Add parallel Print Page Options

Àwọn ìlú àwọn ọmọ Lefi

21 (A)Báyìí ni olórí ìdílé àwọn ọmọ Lefi lọ bá Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni àti olórí ẹ̀yà àwọn ìdílé ẹ̀yà Israẹli Ní Ṣilo, ní Kenaani, wọn sọ fún wọn pé, “Olúwa pàṣẹ nípasẹ̀ Mose pé kí wọn fún wa ní ìlú láti máa gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn wa.”

Àwọn ọmọ Israẹli sì fún àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú wọ̀nyí, àti ilẹ̀ pápá oko tútù lára ilẹ̀ ìní tiwọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Ìpín kìn-ín-ní wà fún àwọn ọmọ Kohati, ní agbo ilé, agbo ilé. Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ ọmọ Aaroni àlùfáà ni a pín ìlú mẹ́tàlá fún láti ara ẹ̀yà Juda, Simeoni àti Benjamini.

Ìyókù àwọn ọmọ Kohati ni a pín ìlú mẹ́wàá fún láti ara ẹ̀yà Efraimu, Dani àti ìdajì Manase.

Àwọn ẹ̀yà Gerṣoni ni a pín ìlú mẹ́tàlá fún láti ara ẹ̀yà Isakari, Aṣeri, Naftali àti ìdajì ẹ̀yà Manase ní Baṣani.

Àwọn ọmọ Merari ní agbo ilé, agbo ilé ni wọ́n fún ní ìlú méjìlá láti ara ẹ̀yà Reubeni, Gadi àti Sebuluni.

Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli pín ìlú wọ̀nyí àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ẹnu Mose.

Láti ara ẹ̀yà Juda àti ẹ̀yà Simeoni ni wọ́n ti pín àwọn ìlú tí a dárúkọ wọ̀nyí, 10 (Ìlú wọ̀nyí ni a fún àwọn ọmọ Aaroni tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú ìdílé Kohati tí í ṣe ọmọ Lefi, nítorí tí ìpín àkọ́kọ́ jẹ́ tiwọn).

11 Wọ́n fún wọn ní Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni), pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù tí ó yí wọn ká, ní ilẹ̀ òkè Juda. (Arba ni baba ńlá Anaki.) 12 Ṣùgbọ́n àwọn oko àti àwọn abúlé ní agbègbè ìlú náà ni wọ́n ti fi fún Kalebu ọmọ Jefunne gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ̀. 13 Ní àfikún wọ́n sì fún àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ní Hebroni (ọ̀kan nínú ìlú ààbò fún àwọn apànìyàn) pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù rẹ̀, Libina, 14 Jattiri, Eṣitemoa, 15 Holoni àti Debiri, 16 Aini, Jutta àti Beti-Ṣemeṣi, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn. Ìlú mẹ́sàn-án láti ara ẹ̀yà méjì wọ̀nyí.

17 Láti ara ẹ̀yà Benjamini ni wọ́n ti fún wọn ní:

Gibeoni, Geba, 18 Anatoti àti Almoni, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.

19 Gbogbo ìlú àwọn àlùfáà, ìran Aaroni jẹ́ mẹ́tàlá pẹ̀lú ilẹ̀ pápá wọn.

20 Ìyókù ìdílé Kohati tí ó jẹ́ ọmọ Lefi ní a pín ìlú fún láti ara ẹ̀yà Efraimu.

21 Ní ilẹ̀ òkè Efraimu wọ́n fún wọn ní:

Ṣekemu (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn) àti Geseri, 22 Kibasaimu àti Beti-Horoni, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú mẹ́rin.

23 Láti ara ẹ̀yà Dani ni wọ́n ti fún wọn ní:

Elteke, Gibetoni, 24 Aijaloni àti Gati-Rimoni, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn jẹ́ ìlú mẹ́rin.

25 Láti ara ìdajì ẹ̀yà Manase ni wọ́n ti fún wọn ní:

Taanaki àti Gati-Rimoni pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú méjì.

26 Gbogbo ìlú mẹ́wẹ̀ẹ̀wá yìí àti ilẹ̀ pápá wọn ni a fi fún ìyókù ìdílé Kohati.

27 Àwọn ọmọ Gerṣoni ìdílé àwọn ọmọ Lefi ni wọ́n fún lára:

ìdajì ẹ̀yà Manase,

Golani ní Baṣani (ìlú ààbò fún apànìyàn) àti Be-Eṣterah pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọ́n jẹ́ méjì;

28 Láti ara ẹ̀yà Isakari ni wọ́n ti fún wọn ní,

Kiṣioni Daberati, 29 Jarmatu àti Eni-Gannimu, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.

30 Láti ara ẹ̀yà Aṣeri ni wọ́n ti fún wọn ní

Miṣali, àti Abdoni, 31 Helikati àti Rehobu, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin;

32 Láti ara ẹ̀yà Naftali ni a ti fún wọn ní:

Kedeṣi ní Galili (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn), Hamoti Dori àti Karitani, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́ta.

33 Gbogbo ìlú tí ó jẹ́ ti ọmọ Gerṣoni jẹ́ mẹ́tàlá, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn.

34 Láti ara ẹ̀yà Sebuluni ni a ti fún ìdílé Merari (tí í ṣe ìyókù ọmọ Lefi) ní:

Jokneamu, Karta, 35 Dimina àti Nahalali, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.

36 Láti ara ẹ̀yà Reubeni ni wọ́n ti fún wọn ní

Beseri, àti Jahisa, 37 Kedemoti àti Mefaati, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.

38 Láti ara ẹ̀yà Gadi ni wọ́n ti fún wọn ní

Ramoti ní Gileadi (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn), Mahanaimu, 39 Heṣboni àti Jaseri, e pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.

40 Gbogbo ìlú tí wọ́n pín fún àwọn ọmọ Merari tí wọ́n jẹ́ ìyókù àwọn ọmọ Lefi jẹ́ méjìlá.

41 Gbogbo ìlú àwọn ọmọ Lefi tó wà láàrín ara ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ méjì-dínláádọ́ta lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko wọn. 42 Ọ̀kọ̀ọ̀kan ìlú wọ̀nyí ni ó ni ilẹ̀ pápá oko tí ó yí ì ká, bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún gbogbo ìlú wọ̀nyí.

43 Báyìí ni Olúwa fún Israẹli ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ṣèlérí láti fi fún àwọn baba ńlá wọn. Nígbà tí wọ́n sì gbà á tan wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀. 44 Olúwa sì fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún baba ńlá wọn. Kò sì sí ọ̀kankan nínú àwọn ọ̀tá wọn tí ó lè dojúkọ wọ́n. Olúwa sì fi gbogbo àwọn ọ̀tá wọn lé wọn ní ọwọ́. 45 Kò sí ọ̀kan nínú ìlérí rere tí Olúwa ṣe fún ilé Israẹli tí ó kùnà; Gbogbo rẹ̀ ni ó ṣe.

Towns for the Levites(A)

21 Now the family heads of the Levites approached Eleazar the priest, Joshua son of Nun, and the heads of the other tribal families of Israel(B) at Shiloh(C) in Canaan and said to them, “The Lord commanded through Moses that you give us towns(D) to live in, with pasturelands for our livestock.”(E) So, as the Lord had commanded, the Israelites gave the Levites the following towns and pasturelands out of their own inheritance:

The first lot came out for the Kohathites,(F) according to their clans. The Levites who were descendants of Aaron the priest were allotted thirteen towns from the tribes of Judah, Simeon and Benjamin.(G) The rest of Kohath’s descendants were allotted ten towns from the clans of the tribes of Ephraim, Dan and half of Manasseh.(H)

The descendants of Gershon(I) were allotted thirteen towns from the clans of the tribes of Issachar,(J) Asher,(K) Naphtali and the half-tribe of Manasseh in Bashan.

The descendants of Merari,(L) according to their clans, received twelve(M) towns from the tribes of Reuben, Gad and Zebulun.(N)

So the Israelites allotted to the Levites these towns and their pasturelands, as the Lord had commanded through Moses.

From the tribes of Judah and Simeon they allotted the following towns by name 10 (these towns were assigned to the descendants of Aaron who were from the Kohathite clans of the Levites, because the first lot fell to them):

11 They gave them Kiriath Arba(O) (that is, Hebron(P)), with its surrounding pastureland, in the hill country of Judah. (Arba was the forefather of Anak.) 12 But the fields and villages around the city they had given to Caleb son of Jephunneh as his possession.(Q)

13 So to the descendants of Aaron the priest they gave Hebron (a city of refuge(R) for one accused of murder), Libnah,(S) 14 Jattir,(T) Eshtemoa,(U) 15 Holon,(V) Debir,(W) 16 Ain,(X) Juttah(Y) and Beth Shemesh,(Z) together with their pasturelands—nine towns from these two tribes.

17 And from the tribe of Benjamin they gave them Gibeon,(AA) Geba,(AB) 18 Anathoth(AC) and Almon, together with their pasturelands—four towns.

19 The total number of towns(AD) for the priests, the descendants of Aaron, came to thirteen, together with their pasturelands.(AE)

20 The rest of the Kohathite clans of the Levites were allotted towns from the tribe of Ephraim:

21 In the hill country of Ephraim they were given Shechem(AF) (a city of refuge for one accused of murder) and Gezer,(AG) 22 Kibzaim and Beth Horon,(AH) together with their pasturelands—four towns.(AI)

23 Also from the tribe of Dan they received Eltekeh, Gibbethon,(AJ) 24 Aijalon(AK) and Gath Rimmon,(AL) together with their pasturelands—four towns.

25 From half the tribe of Manasseh they received Taanach(AM) and Gath Rimmon, together with their pasturelands—two towns.

26 All these ten towns and their pasturelands were given to the rest of the Kohathite clans.(AN)

27 The Levite clans of the Gershonites were given:

from the half-tribe of Manasseh,

Golan in Bashan(AO) (a city of refuge for one accused of murder(AP)) and Be Eshterah, together with their pasturelands—two towns;

28 from the tribe of Issachar,(AQ)

Kishion,(AR) Daberath,(AS) 29 Jarmuth(AT) and En Gannim,(AU) together with their pasturelands—four towns;

30 from the tribe of Asher,(AV)

Mishal,(AW) Abdon,(AX) 31 Helkath and Rehob,(AY) together with their pasturelands—four towns;

32 from the tribe of Naphtali,

Kedesh(AZ) in Galilee (a city of refuge for one accused of murder(BA)), Hammoth Dor and Kartan, together with their pasturelands—three towns.

33 The total number of towns of the Gershonite(BB) clans came to thirteen, together with their pasturelands.

34 The Merarite clans (the rest of the Levites) were given:

from the tribe of Zebulun,(BC)

Jokneam,(BD) Kartah, 35 Dimnah and Nahalal,(BE) together with their pasturelands—four towns;

36 from the tribe of Reuben,

Bezer,(BF) Jahaz,(BG) 37 Kedemoth and Mephaath,(BH) together with their pasturelands—four towns;

38 from the tribe of Gad,

Ramoth(BI) in Gilead(BJ) (a city of refuge for one accused of murder), Mahanaim,(BK) 39 Heshbon and Jazer,(BL) together with their pasturelands—four towns in all.

40 The total number of towns allotted to the Merarite clans, who were the rest of the Levites, came to twelve.(BM)

41 The towns of the Levites in the territory held by the Israelites were forty-eight in all, together with their pasturelands.(BN) 42 Each of these towns had pasturelands surrounding it; this was true for all these towns.

43 So the Lord gave Israel all the land he had sworn to give their ancestors,(BO) and they took possession(BP) of it and settled there.(BQ) 44 The Lord gave them rest(BR) on every side, just as he had sworn to their ancestors. Not one of their enemies(BS) withstood them; the Lord gave all their enemies(BT) into their hands.(BU) 45 Not one of all the Lord’s good promises(BV) to Israel failed; every one was fulfilled.