Add parallel Print Page Options

Ìlú ààbò

19 (A)Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá ti pa àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò fi ilẹ̀ wọn fún ọ run, àti nígbà tí ìwọ bá ti lé wọn jáde tí o sì dó sí àwọn ilẹ̀ àti ilé wọn gbogbo. Ìwọ yóò ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ fún ara à rẹ láàrín ilẹ̀ rẹ tí Olúwa Ọlọ́run fún ọ láti ni. Ṣe àwọn ọ̀nà sí wọn àti kí o pín ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún sí ọ̀nà mẹ́ta nítorí kí apànìyàn lè sá níbẹ̀.

Èyí ni òfin nípa apànìyàn, tí ó sì sá síbẹ̀ láti pa ẹ̀mí rẹ̀ mọ́. Ẹni tí ó pa aládùúgbò láìmọ̀ọ́mọ̀ṣeé láìjẹ́ pé ó ti ní àrankàn pẹ̀lú u rẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan lè lọ sínú igbó pẹ̀lú aládùúgbò rẹ̀ láti gé igi, bí ó sì ti gbé àáké e rẹ̀ láti gé igi náà lulẹ̀, bí àáké náà bá yọ tí ó sì bà aládùúgbò rẹ̀, tí òun sì kú. Ọkùnrin yìí lè sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú yìí láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lè máa lépa rẹ̀ nínú ìbínú, kí ó sì lé e bá nítorí pé ọ̀nà jì, kí ó sì pa á bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ sí ikú, nígbà tí ó ṣe é sí aládùúgbò rẹ̀ láìjẹ́ pé ó ti ní àrankàn pẹ̀lú u rẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́. Ìdí nìyìí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ fún ara rẹ.

Olúwa Ọlọ́run rẹ bá sì fẹ́ agbègbè rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba ńlá a yín, tí ó sì fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ti ṣe ìlérí fún wọn, nítorí tí ìwọ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tẹ̀lé gbogbo òfin yìí tí mo pàṣẹ fún ọ lónìí yìí, kí o fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì rìn ní ọ̀nà an rẹ̀ ní gbogbo ìgbà náà, kí o ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀. 10 Ṣe èyí kí a má ṣe ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ni ilẹ̀ rẹ, èyí tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, kí ìwọ kí ó má bá a jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ títa.

11 Ṣùgbọ́n tí ọkùnrin kan bá kórìíra arákùnrin rẹ̀, tí ó sì lúgọ dè é, tí ó mú u tí o lù ú pa, tí ọkùnrin náà sì sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú wọ̀nyí, 12 àwọn àgbàgbà ìlú rẹ yóò sì ránṣẹ́ pè é ìwọ, yóò sì mú un padà láti ìlú náà, wọn yóò sì fi í lé àwọn agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́ kí ó lè kú. 13 Má ṣe ṣàánú fún un. O ní láti fọ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò ni Israẹli, kí ó bá à lè dára fún ọ.

14 Má ṣe pa òkúta ààlà aládùúgbò rẹ dà tí aṣíwájú rẹ fi lélẹ̀ nínú ogún tí ó gbà nínú ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ láti ni ní ìní.

Ẹlẹ́rìí

15 (B)Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo kò tó láti dájọ́ ọkùnrin kan tí o fi ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ yóò wù kí ó lè ṣẹ̀ lẹ́bi. A ó fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ láti orí ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta.

16 (C)Tí alárankàn ẹlẹ́rìí èké bá dúró láti fi ẹ̀sùn ẹ̀ṣẹ̀ kan ọkùnrin kan, 17 àwọn méjèèjì tí àríyànjiyàn wà láàrín wọn gbọdọ̀ dúró níwájú Olúwa níwájú àwọn àlùfáà àti àwọn adájọ́ tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní ìgbà náà. 18 Àwọn adájọ́ gbọdọ̀ ṣe ìwádìí fínní fínní bí ẹ̀rí bá sì jẹ́ irọ́, tí ó fi ẹ̀rí èké sun arákùnrin rẹ̀, 19 (D)nígbà náà ni kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fẹ́ ṣe sí arákùnrin rẹ̀. O ní láti wẹ búburú kúrò láàrín rẹ. 20 Àwọn ènìyàn tókù yóò gbọ́ nípa èyí, wọn yóò sì bẹ̀rù, kí irú nǹkan búburú bẹ́ẹ̀ máa tún sẹ̀ mọ́ láàrín yín. 21 (E)Má ṣe fi àánú hàn, ẹ̀mí fún ẹ̀mí, ojú fún ojú, eyín fún eyín, apá fún apá, ẹsẹ̀ fún ẹsẹ̀.