Add parallel Print Page Options

Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, sọ fún àwọn àgbàgbà Israẹli, kì ó sì wí fún wọn pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ṣe ki ẹ lè wádìí lọ́dọ̀ mi ni ẹ ṣe wá? Bí mo ti wà láààyè, ní Olúwa Olódùmarè wí, Èmi kì yóò gbà kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi.’

“Ìwọ fẹ́ dájọ́ wọn bí? Ìwọ fẹ́ dájọ́ wọn bí ọmọ ènìyàn? Nítorí náà fi gbogbo ìwà ìríra baba wọn kò wọ́n lójú, kí ó sì sọ fún wọn pé: ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ tí mo yàn Israẹli, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ìbúra sí àwọn ọmọ ilé Jakọbu, mo sì fi ara mi hàn wọn ní Ejibiti, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ẹ̀jẹ́ wí pé, “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.” Ní ọjọ́ náà mo lọ búra fún wọn pé, èmi yóò mú wọn jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti lọ sí ilẹ̀ ti mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrín àwọn ilẹ̀ yòókù. Mo sì wí fún wọn pé, “Kí olúkúlùkù nínú yín gbé ìríra ojú rẹ̀ kúrò, kí ẹ sì má bá sọ ara yín di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà Ejibiti, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”

“ ‘Ṣùgbọ́n wọn ṣọ̀tẹ̀ sí mi wọn kò sì gbọ́rọ̀, wọn kò gbé àwòrán ìríra tí wọ́n dojúkọ kúrò níwájú wọn bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si kọ̀ àwọn òrìṣà Ejibiti sílẹ̀, torí náà mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí, èmi yóò sì jẹ́ kí ìbínú mi sẹ̀ lórí wọn ní ilẹ̀ Ejibiti. Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń gbé láàrín wọn, lójú àwọn ẹni tí mo ti fi ara hàn fún ara Israẹli nípa mímú wọn jáde ní ilẹ̀ Ejibiti. 10 Nítorí náà, mo mú wọn jáde ní ilẹ̀ Ejibiti mo sì mú wọn wá sínú aginjù. 11 Mo sì fún wọn ni òfin mi, mo sì fi àwọn òfin mi hàn wọ́n; nítorí pé ẹni tó bá ṣe wọ́n yóò yè nípa wọn. 12 Bẹ́ẹ̀ ni mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ààmì láàrín àwọn àti èmi, kí wọn lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa tó sọ wọn di mímọ́.

13 “ ‘Síbẹ̀; ilé Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí mí nínú aginjù. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sì kọ àwọn òfin mi sílẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá pa á mọ́ yóò yè nínú rẹ̀. Wọn sì sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Nítorí náà, mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú gbígbóná mi sórí wọn, èmi yóò sì pa wọ́n run nínú aginjù. 14 Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní mú kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo kó wọn jáde. 15 Nítorí náà, mo tún gbọ́wọ́ mi sókè ní ìbúra fún wọn nínú aginjù pé, èmi kì yóò mú wọn dé ilẹ̀ tí mo fi fún wọn—ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrín àwọn ilẹ̀ yòókù. 16 Nítorí pé, wọn kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sọ ọjọ́ ìsinmi mi dí aláìmọ́. Nítorí pé tọkàntọkàn ni wọn ń tẹ̀lé òrìṣà wọn. 17 Síbẹ̀síbẹ̀ mo wò wọ́n pẹ̀lú àánú, ń kò sì pa wọ́n run tàbí kí òpin dé bá wọn nínú aginjù.

Read full chapter

Then the word of the Lord came to me: “Son of man, speak to the elders(A) of Israel and say to them, ‘This is what the Sovereign Lord says: Have you come to inquire(B) of me? As surely as I live, I will not let you inquire of me, declares the Sovereign Lord.(C)

“Will you judge them? Will you judge them, son of man? Then confront them with the detestable practices of their ancestors(D) and say to them: ‘This is what the Sovereign Lord says: On the day I chose(E) Israel, I swore with uplifted hand(F) to the descendants of Jacob and revealed myself to them in Egypt. With uplifted hand I said to them, “I am the Lord your God.(G) On that day I swore(H) to them that I would bring them out of Egypt into a land I had searched out for them, a land flowing with milk and honey,(I) the most beautiful of all lands.(J) And I said to them, “Each of you, get rid of the vile images(K) you have set your eyes on, and do not defile yourselves with the idols(L) of Egypt. I am the Lord your God.(M)

“‘But they rebelled against me and would not listen to me;(N) they did not get rid of the vile images they had set their eyes on, nor did they forsake the idols of Egypt.(O) So I said I would pour out my wrath on them and spend my anger against them in Egypt.(P) But for the sake of my name, I brought them out of Egypt.(Q) I did it to keep my name from being profaned(R) in the eyes of the nations among whom they lived and in whose sight I had revealed myself to the Israelites. 10 Therefore I led them out of Egypt and brought them into the wilderness.(S) 11 I gave them my decrees and made known to them my laws, by which the person who obeys them will live.(T) 12 Also I gave them my Sabbaths(U) as a sign(V) between us,(W) so they would know that I the Lord made them holy.(X)

13 “‘Yet the people of Israel rebelled(Y) against me in the wilderness. They did not follow my decrees but rejected my laws(Z)—by which the person who obeys them will live—and they utterly desecrated my Sabbaths.(AA) So I said I would pour out my wrath(AB) on them and destroy(AC) them in the wilderness.(AD) 14 But for the sake of my name I did what would keep it from being profaned(AE) in the eyes of the nations in whose sight I had brought them out.(AF) 15 Also with uplifted hand I swore(AG) to them in the wilderness that I would not bring them into the land I had given them—a land flowing with milk and honey, the most beautiful of all lands(AH) 16 because they rejected my laws(AI) and did not follow my decrees and desecrated my Sabbaths. For their hearts(AJ) were devoted to their idols.(AK) 17 Yet I looked on them with pity and did not destroy(AL) them or put an end to them in the wilderness.

Read full chapter