Add parallel Print Page Options

Ọ̀rọ̀ Elifasi: Ọlọ́run kì í fi ìyà jẹ olódodo

Ìgbà náà ni Elifasi, ará Temani dáhùn wí pé:

“Bí àwa bá fi ẹnu lé e, láti bá ọ sọ̀rọ̀, ìwọ o ha banújẹ́?
    Ṣùgbọ́n ta ni ó lè pa ọ̀rọ̀ mọ́ ẹnu láìsọ?
Kíyèsi i, ìwọ sá ti kọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn,
    ìwọ ṣá ti mú ọwọ́ aláìlera le.
Ọ̀rọ̀ rẹ ti gbé àwọn tí ń ṣubú lọ dúró,
    ìwọ sì ti mú eékún àwọn tí ń wárìrì lera.
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó dé bá ọ, ó sì rẹ̀ ọ́, ó kọlù ọ́;
    ara rẹ kò lélẹ̀.
Ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ kò ha jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ
    àti ìdúró ọ̀nà rẹ kò ha sì jẹ́ ìrètí rẹ?

“Èmi bẹ̀ ọ́ rántí: Ta ni ó ṣègbé rí láìṣẹ̀?
    Tàbí níbo ni a gbé gé olódodo kúrò rí?
Àní bí èmi ti rí i pé, àwọn tí ń ṣe ìtulẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀,
    tí wọ́n sì fún irúgbìn ìwà búburú, wọn a sì ká èso rẹ̀ náà.
Nípa ìfẹ́ sí Ọlọ́run wọn a ṣègbé,
    nípa èémí ìbínú rẹ̀ wọn a parun.
10 Bíbú ramúramù kìnnìún àti ohùn òǹrorò kìnnìún
    àti eyín àwọn ẹgbọrọ kìnnìún ní a ká.
11 Kìnnìún kígbe, nítorí àìrí ohun ọdẹ,
    àwọn ẹgbọrọ kìnnìún sísanra ni a túká kiri.

12 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí a fi ohun àṣírí kan hàn fún mi,
    etí mi sì gbà díẹ̀ nínú rẹ̀.
13 Ní ìrò inú lójú ìran òru,
    nígbà tí oorun èjìká kùn ènìyàn.
14 Ẹ̀rù bà mí àti ìwárìrì
    tí ó mú gbogbo egungun mi jí pépé.
15 Nígbà náà ni ẹ̀mí kan kọjá lọ ní iwájú mi,
    irun ara mi dìde dúró ṣánṣán.
16 Ó dúró jẹ́ẹ́,
    ṣùgbọ́n èmi kò le wo àpẹẹrẹ ìrí rẹ̀,
àwòrán kan hàn níwájú mi,
    ìdákẹ́rọ́rọ́ wà, mo sì gbóhùn kan wí pé:
17 ‘Ẹni kíkú le jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run,
    ènìyàn ha le mọ́ ju Ẹlẹ́dàá rẹ̀ bí?
18 Kíyèsi i, òun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,
    nínú àwọn angẹli rẹ̀ ní ó sì rí ẹ̀ṣẹ̀.
19 Mélòó mélòó àwọn tí ń gbé inú ilé amọ̀,
    ẹni tí ìpìlẹ̀ wọ́n jásí erùpẹ̀
    tí yóò di rírun kòkòrò.
20 A pa wọ́n run láàrín òwúrọ̀ àti àṣálẹ́
    wọ́n sì parun títí láé, láìrí ẹni kà á sí.
21 A kò ha ké okùn iye wọ́n kúrò bí?
    Wọ́n kú, àní láìlọ́gbọ́n?’