Add parallel Print Page Options

12 (A)Bí ẹ bá ń kíyèsi àwọn òfin wọ̀nyí tí ẹ sì ń ṣọ́ra láti ṣe wọ́n, nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run yín yóò pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún un yín, bí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín. 13 Yóò fẹ́ràn yín, yóò bùkún un yín yóò sì mú kí ẹ pọ̀ sí i. Yóò bùkún èso inú yín, ọ̀gbìn ilẹ̀ yín, oúnjẹ yín, wáìnì tuntun àti òróró yín, àwọn màlúù, agbo ẹran yín, àti àwọn àgùntàn, ọ̀wọ́ ẹran yín, ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá yín láti fún un yín. 14 A ó bùkún un yín ju gbogbo ènìyàn lọ, kò sí ẹni tí yóò yàgàn nínú ọkùnrin tàbí obìnrin yín, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọ̀kan nínú àwọn ohun ọ̀sìn in yín tí yóò wà láìlọ́mọ. 15 Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ààrùn gbogbo, kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí ààrùn búburú tí ẹ mọ̀ ní Ejibiti wá sára yín, ṣùgbọ́n yóò fi wọ́n lé ara gbogbo àwọn tí ó kórìíra yín. 16 Gbogbo àwọn ènìyàn tí Olúwa Ọlọ́run yín fi lé yín lọ́wọ́ ni kí ẹ parun pátápátá. Ẹ má ṣe ṣàánú fún wọn, ẹ má ṣe sin olúwa ọlọ́run wọn torí pé ìdánwò ni èyí jẹ́ fún un yín.

17 Ẹ lè máa rò láàrín ara yín pé, “Àwọn orílẹ̀-èdè yìí lágbára jù wá lọ. Báwo ni a o ṣe lé wọn jáde?” 18 Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn: Ẹ rántí dáradára ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe sí Farao àti gbogbo Ejibiti. 19 Ẹ sá à fi ojú u yín rí àwọn àdánwò ńlá, àwọn iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá, ọwọ́ agbára àti nínà ọwọ́ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi mú un yín jáde. Olúwa Ọlọ́run yín yóò ṣe bákan náà sí gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ẹ ń bẹ̀rù. 20 Pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa Ọlọ́run yín yóò rán oyin sáàrín wọn títí tí àwọn tí ó sálà tí wọ́n sápamọ́ fún un yín, yóò fi ṣègbé. 21 Ẹ má gbọ̀n jìnnìjìnnì torí wọn, torí pé Olúwa Ọlọ́run yín tí ó wà láàrín yín, Ọlọ́run alágbára ni, àti Ọlọ́run tí ó tóbi lọ́pọ̀lọpọ̀. 22 Olúwa Ọlọ́run yín yóò lé gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀n-ọn-nì kúrò níwájú u yín díẹ̀díẹ̀. A kò nígbà yín láààyè láti lé wọn dànù lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Kí àwọn ẹranko igbó má ba à gbilẹ̀ sí i láàrín yín. 23 Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́, yóò sì máa fà wọ́n sínú dàrúdàpọ̀ títí tí wọn yóò fi run. 24 Yóò fi àwọn ọba wọn lé e yín lọ́wọ́, ẹ̀yin ó sì pa orúkọ wọn rẹ́ lábẹ́ ọ̀run. Kò sí ẹni tí yóò lè dojú ìjà kọ yín títí tí ẹ ó fi pa wọ́n run. 25 Dá iná sun àwọn ère òrìṣà wọn, ẹ má ṣe ṣe ojúkòkòrò sí fàdákà tàbí wúrà tí ó wà lára wọn. Ẹ má ṣe mú un fún ara yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò jẹ́ ìdẹ̀kùn fún un yín, torí pé ìríra ni sí Olúwa Ọlọ́run yín. 26 Ẹ má ṣe mú ohun ìríra wá sí ilé yín, kí ìwọ má ba à di ẹni ìparun bí i rẹ̀. Ẹ kórìíra rẹ̀ kí ẹ sì kà á sí ìríra pátápátá, torí pé a yà á sọ́tọ̀ fún ìparun ni.

Read full chapter

12 If you pay attention to these laws and are careful to follow them, then the Lord your God will keep his covenant of love with you, as he swore to your ancestors.(A) 13 He will love you and bless you(B) and increase your numbers.(C) He will bless the fruit of your womb,(D) the crops of your land—your grain, new wine(E) and olive oil(F)—the calves of your herds and the lambs of your flocks in the land he swore to your ancestors to give you.(G) 14 You will be blessed more than any other people; none of your men or women will be childless, nor will any of your livestock be without young.(H) 15 The Lord will keep you free from every disease.(I) He will not inflict on you the horrible diseases you knew in Egypt,(J) but he will inflict them on all who hate you.(K) 16 You must destroy all the peoples the Lord your God gives over to you.(L) Do not look on them with pity(M) and do not serve their gods,(N) for that will be a snare(O) to you.

17 You may say to yourselves, “These nations are stronger than we are. How can we drive them out?(P) 18 But do not be afraid(Q) of them; remember well what the Lord your God did to Pharaoh and to all Egypt.(R) 19 You saw with your own eyes the great trials, the signs and wonders, the mighty hand(S) and outstretched arm, with which the Lord your God brought you out. The Lord your God will do the same to all the peoples you now fear.(T) 20 Moreover, the Lord your God will send the hornet(U) among them until even the survivors who hide from you have perished. 21 Do not be terrified by them, for the Lord your God, who is among you,(V) is a great and awesome God.(W) 22 The Lord your God will drive out those nations before you, little by little.(X) You will not be allowed to eliminate them all at once, or the wild animals will multiply around you. 23 But the Lord your God will deliver them over to you, throwing them into great confusion until they are destroyed.(Y) 24 He will give their kings(Z) into your hand,(AA) and you will wipe out their names from under heaven. No one will be able to stand up against you;(AB) you will destroy them.(AC) 25 The images of their gods you are to burn(AD) in the fire. Do not covet(AE) the silver and gold on them, and do not take it for yourselves, or you will be ensnared(AF) by it, for it is detestable(AG) to the Lord your God. 26 Do not bring a detestable thing into your house or you, like it, will be set apart for destruction.(AH) Regard it as vile and utterly detest it, for it is set apart for destruction.

Read full chapter

Ìbùkún fún ìgbọ́ràn

28 (A)Bí ìwọ bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ ní kíkún kí o sì kíyèsára láti tẹ̀lé gbogbo ohun tí ó pàṣẹ tí mo fi fún ọ lónìí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé ọ lékè ju gbogbo orílẹ̀-èdè ayé lọ. Gbogbo ìbùkún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ bí o bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ:

Ìbùkún ni fún ọ ni ìlú, ìbùkún ni fún ọ ní oko.

Ìbùkún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, àti irú ohun ọ̀sìn rẹ àti ìbísí i màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.

Ìbùkún ni fún agbọ̀n rẹ àti fún ọpọ́n ipò ìyẹ̀fun rẹ.

Ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá wọlé, ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.

Olúwa yóò gbà fún ọ pé gbogbo ọ̀tá tí ó dìde sí ọ yóò bì ṣubú níwájú rẹ. Wọn yóò tọ̀ ọ́ wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n wọn yóò sá fún ọ ní ọ̀nà méje.

Olúwa yóò rán ìbùkún sí ọ àti sí ohun gbogbo tí o bá dáwọ́ rẹ lé. Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún un fún ọ nínú ilẹ̀ tí ó ń fi fún ọ.

Olúwa yóò fi ọ́ múlẹ̀ bí ènìyàn mímọ́, bí ó ti ṣe ìlérí fún ọ lórí ìbúra, bí o bá pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ mọ́ tí o sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀. 10 Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé yóò rí i pé a pè ọ́ ní orúkọ Olúwa, wọn yóò sì bẹ̀rù rẹ. 11 Olúwa yóò fi àlàáfíà fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, fún ọmọ inú rẹ, irú ohun ọ̀sìn rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá rẹ láti fún ọ.

12 Olúwa yóò ṣí ọ̀run sílẹ̀, ìṣúra rere rẹ̀ fún ọ, láti rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ ní àsìkò rẹ àti láti bùkún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ. Ìwọ yóò yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ṣùgbọ́n ìwọ kò ní í yá lọ́wọ́ ẹnìkankan. 13 Olúwa yóò fi ọ́ ṣe orí, ìwọ kì yóò sì jẹ́ ìrù. Bí o bá fi etí sílẹ̀ sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ tí mo fi fún ọ kí o sì máa rọra tẹ̀lé wọn, ìwọ yóò máa wà lókè, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò wà ní ìsàlẹ̀ láé. 14 Má ṣe yà sọ́tùn tàbí sósì kúrò, nínú èyíkéyìí àwọn àṣẹ tí mo fi fún ọ ní òní yìí, kí o má ṣe tẹ̀lé àwọn ọlọ́run mìíràn láti máa sìn wọ́n.

Read full chapter

Blessings for Obedience

28 If you fully obey the Lord your God and carefully follow(A) all his commands(B) I give you today, the Lord your God will set you high above all the nations on earth.(C) All these blessings will come on you(D) and accompany you if you obey the Lord your God:

You will be blessed(E) in the city and blessed in the country.(F)

The fruit of your womb will be blessed, and the crops of your land and the young of your livestock—the calves of your herds and the lambs of your flocks.(G)

Your basket and your kneading trough will be blessed.

You will be blessed when you come in and blessed when you go out.(H)

The Lord will grant that the enemies(I) who rise up against you will be defeated before you. They will come at you from one direction but flee from you in seven.(J)

The Lord will send a blessing on your barns and on everything you put your hand to. The Lord your God will bless(K) you in the land he is giving you.

The Lord will establish you as his holy people,(L) as he promised you on oath, if you keep the commands(M) of the Lord your God and walk in obedience to him. 10 Then all the peoples on earth will see that you are called by the name(N) of the Lord, and they will fear you. 11 The Lord will grant you abundant prosperity—in the fruit of your womb, the young of your livestock(O) and the crops of your ground—in the land he swore to your ancestors to give you.(P)

12 The Lord will open the heavens, the storehouse(Q) of his bounty,(R) to send rain(S) on your land in season and to bless(T) all the work of your hands. You will lend to many nations but will borrow from none.(U) 13 The Lord will make you the head, not the tail. If you pay attention to the commands of the Lord your God that I give you this day and carefully follow(V) them, you will always be at the top, never at the bottom.(W) 14 Do not turn aside from any of the commands I give you today, to the right or to the left,(X) following other gods and serving them.

Read full chapter