Add parallel Print Page Options

10 (A)“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀ yálà nínú ìdílé Israẹli tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrín wọn: Èmi yóò bínú sí irú ẹni náà tí ó jẹ ẹ̀jẹ̀: èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 11 Nítorí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹ̀dá wà, èmi sì ti fi fún yín lórí pẹpẹ fún ètùtù ọkàn yín: nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni a fi ń ṣe ètùtù fún ẹ̀mí ènìyàn. 12 Ìdí nìyí tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ọ̀kankan nínú yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àlejò kan tí ń ṣe àtìpó nínú yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.

13 “ ‘Ẹnikẹ́ni yálà nínú àwọn ọmọ Israẹli tàbí àlejò tí ń gbé láàrín wọn, tí ó bá pa ẹranko tàbí ẹyẹ tí ó yẹ fún jíjẹ gbọdọ̀ ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì bò ó mọ́lẹ̀. 14 Torí pé ẹ̀mí gbogbo ẹ̀dá ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, torí náà ni mo fi kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí kankan: torí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí wọ̀nyí ni ẹ̀mí wọn wà: ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó gé kúrò.

Read full chapter

26 (A)“ ‘Ẹ má ṣe jẹ ẹrankẹ́ran pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

“ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ yẹ̀míwò tàbí oṣó.

Read full chapter