Add parallel Print Page Options

Esekiẹli gẹ́gẹ́ bi olùṣọ́ Israẹli

33 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: “Ọmọ ènìyàn sọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn ilẹ̀ rẹ kí ó sì sọ fún wọn: ‘Nígbà tí mo bá fi idà kọlu ilẹ̀ kan, tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yan ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin wọn láti jẹ́ alóre wọn, tí ó sì rí i pé idà ń bọ̀ lórí ilẹ̀ náà, tí ó sì fọn ìpè láti kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, nígbà náà tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ìpè ṣùgbọ́n tí kò gbọ́ ìkìlọ̀, tí idà náà wá tí ó sì gba ẹ̀mí rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà lórí ara rẹ̀. Nítorí tí ó gbọ́ ohùn ìpè ṣùgbọ́n tí kò sì gbọ́ ìkìlọ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní orí ara rẹ̀: Tí ó bá gbọ́ ìkìlọ̀, òun ìbá ti gba ara rẹ̀ là. Ṣùgbọ́n bí alóre bá rí idà tí o ń bọ̀, tí kò sì fọn ìpè láti ki àwọn ènìyàn nílọ̀, tí idà náà wá, tí ó sì gba ẹ̀mí ọ̀kan nínú wọn, a yóò mú ọkùnrin náà lọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n èmi yóò béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.’

“Ọmọ ènìyàn, èmi fi ọ ṣe alóre fún ilé Israẹli; nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo sọ, kí o sì fún wọn ni ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi. Nígbà ti mo bá sọ fún ẹni búburú pé, ‘A! Ẹni búburú, ìwọ yóò kú dandan,’ ti ìwọ kò sì sọ̀rọ̀ síta láti yí i lọ́kàn padà kúrò ni ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ẹni búburú náà yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èmi yóò sì béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá kìlọ̀ fún ẹni búburú láti yí padà kúrò ni ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, tí òun kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, òun yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ti gba ọkàn rẹ̀ là.

Read full chapter