Add parallel Print Page Options

(A)Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkè
    ẹsẹ̀ àwọn tí ó mú ìhìnrere ayọ̀ wá,
tí wọ́n kéde àlàáfíà,
    tí ó mú ìhìnrere wá,
tí ó kéde ìgbàlà,
    tí ó sọ fún Sioni pé,
    “Ọlọ́run rẹ ń jẹ ọba!”

Read full chapter

15 (A)Wò ó, lórí àwọn òkè,
    àwọn ẹsẹ̀ ẹni tí ó mú ìròyìn ayọ̀ wá,
    ẹni tí ó ń kéde àlàáfíà,
Ìwọ Juda, pa àṣẹ rẹ tí ó ní ìrònú mọ́,
    kí ó sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ.
Àwọn ènìyàn búburú kì yóò sì gbóguntì ọ́ mọ́;
    wọn yóò sì parun pátápátá.

Read full chapter

36 Ẹyin mọ ọrọ̀ tí Ọlọ́run rán sí àwọn ọmọ Israẹli láti kéde ìròyìn ayọ̀ àlàáfíà nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni ti ṣe Olúwa ohun gbogbo

Read full chapter

15 (A)Wọ́n ó ha sì ti ṣe wàásù, bí kò ṣe pé a rán wọn? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń wàásù ìhìnrere àlàáfíà ti dára tó, àwọn tí ń wàásù ìròyìn ayọ̀ ohun rere!”

Read full chapter