Add parallel Print Page Options

32 “Èyí yìí ní ohun ti Olúwa Olódùmarè:

“Ìwọ yóò mu nínú ago ẹ̀gbọ́n rẹ,
    ago tí ó tóbi tí ó sì jinnú:
yóò mú ìfiṣẹ̀sín àti ìfiṣe ẹlẹ́yà wá,
    nítorí tí ago náà gba nǹkan púpọ̀.

Read full chapter

33 Ìwọ yóò mu àmupara àti ìbànújẹ́,
    ago ìparun àti ìsọdahoro
    ago ẹ̀gbọ́n rẹ Samaria.

Read full chapter

12 Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn ṣe fojú tó agbo ẹran rẹ̀ tí ó fọ́nká nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe fojú tó àgùntàn mi. Èmi yóò gbá wọn kúrò ni gbogbo ibi tí wọ́n fọ́nká sí ni ọjọ́ ìkùùkuu àti òkùnkùn.

Read full chapter

15 Èmi fúnra mi yóò darí àgùntàn mi, èmi yóò mú wọn dùbúlẹ̀, ni Olúwa Olódùmarè wí.

Read full chapter

16 (A)Èmi yóò ṣe àwárí àwọn tí ó nú, èmi yóò mú àwọn tí ó ń rin ìrìn àrè kiri padà. Èmi yóò di ọgbẹ́ àwọn tí ó fi ara pa, èmi yóò sì fún àwọn aláìlágbára ni okun, ṣùgbọ́n àwọn tí ó sanra tí ó sì ni agbára ní èmi yóò parun. Èmi yóò ṣe olùṣọ́ àwọn agbo ẹran náà pẹ̀lú òdodo.

Read full chapter