Add parallel Print Page Options

Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Tire

23 (A)Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Tire:

Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi!
    Nítorí a ti pa Tire run
láìsí ilé tàbí èbúté.
    Láti ilẹ̀ Saipurọsi ni
    ọ̀rọ̀ ti wá sọ́dọ̀ wọn.

Dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù
    àti ẹ̀yin oníṣòwò ti Sidoni,
    ẹ̀yin tí àwọn a wẹ Òkun ti sọ dọlọ́rọ̀.
Láti orí àwọn omi ńlá
    ni irúgbìn ìyẹ̀fun ti ilẹ̀ Ṣihori ti wá
ìkórè ti odò Naili ni owóòná Tire,
    òun sì ti di ibùjókòó ọjà fún
    àwọn orílẹ̀-èdè.

Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ Sidoni àti ìwọ
    àní ìwọ ilé ààbò ti Òkun,
nítorí Òkun ti sọ̀rọ̀:
    “Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ rí
Èmi kò tí ì wo àwọn ọmọkùnrin
    tàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí.”
Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé Ejibiti,
    wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípa
    ìròyìn láti Tire.

Kọjá wá sí Tarṣiṣi;
    pohùnréré, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù.
Ǹjẹ́ èyí náà ni ìlú àríyá yín,
    ògbólógbòó ìlú náà,
èyí tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ti sìn ín lọ
    láti lọ tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré.
Ta ló gbèrò èyí sí Tire,
    ìlú aládé,
àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-aládé
    tí àwọn oníṣòwò wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míká
    ní orílẹ̀ ayé?
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti ṣètò rẹ̀,
    láti tẹrí ìgbéraga àti ògo rẹ ba
àti láti rẹ gbogbo àwọn ọlọ́lá
    ilé ayé sílẹ̀.

10 Tu ilẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí i ti ipadò odò Ejibiti,
    Ìwọ ọmọbìnrin Tarṣiṣi,
    nítorí ìwọ kò ní èbúté mọ́.
11 Olúwa ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí Òkun
    ó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.
Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Kenaani
    pé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run.
12 Ó wí pé, “Kò sí àríyá fún ọ mọ́”
    ìwọ wúńdíá ti Sidoni, tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀ báyìí!

“Gbéra, rékọjá lọ sí Saipurọsi,
    níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi.”
13 Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Babeli,
    àwọn ènìyàn tí kò jámọ́ nǹkan kan báyìí
Àwọn Asiria ti sọ ọ́ di
    ibùgbé àwọn ohun ẹranko aginjù;
wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gùn wọn sókè,
    wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòhò
    wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn.

14 Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi;
    wọ́n ti pa odi rẹ̀ run!

15 Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tire fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tire gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè:

16 “Mú dùùrù kan, rìn kọjá láàrín ìlú,
    Ìwọ àgbèrè tí a ti gbàgbé;
lu dùùrù dáradára, kọ ọ̀pọ̀ orin,
    kí a lè ba à rántí rẹ.”

17 (B)Ní òpin àádọ́rin ọdún náà, Olúwa yóò bá Tire jà. Òun yóò sì padà sí àyálò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí panṣágà, yóò sì máa ṣe òwò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ní ilẹ̀ ayé. 18 Síbẹ̀síbẹ̀ èrè rẹ̀ àti owó iṣẹ́ rẹ̀ ni a ó yà sọ́tọ̀ fún Olúwa; a kò ní kó wọn pamọ́ tàbí kí a há wọn mọ́wọ́. Ère rẹ̀ ni a ó fi fún àwọn tí ó ń gbé níwájú Olúwa, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti aṣọ.

(A)“Nísinsin yìí, kí ni ẹ̀yin ní fi mí ṣe Tire àti Sidoni, àti gbogbo ẹ̀yin ẹkún Filistia? Ẹ̀yin yóò ha sàn ẹ̀san fún mi? Bí ẹ̀yin bá sì san ẹ̀san fún mi, ní kánkán àti ní kíákíá ní èmi yóò san ẹ̀san ohun ti ẹ̀yin ṣe padà sórí ara yín. Nítorí tí ẹ̀yin tí mú fàdákà mi àti wúrà mi, ẹ̀yin si tí mú ohun rere dáradára mi lọ sínú tẹmpili yín. Àti àwọn ọmọ Juda, àti àwọn ọmọ Jerusalẹmu ní ẹ̀yin ti tà fún àwọn ará Giriki, kí ẹ̀yin bá à lè sí wọn jìnnà kúrò ní agbègbè ilẹ̀ ìní wọn.

“Kíyèsi í, èmi yóò gbé wọ́n dìde kúrò níbi tì ẹ̀yin ti tà wọ́n sí, èmi yóò sì san ẹ̀san ohun ti ẹ ṣe padà sórí ara yín. Èmi yóò si tà àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín sí ọwọ́ àwọn ọmọ Juda, wọ́n yóò sì tà wọ́n fún àwọn ara Sabeani, fún orílẹ̀-èdè kan tí ó jìnnà réré.” Nítorí Olúwa ní o ti sọ ọ.

Read full chapter

(A)Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Tire
    àní nítorí mẹ́rin, Èmi kì yóò yí ìpinnu ìjìyà mi padà.
Nítorí wọ́n ta gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìgbèkùn fún Edomu
    Wọn kò sì nání májẹ̀mú ọbàkan,
10 Èmi yóò rán iná sí ara odi Tire
    Tí yóò jó gbogbo àwọn ààfin rẹ̀ run.”

Read full chapter

Tire sì mọ odi líle fún ara rẹ̀,
    ó sì kó fàdákà jọ bí eruku,
    àti wúrà dáradára bí ẹrẹ̀ ìgboro.
Ṣùgbọ́n, Olúwa yóò kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ,
    yóò sì pa agbára rẹ̀ run ní ojú Òkun,
    a ó sì fi iná jó o run.

Read full chapter