Add parallel Print Page Options

21 Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sùn fọnfọn; nígbà tí ó sì ń sùn, Ọlọ́run yọ egungun ìhà rẹ̀ kan, ó sì fi ẹran-ara bò ó padà. 22 Olúwa Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, Ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá.

23 Ọkùnrin náà sì wí pé,

“Èyí ni egungun láti inú egungun mi
    àti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi;
‘obìnrin’ ni a ó máa pè é,
    nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.”

Read full chapter