Add parallel Print Page Options

Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé
    “Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù;
Ọlọ́run yín yóò wá,
    òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀san;
pẹ̀lú ìgbẹ̀san mímọ́
    òun yóò wá láti gbà yín là.”

Read full chapter

Aláìlera àti alágbára

14 Ẹ gba ẹni tí ó bá ṣe àìlera ní ìgbàgbọ́ mọ́ra, kí ẹ má ṣe tọpinpin ìṣeyèméjì rẹ̀.

Read full chapter

(A)Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ènìyàn lo mọ èyí: Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn tí ó ti ń bọ̀rìṣà lọ́jọ́ tó ti pẹ́ títí di ìsinsin yìí jẹ ẹ́ bí ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà; àti ẹ̀rí ọkàn wọn tí ó ṣe àìlera sì di aláìmọ́.

Read full chapter

Ìkìlọ̀ ní ṣíṣe ìmẹ́lẹ́

(A)Ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wa, àwa pàṣẹ fún un yín ará, pé kí ẹ yẹra fún gbogbo àwọn arákùnrin yín tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́, tí kò sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí ẹ gbà ní ọ̀dọ̀ wa.

Read full chapter

(A)Nítorí ẹ̀yin náà mọ̀ bí ó ṣe yẹ kí ẹ máa fi ara wé wa. Àwa kì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nígbà tí a wà ní ọ̀dọ̀ yín.

Read full chapter

11 (A)A gbọ́ pé àwọn kan wà láàrín yín tí wọn jẹ́ ìmẹ́lẹ́. Wọ́n jẹ́ atọjúlékiri.

Read full chapter