Add parallel Print Page Options

(A)“Nísinsin yìí, tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dá
    tí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹ
tí o sì ń sọ fún ara rẹ pé,
    ‘Èmi ni, kò sì ṣí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.
Èmi kì yóò di opó
    tàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’
(B)Méjèèjì yìí ni yóò wá sórí rẹ
    láìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà:
pípàdánù ọmọ àti dídi opó.
    Wọn yóò wá sórí rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,
pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹ
    àti àwọn èpè rẹ tí ko lágbára.

Read full chapter