Add parallel Print Page Options

Àwọn ẹsẹ̀ Jerusalẹmu

22 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

“Ọmọ ènìyàn ǹjẹ́ ìwọ yóò ha ṣe ìdájọ́ rẹ̀? Ǹjẹ́ ìwọ ha ṣe ìdájọ́ ìlú atàjẹ̀sílẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀ dojúkọ wọn pẹ̀lú gbogbo ìwà ìríra wọn. Kí ó sì wí pé: ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ìwọ ìlú ńlá tí ó mú ìparun wá sórí ara rẹ nípa títàjẹ̀sílẹ̀ ní àárín rẹ, tí ó sì ba ara rẹ̀ jẹ́ nípa ṣíṣe àwọn ère, Ìwọ ti jẹ̀bi nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀, àti pé àwọn ère tí ó ṣe tí bà ọ́ jẹ́. Ìwọ tí mú ọjọ́ rẹ súnmọ́ tòsí, ìparí àwọn ọdún rẹ sì ti dé. Nítorí náà èmi yóò fi ọ ṣe ohun ẹ̀gàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè àti ohun ẹ̀sín lójú gbogbo ìlú. Àwọn tí ó wà ní tòsí àti àwọn tí ó jìnnà sí ọ, yóò fi ọ ṣe ẹlẹ́yà, ìwọ ìlú ẹlẹ́gàn, tí ó kún fún làálàá.

“ ‘Wo bí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin ọba Israẹli tí ó wà nínú yín ti ń lo agbára rẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀. Nínú rẹ wọn ti hùwà sí baba àti ìyá pẹ̀lú ìfojú tínrín; nínú rẹ wọn ti ni àwọn àlejò lára, wọn sì hùwàkiwà sí aláìní baba àti opó. Ìwọ tí kọ àwọn ohun mímọ́ mi sílẹ̀, ìwọ sì ti lo ọjọ́ ìsinmi mi ní ìlòkulò. Nínú rẹ ni àwọn ayannijẹ ènìyàn pinnu láti tàjẹ̀ sílẹ̀; nínú rẹ ní àwọn tí ó ń jẹun ní orí òkè ojúbọ òrìṣà, wọn sì hùwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. 10 Nínú rẹ ní àwọn ti kò bu ọlá fún àwọn àkéte baba wọn; nínú rẹ ni àwọn tí o ń bá àwọn obìnrin lò nígbà tí wọ́n ń ṣe àkókò lọ́wọ́, ní àsìkò tí a ka wọn sì aláìmọ́. 11 Nínú rẹ ọkùnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ìríra pẹ̀lú aya aládùúgbò rẹ̀, òmíràn bá ìyàwó ọmọ rẹ̀ jẹ́, òmíràn sì bá arábìnrin rẹ̀ lòpọ̀ èyí tí í ṣe ọbàkan rẹ̀. 12 (A)Nínú rẹ àwọn ènìyàn gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀; ìwọ gba èlé lọ́pọ̀pọpọ̀ láti mú aláìṣòótọ́ jèrè láti ara aládùúgbò rẹ nípa ìrẹ́jẹ. Ìwọ sì ti gbàgbé èmi; ni Olúwa Olódùmarè wí.

13 “ ‘Èmi yóò kúkú pàtẹ́wọ́ lórí èrè àìmọ̀ tí ìwọ ti jẹ, àti lórí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀ ní àárín yín. 14 Ọkàn rẹ le gbà á, tàbí ọwọ́ rẹ lè le, ní ọjọ́ tí èmi yóò bá ọ ṣé? Èmi Olúwa ó ti sọ̀rọ̀, Èmi yóò sì ṣe é. 15 Èmi yóò tú yin ká ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò fọ́n ọ ká sí àwọn ìlú; èmi yóò sì fi òpin sí àìmọ́ rẹ. 16 Nígbà tí a ó bà ọ́ jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”

17 Nígbà náà ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 18 “Ọmọ ènìyàn, ilé Israẹli ti di ìdàrọ́ sí mi; gbogbo wọn jẹ́ bàbà, idẹ, irin àti òjé ti a fi sínú iná ìléru. Wọn jẹ́ ìdàrọ́ ti fàdákà. 19 Nítorí náà èyí yìí ni ohun ti Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí tí ìwọ ti di ìdàrọ́, èmi yóò kó yín jọ sí Jerusalẹmu. 20 Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń kó fàdákà, bàbà, irin, òjé àti idẹ jọ sínú iná ìléru láti fi iná yọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò kó ọ jọ ní ìbínú àti ìrunú mi, èmi yóò sì fi ọ sì àárín ìlú, èmi yóò sì yọ́ ọ. Níbẹ̀ ní ìwọ yóò sì ti yọ́. 21 Èmi yóò kó yín jọ, èmi o sì fín iná ìbínú mi si yin lára, ẹ o si di yíyọ́ láàrín rẹ̀. 22 Bí a ti ń yọ́ fàdákà nínú iná ìléru bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ìwọ yóò ṣe yọ́ nínú rẹ̀, ìwọ yóò sì mọ̀ wí pé èmi Olúwa ti tú ìbínú mi sórí rẹ.’ ”

23 Lẹ́ẹ̀kan sí i ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé, 24 “Ọmọ ènìyàn, sọ fún ilẹ̀ náà, ‘Ìwọ ní ilẹ̀ tí kò gbá mọ́, ti kò sì rọ òjò tàbí ìrì ní àkókò ìbínú.’ 25 Ìdìtẹ̀ sì wà láàrín àwọn ọmọ-aládé inú rẹ̀, tó dàbí bíbú kìnnìún tó ń fà ẹran ya, wọ́n ń ba àwọn ènìyàn jẹ́, wọ́n ń kó ìṣúra àti àwọn ohun iyebíye wọ́n sì ń sọ púpọ̀ di opó nínú rẹ̀. 26 Àwọn àlùfáà rẹ̀ ti rú òfin mi, wọn si ti sọ ohun mímọ́ mi di àìlọ́wọ̀: wọn kò fi ìyàtọ̀ sáàrín ohun mímọ́ àti àìlọ́wọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi ìyàtọ̀ hàn láàrín ohun àìmọ́, àti mímọ́, wọn sì ti fi ojú wọn pamọ́ kúrò ní ọjọ́ ìsinmi mi, mó sì dí ẹni àìlọ́wọ̀ láàrín wọn. 27 Àwọn ọmọ-aládé àárín rẹ̀ dàbí ìkookò ti ń ṣọdẹ, láti tàjẹ̀ sílẹ̀, láti pa ọkàn run, láti jèrè àìṣòótọ́. 28 Àti àwọn wòlíì rẹ́ ti ṣẹ̀tàn sí wọn, wọn ń rì ìran asán, wọn sì ń fọ àfọ̀ṣẹ èké sí wọn, wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí,’ nígbà tí ó ṣépè Olúwa kò sọ̀rọ̀. 29 Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, tí lo ìwà ìninilára, wọn sì já olè, wọn sì ni àwọn tálákà àti aláìní lára; nítòótọ́, wọn tí ní àlejò lára láìnídìí. Kò sì ṣí ìdájọ́ òdodo.

30 “Èmi si wá ẹnìkan láàrín wọn, tí ìbá tún odi náà mọ́, tí ìbá dúró ní ibi tí ó ya náà níwájú mi fún ilẹ̀ náà, kí èmi má bá à parun: ṣùgbọ́n èmi kò rí ẹnìkan. 31 Nítorí náà ni mo ṣe da ìbínú mi sí wọn lórí, mo ti fi iná ìbínú mi run wọn, mo si ti fi ọ̀nà wọn gbẹ̀san lórí ara wọn, ní Olúwa Olódùmarè wí.”

Judgment on Jerusalem’s Sins

22 The word of the Lord came to me:

“Son of man, will you judge her? Will you judge this city of bloodshed?(A) Then confront her with all her detestable practices(B) and say: ‘This is what the Sovereign Lord says: You city that brings on herself doom by shedding blood(C) in her midst and defiles herself by making idols, you have become guilty because of the blood you have shed(D) and have become defiled by the idols you have made. You have brought your days to a close, and the end of your years has come.(E) Therefore I will make you an object of scorn(F) to the nations and a laughingstock to all the countries.(G) Those who are near and those who are far away will mock you, you infamous city, full of turmoil.(H)

“‘See how each of the princes of Israel who are in you uses his power to shed blood.(I) In you they have treated father and mother with contempt;(J) in you they have oppressed the foreigner(K) and mistreated the fatherless and the widow.(L) You have despised my holy things and desecrated my Sabbaths.(M) In you are slanderers(N) who are bent on shedding blood;(O) in you are those who eat at the mountain shrines(P) and commit lewd acts.(Q) 10 In you are those who dishonor their father’s bed;(R) in you are those who violate women during their period,(S) when they are ceremonially unclean.(T) 11 In you one man commits a detestable offense with his neighbor’s wife,(U) another shamefully defiles his daughter-in-law,(V) and another violates his sister,(W) his own father’s daughter.(X) 12 In you are people who accept bribes(Y) to shed blood; you take interest(Z) and make a profit from the poor. You extort unjust gain from your neighbors.(AA) And you have forgotten(AB) me, declares the Sovereign Lord.(AC)

13 “‘I will surely strike my hands(AD) together at the unjust gain(AE) you have made and at the blood(AF) you have shed in your midst.(AG) 14 Will your courage endure(AH) or your hands(AI) be strong in the day I deal with you? I the Lord have spoken,(AJ) and I will do it.(AK) 15 I will disperse you among the nations and scatter(AL) you through the countries; and I will put an end to(AM) your uncleanness.(AN) 16 When you have been defiled[a] in the eyes of the nations, you will know that I am the Lord.’”

17 Then the word of the Lord came to me: 18 “Son of man, the people of Israel have become dross(AO) to me; all of them are the copper, tin, iron and lead left inside a furnace.(AP) They are but the dross of silver.(AQ) 19 Therefore this is what the Sovereign Lord says: ‘Because you have all become dross,(AR) I will gather you into Jerusalem. 20 As silver, copper, iron, lead and tin are gathered into a furnace to be melted with a fiery blast, so will I gather you in my anger and my wrath and put you inside the city and melt you.(AS) 21 I will gather you and I will blow(AT) on you with my fiery wrath, and you will be melted inside her.(AU) 22 As silver is melted(AV) in a furnace, so you will be melted inside her, and you will know that I the Lord have poured out my wrath(AW) on you.’”(AX)

23 Again the word of the Lord came to me: 24 “Son of man, say to the land, ‘You are a land that has not been cleansed or rained on in the day of wrath.’(AY) 25 There is a conspiracy(AZ) of her princes[b] within her like a roaring lion(BA) tearing its prey; they devour people,(BB) take treasures and precious things and make many widows(BC) within her. 26 Her priests do violence to my law(BD) and profane my holy things; they do not distinguish between the holy and the common;(BE) they teach that there is no difference between the unclean and the clean;(BF) and they shut their eyes to the keeping of my Sabbaths, so that I am profaned(BG) among them.(BH) 27 Her officials(BI) within her are like wolves(BJ) tearing their prey; they shed blood and kill people(BK) to make unjust gain.(BL) 28 Her prophets whitewash(BM) these deeds for them by false visions and lying divinations.(BN) They say, ‘This is what the Sovereign Lord says’—when the Lord has not spoken.(BO) 29 The people of the land practice extortion and commit robbery;(BP) they oppress the poor and needy and mistreat the foreigner,(BQ) denying them justice.(BR)

30 “I looked for someone among them who would build up the wall(BS) and stand before me in the gap on behalf of the land so I would not have to destroy it, but I found no one.(BT) 31 So I will pour out my wrath on them and consume them with my fiery anger,(BU) bringing down(BV) on their own heads all they have done, declares the Sovereign Lord.(BW)

Footnotes

  1. Ezekiel 22:16 Or When I have allotted you your inheritance
  2. Ezekiel 22:25 Septuagint; Hebrew prophets