Add parallel Print Page Options

Àgbàlá

(A)“Ìwọ yóò sì ṣe àgbàlá fún àgọ́ náà. Ní ìhà gúúsù gbọdọ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ (mítà mẹ́rìn-dínláàádọ́ta) ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́, 10 pẹ̀lú ogún (20) òpó àti ogún (20) ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà, kí ó sì di àwọn òpó mú. 11 Kí ìhà àríwá náà jẹ́ mítà mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa, pẹ̀lú ogun (20) òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà tí ó sì di àwọn òpó mú.

12 “Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, kí ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá. 13 Ní ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn tí ń jáde, àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, 14 Aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní gíga ní yóò wà ní ìhà ẹnu-ọ̀nà, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta, 15 Àti aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní gíga yóò wá ní ìhà kejì, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta.

16 “Àti fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà, pèsè aṣọ títa, mítà mẹ́sàn-án ní gíga, ti aláró, elése àlùkò, ti òdòdó, àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe, pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin. 17 Gbogbo òpó ti ó wà ní àyíká àgbàlá náà ni a ó fi fàdákà ṣo pọ̀ àti ìkọ́, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ. 18 Àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ni gíga àti mítà mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, pẹ̀lú aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn mítà méjì ní gíga, àti pẹ̀lú ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ. 19 Gbogbo irú iṣẹ́ tí ó wà kí ó ṣe, papọ̀ pẹ̀lú gbogbo èèkàn àgọ́ náà àti fún tí àgbàlá náà, kí ó jẹ́ idẹ.

Read full chapter