Add parallel Print Page Options

(A)Ẹ gòkè lọ sí ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin. Ṣùgbọ́n èmi kò ní lọ pẹ̀lú yín, nítorí ènìyàn ọlọ́rùn líle ni ẹ̀yin, kí èmi má ba à run yín ní ọ̀nà.”

Read full chapter

Nítorí Olúwa ti wí fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ènìyàn ọlọ́rùn líle ní ẹ̀yin, bí èmi bá lè wá sí àárín yín ni ìṣẹ́jú kan, èmi lè pa yín run. Ní ṣinṣin yìí, bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ rẹ kúrò, èmi yóò sì gbèrò ohun tí èmi yóò ṣe pẹ̀lú rẹ.’ ”

Read full chapter

26 Ejibiti, Juda, Edomu, Ammoni, Moabu àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní ọ̀nà jíjìn réré ní aginjù. Nítorí pé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jẹ́ aláìkọlà gbogbo àwọn ará ilé Israẹli sì jẹ́ aláìkọlà ọkàn.”

Read full chapter

10 Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti
    tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn? Ta ni
yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi? Etí wọn
    ti di, nítorí náà wọn kò lè gbọ́.
Ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ ohun búburú sí wọn,
    wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀.

Read full chapter

14 nítorí nígbà tí ìlú ṣọ̀tẹ̀ níbi omi ní Aginjù Sini, tí gbogbo yín ṣe àìgbọ́ràn sí mi láti yà mí sí mímọ́ níwájú wọn.” (Èyí ni omi Meriba ní Kadeṣi ní aginjù Sini.)

Read full chapter

10 Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ṣọ̀tẹ̀
    wọ́n sì ba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ nínú jẹ́.
Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà ó sì di ọ̀tá wọn
    òun tìkára rẹ̀ sì bá wọn jà.

Read full chapter