Add parallel Print Page Options

Àwọn aṣọ Àlùfáà mìíràn

31 (A)“Ìwọ yóò ṣì ṣe aṣọ ìgúnwà ẹ̀wù efodu náà ní kìkì aṣọ aláró, 32 pẹ̀lú ojú ọrùn kí ó wà láàrín rẹ̀ fún orí. Kí iṣẹ́ ọ̀nà wà létí rẹ̀ bí ìṣẹ́tí yí i ká bí agbádá, kí ó má ba à ya. 33 Ṣe pomegiranate ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò àti ti òdòdó yí ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká, pẹ̀lú ṣaworo wúrà láàrín wọn. 34 Àwọn ṣaworo wúrà àti àwọn pomegiranate ni kí ó yí ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká.

Read full chapter