Add parallel Print Page Options

16 (A)Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ-aládé etí Òkun yóò sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn yóò sì pa àwọn aṣọ ìgúnwà wọn da, tì wọn yóò sì bọ́ àwọn aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ kúrò. Ẹ̀rù yóò bò wọ́n, wọn yóò sì jókòó lórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀, wọn yóò sì máa wárìrì ní gbogbo ìgbà, ẹnu yóò sì yà wọ́n sí ọ́. 17 Nígbà náà wọn yóò gbóhùn ẹkún sókè nítorí rẹ, wọn yóò sì wí fún ọ pé:

“ ‘Báwo ni a ṣe pa ọ́ run, ìwọ ìlú olókìkí
    ìwọ tí àwọn èrò okun ti gbé inú rẹ̀!
Ìwọ jẹ alágbára lórí okun gbogbo
    òun àti àwọn olùgbé inú rẹ̀;
ìwọ gbé ẹ̀rù rẹ
    lórí gbogbo olùgbé ibẹ̀.

Read full chapter