Add parallel Print Page Options

Yíyọ orúkọ ènìyàn kúrò nínú orúkọ àwọn ènìyàn Olúwa

23 Kí ẹnikẹ́ni tí a fọ́ ní kóró ẹpọ̀n nípa rírùn tàbí gígé má ṣe wọ inú ìjọ Olúwa wá.

Kí ọmọ àlè má ṣe wọ ìpéjọ Olúwa, pàápàá títí dé ìran kẹwàá.

(A)Kí ọmọ Ammoni tàbí ọmọ Moabu, kì yóò wọ ìjọ Olúwa, àní títí dé ìran kẹwàá, ènìyàn wọn kan kì yóò wọ inú ìjọ ènìyàn Olúwaláéláé. (B)Nítorí wọn kò fi àkàrà àti omi pàdé e yín lójú ọ̀nà nígbà tí ò ń bọ̀ láti Ejibiti àti nítorí wọ́n gba ẹ̀yà iṣẹ́ láti fi ọ́ gégùn ún Balaamu ọmọ Beori ará a Petori ti Aramu-Naharaimu. (C)Síbẹ̀síbẹ̀, Olúwa Ọlọ́run rẹ kò ní fetí sí Balaamu ṣùgbọ́n ó yí ègún sí ìbùkún fún ọ, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ fẹ́ràn rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ wá àlàáfíà, tàbí ire wọn níwọ̀n ìgbà tí o sì wà láààyè.

Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra ará Edomu kan nítorí arákùnrin rẹ ni. Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra ará Ejibiti, nítorí o gbé gẹ́gẹ́ bí àjèjì ní ilẹ̀ rẹ̀. Ìran kẹta àwọn ọmọ tí a bí fún wọn lè wọ ìpéjọ Olúwa.

Ìwà àìmọ́ nínú àgọ́

Nígbà tí o bá dó ti àwọn ọ̀tá rẹ, pa gbogbo ohun àìmọ́ kúrò. 10 Bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin rẹ bá jẹ́ aláìmọ́ nítorí ìtújáde tí ó ní, o ní láti jáde kúrò nínú àgọ́, kí o má ṣe wọ inú àgọ́. 11 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ o ní láti wẹ ara rẹ, àti ní àṣálẹ́ kí o padà sínú àgọ́.

12 Sàmì sí ibìkan lóde àgọ́, níbi tí o lè máa lọ láti dẹ ara rẹ lára. 13 Kí ìwọ kí ó sì mú ìwalẹ̀ kan pẹ̀lú ohun ìjà rẹ; yóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ yóò bá gbọnṣẹ̀ lẹ́yìn ibùdó, kí ìwọ kí ó mú ìwalẹ̀, kí ìwọ kí ó sì yípadà, kí o sì bo ohun tí ó jáde láara rẹ. 14 Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń rìn láàrín àgọ́ láti dáàbò bò ọ́ àti láti fi àwọn ọ̀tá à rẹ lé ọ lọ́wọ́. Àgọ́ rẹ ní láti jẹ́ mímọ́, nítorí kí ó má ba à rí ohun àìtọ́ láàrín yín kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ yín.

Onírúurú òfin

15 Bí ẹrú kan bá ti gba ààbò lọ́dọ̀ rẹ, má ṣe fi lé ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́. 16 Jẹ́ kí ó máa gbé láàrín rẹ níbikíbi tí ó bá fẹ́ àti èyíkéyìí ìlú tí ó bá mú. Má ṣe ni í lára.

17 Kí ọkùnrin tàbí obìnrin Israẹli má ṣe padà di alágbèrè ojúbọ òrìṣà. 18 Ìwọ kò gbọdọ̀ mú owó iṣẹ́ panṣágà obìnrin tàbí ọkùnrin wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ láti fi san ẹ̀jẹ́ kankan; nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ kórìíra àwọn méjèèjì.

19 (D)Ìwọ kò gbọdọ̀ ka èlé sí arákùnrin rẹ lọ́rùn, bóyá lórí owó tàbí oúnjẹ tàbí ohunkóhun mìíràn tí ó lè mú èlé wá. 20 Ìwọ lè ka èlé sí àlejò lọ́rùn, ṣùgbọ́n kì í ṣe arákùnrin ọmọ Israẹli, nítorí kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún ọ nínú ohun gbogbo tí o bá dáwọ́lé ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.

21 (E)Bí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, má ṣe lọ́ra láti san án, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, o sì máa jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀. 22 Ṣùgbọ́n tí o bá fàsẹ́yìn láti jẹ́ ẹ̀jẹ́, o kò ní jẹ̀bi. 23 Rí i dájú pé o ṣe ohunkóhun tí o bá ti ètè rẹ jáde, nítorí pé ìwọ fi tinútinú rẹ jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú ẹnu ara rẹ.

24 Bí ìwọ bá wọ inú ọgbà àjàrà aládùúgbò rẹ, o lè jẹ gbogbo èso àjàrà tí o bá fẹ́, ṣùgbọ́n má ṣe fi nǹkan kan sínú agbọ̀n rẹ. 25 Bí ìwọ bá wọ inú oko ọkà aládùúgbò rẹ, o lè fi ọwọ́ rẹ ya síírí rẹ̀, ṣùgbọ́n o kò gbọdọ̀ ki dòjé bọ ọkà tí ó dúró.

Exclusion From the Assembly

23 [a]No one who has been emasculated(A) by crushing or cutting may enter the assembly of the Lord.

No one born of a forbidden marriage[b] nor any of their descendants may enter the assembly of the Lord, not even in the tenth generation.

No Ammonite(B) or Moabite or any of their descendants may enter the assembly of the Lord, not even in the tenth generation.(C) For they did not come to meet you with bread and water(D) on your way when you came out of Egypt, and they hired Balaam(E) son of Beor from Pethor in Aram Naharaim[c](F) to pronounce a curse on you.(G) However, the Lord your God would not listen to Balaam but turned the curse(H) into a blessing for you, because the Lord your God loves(I) you. Do not seek a treaty(J) of friendship with them as long as you live.(K)

Do not despise an Edomite,(L) for the Edomites are related to you.(M) Do not despise an Egyptian, because you resided as foreigners in their country.(N) The third generation of children born to them may enter the assembly of the Lord.

Uncleanness in the Camp

When you are encamped against your enemies, keep away from everything impure.(O) 10 If one of your men is unclean because of a nocturnal emission, he is to go outside the camp and stay there.(P) 11 But as evening approaches he is to wash himself, and at sunset(Q) he may return to the camp.(R)

12 Designate a place outside the camp where you can go to relieve yourself. 13 As part of your equipment have something to dig with, and when you relieve yourself, dig a hole and cover up your excrement. 14 For the Lord your God moves(S) about in your camp to protect you and to deliver your enemies to you. Your camp must be holy,(T) so that he will not see among you anything indecent and turn away from you.

Miscellaneous Laws

15 If a slave has taken refuge(U) with you, do not hand them over to their master.(V) 16 Let them live among you wherever they like and in whatever town they choose. Do not oppress(W) them.

17 No Israelite man(X) or woman is to become a shrine prostitute.(Y) 18 You must not bring the earnings of a female prostitute or of a male prostitute[d] into the house of the Lord your God to pay any vow, because the Lord your God detests them both.(Z)

19 Do not charge a fellow Israelite interest, whether on money or food or anything else that may earn interest.(AA) 20 You may charge a foreigner(AB) interest, but not a fellow Israelite, so that the Lord your God may bless(AC) you in everything you put your hand to in the land you are entering to possess.

21 If you make a vow to the Lord your God, do not be slow to pay it,(AD) for the Lord your God will certainly demand it of you and you will be guilty of sin.(AE) 22 But if you refrain from making a vow, you will not be guilty.(AF) 23 Whatever your lips utter you must be sure to do, because you made your vow freely to the Lord your God with your own mouth.

24 If you enter your neighbor’s vineyard, you may eat all the grapes you want, but do not put any in your basket. 25 If you enter your neighbor’s grainfield, you may pick kernels with your hands, but you must not put a sickle to their standing grain.(AG)

Footnotes

  1. Deuteronomy 23:1 In Hebrew texts 23:1-25 is numbered 23:2-26.
  2. Deuteronomy 23:2 Or one of illegitimate birth
  3. Deuteronomy 23:4 That is, Northwest Mesopotamia
  4. Deuteronomy 23:18 Hebrew of a dog