Add parallel Print Page Options

Dariusi rí ìwé àṣẹ Sairusi

Nígbà náà ni ọba Dariusi pàṣẹ, wọ́n sì wá inú ilé ìfí-nǹkan-pamọ́-sí ní ilé ìṣúra ní Babeli. A rí ìwé kíká kan ní Ekbatana ibi kíkó ìwé sí ní ilé olódi agbègbè Media, wọ̀nyí ni ohun tí a kọ sínú rẹ̀:

Ìwé ìrántí:

(A)Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba ọba Kirusi, ọba pa àṣẹ kan nípa tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu:

Jẹ́ kí a tún tẹmpili ibi tí a ti ń rú onírúurú ẹbọ kọ́, kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ni gíga àti fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ àádọ́rùn-ún ẹsẹ̀ bàtà, pẹ̀lú ipele òkúta ńláńlá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ipele pákó kan, kí a san owó rẹ̀ láti inú ilé ìṣúra ọba. Sì jẹ́ kí wúrà àti àwọn ohun èlò fàdákà ti ilé Ọlọ́run, tí Nebukadnessari kó láti ilé Olúwa ní Jerusalẹmu tí ó sì kó lọ sí Babeli, di dídápadà sí ààyè wọn nínú tẹmpili ní Jerusalẹmu; kí a kó wọn sí inú ilé Ọlọ́run.

Nítorí náà, kí ìwọ, Tatenai baálẹ̀ agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹlẹgbẹ́ yín, àwọn ìjòyè ti agbègbè náà kúrò níbẹ̀. Ẹ fi iṣẹ́ ilé Ọlọ́run yìí lọ́rùn sílẹ̀ láì dí i lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí baálẹ̀ àwọn Júù àti àwọn àgbàgbà Júù tún ilé Ọlọ́run yín kọ́ sí ipò rẹ̀.

Síwájú sí i, mo pàṣẹ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe fún àwọn àgbàgbà Júù wọ̀nyí lórí kíkọ́ ilé Ọlọ́run yìí:

Gbogbo ìnáwó àwọn ọkùnrin yìí ni kí ẹ san lẹ́kùnrẹ́rẹ́ lára ìṣúra ti ọba, láti ibi àkójọpọ̀ owó ìlú ti agbègbè Eufurate kí iṣẹ́ náà má bà dúró. Ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́—àwọn ọ̀dọ́ akọ màlúù, àwọn àgbò, ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun sí Ọlọ́run ọ̀run, àti jéró, iyọ̀, wáìnì àti òróró, bí àwọn àlùfáà ní Jerusalẹmu ti béèrè ni ẹ gbọdọ̀ fún wọn lójoojúmọ́ láìyẹ̀. 10 Kí wọn lè rú àwọn ẹbọ tí ó tẹ́ Ọlọ́run ọ̀run lọ́rùn kí wọ́n sì gbàdúrà fún àlàáfíà ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀:

11 Síwájú sí i, mo pàṣẹ pé tí ẹnikẹ́ni bá yí àṣẹ yìí padà, kí fa igi àjà ilé rẹ̀ yọ jáde, kí a sì gbe dúró, kí a sì fi òun náà kọ́ sí orí rẹ̀ kí ó wo ilé rẹ̀ palẹ̀ a ó sì sọ ọ́ di ààtàn. 12 Kí Ọlọ́run, tí ó ti jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ máa gbé ibẹ̀, kí ó pa gbogbo ọba àti orílẹ̀-èdè rún tí ó bá gbé ọwọ́ sókè láti yí àṣẹ yìí padà tàbí láti wó tẹmpili yìí tí ó wà ní Jerusalẹmu run.

Èmi Dariusi n pàṣẹ rẹ̀, jẹ́ kí ó di mímúṣẹ láìyí ohunkóhun padà.

Píparí àti yíya tẹmpili sí mímọ́

13 Nígbà náà, nítorí àṣẹ tí ọba Dariusi pa, Tatenai, Baálẹ̀ ti agbègbè Eufurate, àti Ṣetar-bosnai pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pa á mọ́ láìyí ọ̀kan padà. 14 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbàgbà Júù tẹ̀síwájú wọ́n sì ń gbèrú sí i lábẹ́ ìwàásù wòlíì Hagai àti wòlíì Sekariah, ìran Iddo. Wọ́n parí kíkọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run Israẹli àti àwọn àṣẹ Kirusi, Dariusi àti Artasasta àwọn ọba Persia pọ̀. 15 A parí ilé Olúwa ní ọjọ́ kẹta, oṣù Addari (oṣù kejì) ní ọdún kẹfà ti ìjọba ọba Dariusi.

16 Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Israẹli—àwọn àlùfáà, àwọn Lefi àti àwọn ìgbèkùn tí ó padà, ṣe ayẹyẹ yíya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀. 17 Fún yíya ilé Ọlọ́run yìí sí mímọ́, wọ́n pa ọgọ́rùn-ún akọ màlúù (100), ọgọ́rùn-ún méjì àgbò (200) àti ọgọ́ọ̀rún mẹ́rin akọ ọ̀dọ́-àgùntàn (400), àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Israẹli, àgbò méjìlá (12), ọ̀kọ̀ọ̀kan fún olúkúlùkù àwọn ẹ̀yà Israẹli. 18 Wọ́n sì fi àwọn àlùfáà sí àwọn ìpín wọ́n àti àwọn Lefi sì ẹgbẹẹgbẹ́ wọn fún ìsin ti Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé Mose.

Àjọ ìrékọjá

19 Ní ọjọ́ kẹrìnlá ti oṣù Nísàn (oṣù kẹrin), àwọn tí a kó ní ìgbèkùn ṣe ayẹyẹ àjọ ìrékọjá. 20 Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì jẹ́ mímọ́. Àwọn ará Lefi pa ọ̀dọ́-àgùntàn ti àjọ ìrékọjá fún gbogbo àwọn tí a kó ní ìgbèkùn, fún àwọn àlùfáà arákùnrin wọn àti fún ara wọn. 21 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó ti dé láti ìgbèkùn jẹ ẹ́ lápapọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ti ya ara wọn kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ àìmọ́ ti àwọn kèfèrí aládùúgbò wọn láti wá Olúwa Ọlọ́run Israẹli. 22 Fún ọjọ́ méje, wọ́n ṣe ayẹyẹ àkàrà àìwú pẹ̀lú àjẹtì àkàrà. Nítorí tí Olúwa ti kún wọn pẹ̀lú ayọ̀ nípa yíyí ọkàn ọba Asiria padà, tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ ilé Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.

The Decree of Darius

King Darius then issued an order, and they searched in the archives(A) stored in the treasury at Babylon. A scroll was found in the citadel of Ecbatana in the province of Media, and this was written on it:

Memorandum:

In the first year of King Cyrus, the king issued a decree concerning the temple of God in Jerusalem:

Let the temple be rebuilt as a place to present sacrifices, and let its foundations be laid.(B) It is to be sixty cubits[a] high and sixty cubits wide, with three courses(C) of large stones and one of timbers. The costs are to be paid by the royal treasury.(D) Also, the gold(E) and silver articles of the house of God, which Nebuchadnezzar took from the temple in Jerusalem and brought to Babylon, are to be returned to their places in the temple in Jerusalem; they are to be deposited in the house of God.(F)

Now then, Tattenai,(G) governor of Trans-Euphrates, and Shethar-Bozenai(H) and you other officials of that province, stay away from there. Do not interfere with the work on this temple of God. Let the governor of the Jews and the Jewish elders rebuild this house of God on its site.

Moreover, I hereby decree what you are to do for these elders of the Jews in the construction of this house of God:

Their expenses are to be fully paid out of the royal treasury,(I) from the revenues(J) of Trans-Euphrates, so that the work will not stop. Whatever is needed—young bulls, rams, male lambs for burnt offerings(K) to the God of heaven, and wheat, salt, wine and olive oil, as requested by the priests in Jerusalem—must be given them daily without fail, 10 so that they may offer sacrifices pleasing to the God of heaven and pray for the well-being of the king and his sons.(L)

11 Furthermore, I decree that if anyone defies this edict, a beam is to be pulled from their house and they are to be impaled(M) on it. And for this crime their house is to be made a pile of rubble.(N) 12 May God, who has caused his Name to dwell there,(O) overthrow any king or people who lifts a hand to change this decree or to destroy this temple in Jerusalem.

I Darius(P) have decreed it. Let it be carried out with diligence.

Completion and Dedication of the Temple

13 Then, because of the decree King Darius had sent, Tattenai, governor of Trans-Euphrates, and Shethar-Bozenai and their associates(Q) carried it out with diligence. 14 So the elders of the Jews continued to build and prosper under the preaching(R) of Haggai the prophet and Zechariah, a descendant of Iddo. They finished building the temple according to the command of the God of Israel and the decrees of Cyrus,(S) Darius(T) and Artaxerxes,(U) kings of Persia. 15 The temple was completed on the third day of the month Adar, in the sixth year of the reign of King Darius.(V)

16 Then the people of Israel—the priests, the Levites and the rest of the exiles—celebrated the dedication(W) of the house of God with joy. 17 For the dedication of this house of God they offered(X) a hundred bulls, two hundred rams, four hundred male lambs and, as a sin offering[b] for all Israel, twelve male goats, one for each of the tribes of Israel. 18 And they installed the priests in their divisions(Y) and the Levites in their groups(Z) for the service of God at Jerusalem, according to what is written in the Book of Moses.(AA)

The Passover

19 On the fourteenth day of the first month, the exiles celebrated the Passover.(AB) 20 The priests and Levites had purified themselves and were all ceremonially clean. The Levites slaughtered(AC) the Passover lamb for all the exiles, for their relatives the priests and for themselves. 21 So the Israelites who had returned from the exile ate it, together with all who had separated themselves(AD) from the unclean practices(AE) of their Gentile neighbors in order to seek the Lord,(AF) the God of Israel. 22 For seven days they celebrated with joy the Festival of Unleavened Bread,(AG) because the Lord had filled them with joy by changing the attitude(AH) of the king of Assyria so that he assisted them in the work on the house of God, the God of Israel.

Footnotes

  1. Ezra 6:3 That is, about 90 feet or about 27 meters
  2. Ezra 6:17 Or purification offering