Add parallel Print Page Options

14 Nígbà tí àwọn ènìyàn gbéra láti ibùdó láti kọjá nínú odò Jordani, àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí náà ń lọ níwájú wọn. 15 Odò Jordani sì máa ń wà ní kíkún ní gbogbo ìgbà ìkórè. Ṣùgbọ́n bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí ti dé odò Jordani tí ẹsẹ̀ wọn sì kan etí omi, 16 omi tí ń ti òkè sàn wá dúró. Ó sì gbá jọ bí òkìtì ní òkèèrè, ní ìlú tí a ń pè ní Adamu, tí ó wà ní tòsí Saretani; nígbà tí omi tí ń sàn lọ sínú Òkun aginjù, (Òkun Iyọ̀) gé kúrò pátápátá. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kọjá sí òdìkejì ní ìdojúkọ Jeriko. 17 Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí Olúwa sì dúró ṣinṣin lórí ilẹ̀ gbígbẹ ní àárín Jordani, nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kọjá títí gbogbo orílẹ̀-èdè náà fi rékọjá nínú odò Jordani lórí ilẹ̀ gbígbẹ.

Read full chapter

49 “Gòkè lọ sí Abarimu sí òkè Nebo ní Moabu, tí ó kọjú sí Jeriko, kí o sì wo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí mo ń fi fún àwọn ọmọ Israẹli, bí ìní i wọn.

Read full chapter