Add parallel Print Page Options

64 Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá,
    tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ!
Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jó
    tí ó sì mú kí omi ó hó,
sọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mí mọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ
    kí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ!
Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí,
    o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ̀.
(A)Láti ìgbà àtijọ́ kò sí ẹni tí ó gbọ́ rí
    kò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ,
kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ,
    tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.
Ìwọ a máa wá fún ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọn
    ń fi ayọ̀ ṣe ohun tó tọ́,
tí ó rántí ọ̀nà rẹ.
    Ṣùgbọ́n nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀ sí wọn,
inú bí ọ.
    Báwo ni a ó ṣe gbà wá là?
Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́,
    gbogbo òdodo wa sì dàbí èkísà ẹlẹ́gbin;
gbogbo wa kákò bí ewé,
    àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò.
Ẹnikẹ́ni kò pe orúkọ rẹ
    tàbí kí ó gbìyànjú láti dì ẹ́ mú;
nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ fún wa
    ó sì jẹ́ kí àwa ṣòfò dànù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.

Síbẹ̀síbẹ̀, Olúwa, ìwọ ni Baba wa.
    Àwa ni amọ̀, ìwọ ni amọ̀kòkò;
    gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
Má ṣe bínú kọjá ààlà, ìwọ Olúwa:
    Má ṣe rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé.
Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà,
    nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa.
10 Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀;
    Sioni pàápàá di aṣálẹ̀, Jerusalẹmu di ahoro.
11 Tẹmpili mímọ́ ológo wa, níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́,
    ni a ti fi iná sun,
    àti ohun gbogbo tí í ṣe ìṣúra wa ti dahoro.
12 Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí, Olúwa, ìwọ
    ó ha sì tún fi ara rẹ pamọ́ bí?
    Ìwọ ó ha dákẹ́ kí o sì fìyà jẹ wá kọjá ààlà bí?