Add parallel Print Page Options

Ìlérí Ọlọ́run fún Baruku

45 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jeremiah wòlíì sọ fún Baruku ọmọ Neriah ní ọdún kẹrin ti Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda. Lẹ́yìn tí Baruku ti kọ sínú ìwé kíká àwọn ọ̀rọ̀ tí Jeremiah ti ń sọ: “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ fún ọ, Baruku: Ìwọ wí pé, ‘Ègbé ni fún mi! Olúwa ti fi ìbànújẹ́ kún ìrora mi; Àárẹ̀ mú mi nínú ẹ̀dùn mi, èmi kò sì rí ìsinmi.’ ” Olúwa wí pé sọ èyí fún un, “Èyí ni Ọlọ́run sọ: ‘Èyí tí èmi ti kọ́ ni èmi yóò wò lulẹ̀, àti èyí tí èmi ti gbìn ni èmi yóò fàtu, àní ní orí gbogbo ilẹ̀. Ṣé ìwọ sì ń wá ohun títóbi fún ara rẹ? Nítorí náà, má ṣe wá wọn. Èmi yóò mú ibi wá sí orí àwọn ènìyàn gbogbo ni Olúwa wí, ṣùgbọ́n níbikíbi tí ìwọ bá lọ ni èmi yóò jẹ́ kí o sá àsálà pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ.’ ”

A Message to Baruch

45 When Baruch(A) son of Neriah(B) wrote on a scroll(C) the words Jeremiah the prophet dictated in the fourth year of Jehoiakim(D) son of Josiah king of Judah, Jeremiah said this to Baruch: “This is what the Lord, the God of Israel, says to you, Baruch: You said, ‘Woe(E) to me! The Lord has added sorrow(F) to my pain;(G) I am worn out with groaning(H) and find no rest.’(I) But the Lord has told me to say to you, ‘This is what the Lord says: I will overthrow what I have built and uproot(J) what I have planted,(K) throughout the earth.(L) Should you then seek great(M) things for yourself? Do not seek them.(N) For I will bring disaster(O) on all people,(P) declares the Lord, but wherever you go I will let you escape(Q) with your life.’”(R)