Add parallel Print Page Options

12 (A)(B) Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.

Read full chapter

15 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa baba tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pa á.

Read full chapter

17 (A)“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pa á.

Read full chapter

(A)“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé baba tàbí ìyá rẹ̀ ni kí ẹ pa, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí ara rẹ̀ torí pé ó ti ṣépè lé baba àti ìyá rẹ̀.

Read full chapter

16 (A)(B) Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ, bí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún ọ, kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́, àti kí ó lè dára fún ọ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.

Read full chapter

Ọlọ̀tẹ̀ ọmọ

18 (A)Bí ọkùnrin kan bá ní aláìgbọ́ràn tàbí ọlọ̀tẹ̀ ọmọ tí kò gbọ́rọ̀ sí baba àti ìyá rẹ̀ tí kò sì ní í gbà tí wọ́n bá ń bá a wí, 19 baba àti ìyá rẹ̀ yóò gbá a mú, wọn yóò mu wá fún àwọn àgbàgbà ní ẹnu-bodè ìlú u rẹ̀. 20 Wọn yóò sì wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Ọmọ wa yìí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀. Kò ní gbọ́rọ̀ sí wa lẹ́nu. Ọ̀jẹun àti ọ̀mùtí para ni.” 21 Nígbà náà ni gbogbo ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò sọ ọ́ ní òkúta pa. Ìwọ yóò sì mú ìwà ibi kúrò láàrín yín, gbogbo Israẹli yóò gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n.

Read full chapter