Add parallel Print Page Options

29 (A)Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Filistia,
    pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá;
láti ibi gbòǹgbò ejò náà ni paramọ́lẹ̀
    yóò ti hù jáde,
    èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tí í jóni.
30 Ẹni tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù yóò ní pápá oko,
    àwọn aláìní yóò sì dùbúlẹ̀ láìléwu.
Ṣùgbọ́n gbòǹgbò o rẹ̀ ni èmi ó fi ìyàn parun,
    yóò sì ké àwọn ẹni rẹ tí ó sálà kúrò.

31 Hu, ìwọ ẹnu-ọ̀nà! Kígbe, Ìwọ ìlú!
    Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Filistia!
Èéfín kurukuru kan ti àríwá wá,
    kò sì ṣí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn.

Read full chapter

Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Filistia

15 (A)“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí pé: ‘Nítorí tí àwọn ará Filistini hùwà ẹ̀san tí wọ́n sì gbẹ̀san pẹ̀lú odì ní ọkàn wọn, àti pẹ̀lú ìkórìíra gbangba àtijọ́ ní wíwá ọ̀nà láti pa Juda run, 16 nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí pé: Èmi ti ṣetán láti na ọwọ́ mi jáde sí àwọn ará Filistini, èmi yóò sì ké àwọn ará Kereti kúrò, èmi yóò sì pa àwọn tí ó kù ní etí kún run. 17 Èmi yóò sì gbẹ̀san ńlá lára wọn nípa ìbáwí gbígbóná; wọn yóò sì mọ̀ wí pé, Èmi ni Olúwa. Nígbà tí èmi yóò gba ẹ̀san lára wọn.’ ”

Read full chapter

(A)Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Gasa,
    àní nítorí mẹ́rin,
Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà
    Gẹ́gẹ́ bí í oníṣòwò ẹrú,
ó kó gbogbo àwọn ènìyàn mi ní ìgbèkùn.
    Ó sì tà wọ́n fún Edomu,
Èmi yóò rán iná sí ara odi Gasa
    tí yóò jó gbogbo ààfin rẹ̀ run
Èmi yóò ké àwọn olùgbé Aṣdodu kúrò,
    ti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé ní Aṣkeloni mú.
Èmi yóò yí ọwọ́ mi sí Ekroni
    títí tí ìyókù Filistini yóò fi ṣègbé,”
    ni Olúwa Olódùmarè wí.

Read full chapter

Ìlòdì sí Filistia

(A)Nítorí pé, a ó kọ Gasa sílẹ̀,
    Aṣkeloni yóò sì dahoro.
Ní ọ̀sán gangan ni a ó lé Aṣdodu jáde,
    a ó sì fa Ekroni tu kúrò.
Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń gbé etí Òkun,
    ẹ̀yin ènìyàn ara Kereti;
Ọ̀rọ̀ Olúwa dojúkọ ọ́, ìwọ Kenaani,
    ilẹ̀ àwọn ara Filistini.
“Èmi yóò pa yín run,
    ẹnìkan kò sì ní ṣẹ́kù nínú yín.”
Ilẹ̀ náà ní etí Òkun, ni ibùgbé àwọn ará Kereti,
    ni yóò jẹ́ ibùjókòó fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn àti agbo àgùntàn.
Agbègbè náà yóò sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ilé Juda,
    níbẹ̀ ni wọn yóò sì ti rí koríko fún ẹran,
Ní ilé Aṣkeloni ni wọn yóò
    dùbúlẹ̀ ni àṣálẹ́.
Olúwa Ọlọ́run wọn yóò bẹ̀ wọn wò,
    yóò sì yí ìgbèkùn wọn padà.

Read full chapter

Aṣkeloni yóò rí í, yóò sì bẹ̀rù;
    Gasa pẹ̀lú yóò rí í, yóò sì káàánú gidigidi,
    àti Ekroni: nítorí tí ìrètí rẹ̀ yóò ṣákì í.
Gasa yóò pàdánù ọba rẹ̀,
    Aṣkeloni yóò sì di ahoro.
Ọmọ àlè yóò sì gbé inú Aṣdodu,
    Èmi yóò sì gé ìgbéraga àwọn Filistini kúrò.
Èmi yóò sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kúrò ni ẹnu rẹ̀,
    àti àwọn ohun èèwọ̀ kúrò láàrín eyín rẹ̀:
ṣùgbọ́n àwọn tó ṣẹ́kù yóò jẹ́ tí Ọlọ́run wa,
    wọn yóò sì jẹ baálẹ̀ ní Juda,
    àti Ekroni ni yóò rí bí Jebusi.

Read full chapter