Add parallel Print Page Options

Manase àti Efraimu

48 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ si, a wí fún Josẹfu pé, “Baba rẹ ń ṣàìsàn,” nítorí náà, ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, Manase àti Efraimu lọ́wọ́ lọ pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí a sọ fún Jakọbu pé, “Josẹfu ọmọ rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,” Israẹli rọ́jú dìde jókòó lórí ibùsùn rẹ̀.

(A)Jakọbu wí fún Josẹfu pé, “Ọlọ́run Olódùmarè (Eli-Ṣaddai) fi ara hàn mí ní Lusi ní ilẹ̀ Kenaani, níbẹ̀ ni ó sì ti súre fún mi. Ó sì wí fún mi pé, ‘Èmi yóò mú kí o bí sí i, ìwọ yóò sì pọ̀ sí i, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, Èmi yóò sì fún ìwọ àti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun ìní ayérayé.’

“Nítorí náà báyìí, àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tí a bí fún ọ ní ilẹ̀ Ejibiti, kí èmi kí ó tó tọ̀ ọ́ wá ní ìhín, ni mo sọ di ọmọ mi fúnra mi. Manase àti Efraimu yóò jẹ́ tèmi gẹ́gẹ́ bí Reubeni àti Simeoni ti jẹ́ tèmi. Àwọn ọmọ mìíràn tí ìwọ bá bí lẹ́yìn wọn yóò jẹ́ ọmọ rẹ. Ní ilẹ̀ tí wọn yóò jogún, orúkọ arákùnrin wọn ni a ó máa fi pè wọ́n. (B)Bí mo ti ń padà láti Padani, Rakeli kú ní ọ̀nà nígbà tí ó ṣì wà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí tó mú ìbànújẹ́ bá mi, níbi tí kò jìnnà sí Efrata: Nítorí náà èmí sì sin ín sí ẹ̀bá ọ̀nà tí ó lọ sí Efrata” (tí ṣe Bẹtilẹhẹmu).

Nígbà tí Israẹli rí àwọn ọmọ Josẹfu, ó béèrè wí pé, “Àwọn wo nìyí?”

Josẹfu fún baba rẹ̀ lésì pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi fún mi ní ìhín.”

Nígbà náà ni Israẹli wí pé, “Kó wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi kí èmi kí ó ba à le súre fún wọn.”

10 Báyìí, ojú Israẹli ti ń di bàìbàì nítorí ogbó, agbára káká sì ni ó fi ń ríran. Josẹfu sì kó àwọn ọmọ rẹ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, baba rẹ̀ fẹnukò wọ́n ni ẹnu, ó sì dì mọ́ wọn.

11 Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Èmi kò lérò rárá pé, mo tún le rí ojú rẹ mọ́ láéláé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tún fún mi ní àǹfààní, mo sì tún rí àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú.”

12 Nígbà náà ni Josẹfu kó àwọn ọmọ náà kúrò ní orí eékún baba rẹ̀, ó wólẹ̀, ó sì tẹríba. 13 Josẹfu sì mú àwọn méjèèjì, Efraimu ni o fi sí ọwọ́ ọ̀tún òun tìkára rẹ̀, èyí tí í ṣe ọwọ́ òsì fún Israẹli, ó sì fi Manase sí ọwọ́ òsì ara rẹ̀, èyí tí ó bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún Israẹli. 14 Israẹli sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jáde, ó sì gbe lé Efraimu lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni àbúrò, ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ tàsé ara wọn, ó sì na ọwọ́ òsì lé Manase lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Manase ni àkọ́bí.

15 Nígbà náà ni ó súre fún Josẹfu wí pé,

“Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run, ẹni tí baba mi
    Abrahamu àti Isaaki rìn níwájú rẹ̀,
Ọlọ́run tí ó ti jẹ́ olùtọ́jú àti aláàbò
    mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí di òní,
16 Angẹli tí ó dá mi ní ìdè kúrò lọ́wọ́ gbogbo ewu,
    kí ó súre fún àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí.
Kí a máa fi orúkọ mi pè wọ́n àti orúkọ àwọn baba mi
    Abrahamu àti Isaaki,
kí wọn kí ó sì pọ̀ sí i lọ́pọ̀lọpọ̀
    lórí ilẹ̀ ayé.”

17 Nígbà tí Josẹfu rí i pé baba òun gbé ọwọ́ ọ̀tún lé Efraimu lórí, inú rẹ̀ bàjẹ́, ó sì gbá ọwọ́ baba rẹ̀ mú láti gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lórí Efraimu lọ sí orí Manase. 18 Josẹfu wí fun pé, “Rárá, baba mi, èyí ni àkọ́bí, orí rẹ̀ ni kí ìwọ kí o gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé.”

19 Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà, ó wí pé, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀. Òun náà yóò di orílẹ̀-èdè, òun náà yóò sì di ńlá. Ṣùgbọ́n àbúrò rẹ̀ yóò di ẹni ńlá jù ú lọ, irú-ọmọ rẹ yóò sì di ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.” 20 (C)Ó súre fún wọn lọ́jọ́ náà pé,

“Ní orúkọ yín ni Israẹli yóò máa súre yìí pé:
    ‘Kí Ọlọ́run ṣe ọ́ bí i ti Efraimu àti Manase.’ ”

Ó sì gbé Efraimu gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n sí Manase.

21 Nígbà náà ni Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Ọjọ́ ikú mi súnmọ́ etílé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò wà pẹ̀lú yín, yóò sì mú un yín padà sí ilẹ̀ àwọn baba yín. 22 Pẹ̀lúpẹ̀lú èmi yóò fún ọ ní ìpín kan ju ti àwọn arákùnrin rẹ lọ. Ilẹ̀ tí mo fi idà àti ọ̀kọ̀ mi gbà lọ́wọ́ àwọn ará Amori.”

Manasseh and Ephraim

48 Some time later Joseph was told, “Your father is ill.” So he took his two sons Manasseh and Ephraim(A) along with him. When Jacob was told, “Your son Joseph has come to you,” Israel(B) rallied his strength and sat up on the bed.

Jacob said to Joseph, “God Almighty[a](C) appeared to me at Luz(D) in the land of Canaan, and there he blessed me(E) and said to me, ‘I am going to make you fruitful and increase your numbers.(F) I will make you a community of peoples, and I will give this land(G) as an everlasting possession to your descendants after you.’(H)

“Now then, your two sons born to you in Egypt(I) before I came to you here will be reckoned as mine; Ephraim and Manasseh will be mine,(J) just as Reuben(K) and Simeon(L) are mine. Any children born to you after them will be yours; in the territory they inherit they will be reckoned under the names of their brothers. As I was returning from Paddan,[b](M) to my sorrow(N) Rachel died in the land of Canaan while we were still on the way, a little distance from Ephrath. So I buried her there beside the road to Ephrath” (that is, Bethlehem).(O)

When Israel(P) saw the sons of Joseph,(Q) he asked, “Who are these?”

“They are the sons God has given me here,”(R) Joseph said to his father.

Then Israel said, “Bring them to me so I may bless(S) them.”

10 Now Israel’s eyes were failing because of old age, and he could hardly see.(T) So Joseph brought his sons close to him, and his father kissed them(U) and embraced them.(V)

11 Israel(W) said to Joseph, “I never expected to see your face again,(X) and now God has allowed me to see your children too.”(Y)

12 Then Joseph removed them from Israel’s knees(Z) and bowed down with his face to the ground.(AA) 13 And Joseph took both of them, Ephraim on his right toward Israel’s left hand and Manasseh on his left toward Israel’s right hand,(AB) and brought them close to him. 14 But Israel(AC) reached out his right hand and put it on Ephraim’s head,(AD) though he was the younger,(AE) and crossing his arms, he put his left hand on Manasseh’s head, even though Manasseh was the firstborn.(AF)

15 Then he blessed(AG) Joseph and said,

“May the God before whom my fathers
    Abraham and Isaac walked faithfully,(AH)
the God who has been my shepherd(AI)
    all my life to this day,
16 the Angel(AJ) who has delivered me from all harm(AK)
    —may he bless(AL) these boys.(AM)
May they be called by my name
    and the names of my fathers Abraham and Isaac,(AN)
and may they increase greatly
    on the earth.”(AO)

17 When Joseph saw his father placing his right hand(AP) on Ephraim’s head(AQ) he was displeased; so he took hold of his father’s hand to move it from Ephraim’s head to Manasseh’s head. 18 Joseph said to him, “No, my father, this one is the firstborn; put your right hand on his head.”(AR)

19 But his father refused and said, “I know, my son, I know. He too will become a people, and he too will become great.(AS) Nevertheless, his younger brother will be greater than he,(AT) and his descendants will become a group of nations.(AU) 20 He blessed(AV) them that day(AW) and said,

“In your[c] name will Israel(AX) pronounce this blessing:(AY)
    ‘May God make you like Ephraim(AZ) and Manasseh.(BA)’”

So he put Ephraim ahead of Manasseh.

21 Then Israel said to Joseph, “I am about to die, but God will be with you[d](BB) and take you[e] back to the land of your[f] fathers.(BC) 22 And to you I give one more ridge of land[g](BD) than to your brothers,(BE) the ridge I took from the Amorites with my sword(BF) and my bow.”

Footnotes

  1. Genesis 48:3 Hebrew El-Shaddai
  2. Genesis 48:7 That is, Northwest Mesopotamia
  3. Genesis 48:20 The Hebrew is singular.
  4. Genesis 48:21 The Hebrew is plural.
  5. Genesis 48:21 The Hebrew is plural.
  6. Genesis 48:21 The Hebrew is plural.
  7. Genesis 48:22 The Hebrew for ridge of land is identical with the place name Shechem.