Add parallel Print Page Options

Hananiah wòlíì èké

28 Ní oṣù karùn-ún ní ọdún kan náà, ọdún kẹrin ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba Sedekiah ọba Juda, wòlíì Hananiah ọmọ Assuri, tí ó wá láti Gibeoni, sọ fún mi ní ilé Olúwa tí ó wà ní iwájú àwọn àlùfáà àti gbogbo ènìyàn: “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Èmi yóò mú àjàgà ọba Babeli rọrùn. Láàrín ọdún méjì, Èmi yóò mú gbogbo ohun èlò tí ọba Nebukadnessari; ọba Babeli kó kúrò ní ilé Olúwa tí ó sì kó lọ sí Babeli padà wá. Èmi á tún mú ààyè Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda padà, àti gbogbo àwọn tí ń ṣe àtìpó láti Juda ní Babeli,’ èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa pé, ‘àjàgà yín láti ọwọ́ ọba Babeli yóò rọrùn.’ ”

Wòlíì Jeremiah wí fún wòlíì Hananiah ní iwájú ọmọ àlùfáà àti àwọn ènìyàn tí wọ́n dúró ní ilé Olúwa. Jeremiah wòlíì wí pé, “Àmín! Kí Olúwa kí ó ṣe bẹ́ẹ̀! Kí Olúwa kí ó mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ìwọ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ, láti mú ohun èlò ilé Olúwa àti gbogbo àwọn ìgbèkùn láti ilẹ̀ Babeli padà wá sí ibí yìí. Nísinsin yìí, ìwọ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí tí mo sọ sí etí rẹ àti sí etí gbogbo ènìyàn. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn wòlíì tí ó ṣáájú rẹ àti èmi ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ogun, ibi àti àjàkálẹ̀ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Ṣùgbọ́n, àwọn wòlíì tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àlàáfíà ni a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì olóòtítọ́ tí Olúwa rán, tí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ bá wá sí ìmúṣẹ.”

10 Wòlíì Hananiah gbé àjàgà ọrùn wòlíì Jeremiah kúrò, ó sì fọ́ ọ. 11 Hananiah sọ níwájú gbogbo ènìyàn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Bákan náà ni Èmi yóò fọ́ àjàgà ọrùn Nebukadnessari, ọba Babeli láàrín ọdún méjì.’ ” Wòlíì Jeremiah sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ.

12 Láìpẹ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wòlíì wá lẹ́yìn ìgbà tí wòlíì Hananiah ti gbé àjàgà kúrò ní ọrùn wòlíì Jeremiah wí pé: 13 “Lọ sọ fún Hananiah, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Ìwọ ti wó àjàgà onígi, ṣùgbọ́n ní ààyè wọn, wà á bá àjàgà onírin. 14 Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Èmi yóò fi àjàgà onírin sí ọrùn gbogbo orílẹ̀-èdè láti lè máa sin Nebukadnessari ọba Babeli, àti pé gbogbo yín ni ẹ̀ ó máa sìn ín. Èmi yóò tún fún un ní àṣẹ lórí àwọn ẹranko búburú.’ ”

15 Wòlíì Jeremiah sọ fún wòlíì Hananiah pé, “Gbọ́ ọ, Hananiah! Olúwa kò rán ọ, síbẹ̀, ìwọ jẹ́ kí orílẹ̀-èdè yìí gba irọ́ gbọ́. 16 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Mo ṣetán láti mú ọ kúrò nínú ayé, ní ọdún yìí ni ìwọ yóò kú nítorí o ti wàásù ọ̀tẹ̀ sí Olúwa.’ ”

17 Ní oṣù keje ọdún yìí ni Hananiah wòlíì kú.

The False Prophet Hananiah

28 In the fifth month of that same year, the fourth year, early in the reign of Zedekiah(A) king of Judah, the prophet Hananiah son of Azzur, who was from Gibeon,(B) said to me in the house of the Lord in the presence of the priests and all the people: “This is what the Lord Almighty, the God of Israel, says: ‘I will break the yoke(C) of the king of Babylon. Within two years I will bring back to this place all the articles(D) of the Lord’s house that Nebuchadnezzar king of Babylon removed from here and took to Babylon. I will also bring back to this place Jehoiachin[a](E) son of Jehoiakim king of Judah and all the other exiles from Judah who went to Babylon,’ declares the Lord, ‘for I will break the yoke of the king of Babylon.’”(F)

Then the prophet Jeremiah replied to the prophet Hananiah before the priests and all the people who were standing in the house of the Lord. He said, “Amen! May the Lord do so! May the Lord fulfill the words you have prophesied by bringing the articles of the Lord’s house and all the exiles back to this place from Babylon.(G) Nevertheless, listen to what I have to say in your hearing and in the hearing of all the people: From early times the prophets who preceded you and me have prophesied war, disaster and plague(H) against many countries and great kingdoms. But the prophet who prophesies peace will be recognized as one truly sent by the Lord only if his prediction comes true.(I)

10 Then the prophet Hananiah took the yoke(J) off the neck of the prophet Jeremiah and broke it, 11 and he said(K) before all the people, “This is what the Lord says: ‘In the same way I will break the yoke of Nebuchadnezzar king of Babylon off the neck of all the nations within two years.’” At this, the prophet Jeremiah went on his way.

12 After the prophet Hananiah had broken the yoke off the neck of the prophet Jeremiah, the word of the Lord came to Jeremiah: 13 “Go and tell Hananiah, ‘This is what the Lord says: You have broken a wooden yoke, but in its place you will get a yoke of iron. 14 This is what the Lord Almighty, the God of Israel, says: I will put an iron yoke(L) on the necks of all these nations to make them serve(M) Nebuchadnezzar(N) king of Babylon, and they will serve him. I will even give him control over the wild animals.(O)’”

15 Then the prophet Jeremiah said to Hananiah the prophet, “Listen, Hananiah! The Lord has not sent(P) you, yet you have persuaded this nation to trust in lies.(Q) 16 Therefore this is what the Lord says: ‘I am about to remove you from the face of the earth.(R) This very year you are going to die,(S) because you have preached rebellion(T) against the Lord.’”

17 In the seventh month of that same year, Hananiah the prophet died.(U)

Footnotes

  1. Jeremiah 28:4 Hebrew Jeconiah, a variant of Jehoiachin