Add parallel Print Page Options

52 (A)Jí, jí, Ìwọ Sioni,
    wọ ara rẹ ní agbára.
Gbé aṣọ ògo rẹ wọ̀,
    ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́ n nì.
Àwọn aláìkọlà àti aláìmọ́
    kì yóò wọ inú rẹ mọ́.
Gbọn eruku rẹ kúrò;
    dìde sókè, kí o sì gúnwà, Ìwọ Jerusalẹmu.
Bọ́ ẹ̀wọ̀n tí ń bẹ lọ́rùn rẹ kúrò,
    ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin ìgbèkùn Sioni.

Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí;

    “Ọ̀fẹ́ ni a tà ọ́,
    láìsanwó ni a ó sì rà ọ́ padà.”

Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí.

“Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi sọ̀kalẹ̀
    lọ sí Ejibiti láti gbé;
    láìpẹ́ ni Asiria pọ́n wọn lójú.

(B)“Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí?” ni Olúwa wí.

“Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́,
    àwọn tí ó sì ń jẹ ọba lórí wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,”
    ni Olúwa wí.
“Àti ní ọjọọjọ́
    orúkọ mi ni asọ̀rọ̀-òdì sí nígbà gbogbo.
Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi;
    nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀
pé Èmi ni ó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀.
    Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.”

(C)Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkè
    ẹsẹ̀ àwọn tí ó mú ìhìnrere ayọ̀ wá,
tí wọ́n kéde àlàáfíà,
    tí ó mú ìhìnrere wá,
tí ó kéde ìgbàlà,
    tí ó sọ fún Sioni pé,
    “Ọlọ́run rẹ ń jẹ ọba!”
Tẹ́tí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn sókè
    wọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀.
Nígbà tí Olúwa padà sí Sioni,
    wọn yóò rí i pẹ̀lú ojú u wọn.
Ẹ bú sí orin ayọ̀ papọ̀,
    ẹ̀yin ahoro Jerusalẹmu,
nítorí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú,
    ó sì ti ra Jerusalẹmu padà.
10 (D)Olúwa yóò ṣí apá mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀
    ní ojú gbogbo orílẹ̀-èdè,
àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò rí
    ìgbàlà Ọlọ́run wa.

11 (E)Ẹ túká, ẹ túká, ẹ jáde kúrò níhìn-ín-yìí!
    Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan!
Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ kí ẹ sì di mímọ́,
    ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò Olúwa.
12 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò yára kúrò
    tàbí kí ẹ sáré lọ;
nítorí Olúwa ni yóò síwájú yín lọ,
    Ọlọ́run Israẹli ni yóò sì ṣe ààbò lẹ́yìn ín yín.

Ìpọ́njú àti ògo ìránṣẹ́ náà

13 Kíyèsi i, ìránṣẹ́ mi yóò hùwà ọlọ́gbọ́n;
    òun ni a ó gbé sókè tí a ó sì gbéga
    a ó sì gbé e lékè gidigidi.
14 Gẹ́gẹ́ bí a ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n ń bu ọlá fún un—
    ìwò ojú rẹ ni a ti bàjẹ́ kọjá ti ẹnikẹ́ni àti ìrísí rẹ̀ ní a ti bàjẹ́ kọjá ohun tí ènìyàn ń fẹ́.
15 (F)Bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe bomirin àwọn orílẹ̀-èdè ká,
    àwọn ọba yóò sì pa ẹnu wọn mọ́ nítorí rẹ̀.
Nítorí ohun tí a kò sọ fún wọn, wọn yóò rí i,
    àti ohun tí wọn kò tí ì gbọ́, ni yóò sì yé wọn.