Add parallel Print Page Options

Jobu ráhùn sí Ọlọ́run

Ẹ̀yìn èyí ní Jobu yanu, ó sì fi ọjọ́ ìbí rẹ̀ ré Jobu sọ, ó sì wí pé:

(A)“Kí ọjọ́ tí a bí mi kí ó di ìgbàgbé,
    àti òru ni, nínú èyí tí a wí pé, ‘A lóyún ọmọkùnrin kan!’
Kí ọjọ́ náà kí ó já si òkùnkùn,
    kí Ọlọ́run kí ó má ṣe kà á sí láti ọ̀run wá;
    bẹ́ẹ̀ ni kí ìmọ́lẹ̀ kí ó má ṣe mọ́ sí i.
Kí òkùnkùn àti òjìji ikú fi ṣe ti ara wọn;
    kí àwọsánmọ̀ kí ó bà lé e;
    kí ìṣúdudu ọjọ́ kí ó pa láyà.
Kí òkùnkùn kí ó ṣú bo òru náà biribiri,
    kí ó má ṣe yọ pẹ̀lú ọjọ́ ọdún náà:
    kí a má ṣe kà a mọ́ iye ọjọ́ oṣù.
Kí òru náà kí ó yàgàn;
    kí ohun ayọ̀ kan kí ó má ṣe wọ inú rẹ̀ lọ.
Kí àwọn tí í fi ọjọ́ gégùn ún kí o fi gégùn ún,
    tí wọ́n mura tán láti ru Lefitani sókè.
Kí ìràwọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́ rẹ̀ kí ó ṣókùnkùn;
    kí ó má wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó máa mọ́ sí i,
    bẹ́ẹ̀ ni kí ó má ṣe rí àfẹ̀mọ́júmọ́
10 Nítorí tí kò sé ìlẹ̀kùn inú ìyá mi,
    láti pa ìbànújẹ́ rẹ́ ní ojú mi.

11 “Èéṣe tí èmi kò fi kú láti inú wá,
    tàbí tí èmi kò kú ní ìgbà tí mo ti inú jáde wá?
12 Èéṣe tí orúnkún wá pàdé mi,
    tàbí ọmú tí èmi yóò mu?
13 Ǹjẹ́ nísinsin yìí èmi ìbá ti dùbúlẹ̀ jẹ́ẹ́;
    èmi ìbá ti sùn, èmi ìbá ti sinmi
14 pẹ̀lú àwọn ọba àti ìgbìmọ̀ ayé
    tí wọ́n mọ ilé fún ara wọn wá dùbúlẹ̀ nínú ìsọdahoro.
15 Tàbí pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé
    tí ó ní wúrà, tí wọ́n sì fi fàdákà kun ilé wọn
16 Tàbí bí ọlẹ̀ tí a sin, èmi kì bá ti sí:
    bí ọmọ ìṣunú tí kò rí ìmọ́lẹ̀?
17 Níbẹ̀ ni ẹni búburú ṣíwọ́ ìyọnilẹ́nu,
    níbẹ̀ ni ẹni àárẹ̀ wà nínú ìsinmi.
18 Níbẹ̀ ni àwọn ìgbèkùn sinmi pọ̀,
    wọn kò gbóhùn amúnisìn mọ́.
19 Àti èwe àti àgbà wà níbẹ̀,
    ẹrú sì di òmìnira kúrò lọ́wọ́ olówó rẹ̀.

Jobu kígbe nínú ìrora rẹ̀

20 “Nítorí kí ni a ṣe fi ìmọ́lẹ̀ fún òtòṣì,
    àti ìyè fún ọlọ́kàn kíkorò,
21 tí wọ́n dúró de ikú, ṣùgbọ́n òun kò wá,
    tí wọ́n wá a jù ìṣúra tí a bò mọ́lẹ̀ pamọ́ lọ.
22 Ẹni tí ó yọ̀ gidigidi,
    tí inú wọ́n sì dùn nígbà tí wọ́n wá ibojì òkú rí?
23 Kí ni a fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹni
    tí ọ̀nà rẹ̀ fi ara pamọ́ fún,
    tí Ọlọ́run sì ṣọgbà dí mọ́ ká?
24 Nítorí pé èémí-ẹ̀dùn wà ṣáájú oúnjẹ mi;
    ìkérora mi sì tú jáde bí omi.
25 Nítorí pé ohun náà tí mo bẹ̀rù gidigidi ni ó dé bá mi yìí,
    àti ohun tí mo fòyà rẹ̀ bá mi ó sì ṣubú lù mí.
26 Èmi wà láìní àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ní ìsinmi;
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ni ìfàyàbalẹ̀, bí kò ṣe ìdààmú.”