God delivered(BG) him over to us and we struck him down,(BH) together with his sons and his whole army. 34 At that time we took all his towns and completely destroyed[c](BI) them—men, women and children. We left no survivors. 35 But the livestock(BJ) and the plunder(BK) from the towns we had captured we carried off for ourselves. 36 From Aroer(BL) on the rim of the Arnon Gorge, and from the town in the gorge, even as far as Gilead,(BM) not one town was too strong for us. The Lord our God gave(BN) us all of them. 37 But in accordance with the command of the Lord our God,(BO) you did not encroach on any of the land of the Ammonites,(BP) neither the land along the course of the Jabbok(BQ) nor that around the towns in the hills.

Footnotes

  1. Deuteronomy 2:1 Or the Sea of Reeds
  2. Deuteronomy 2:23 That is, Crete
  3. Deuteronomy 2:34 The Hebrew term refers to the irrevocable giving over of things or persons to the Lord, often by totally destroying them.