Add parallel Print Page Options

22 Olúwa sọ fún Mose pé, “Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ kí wọ́n fi ọ̀wọ̀ fún ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli yà sọ́tọ̀ fún mi, kí wọ́n má ba à ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Èmi ni Olúwa.

“Sọ fún wọn pé: ‘Fún àwọn ìran tí ń bọ̀. Bí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ yín tí kò mọ́ bá wá sí ibi ọrẹ mímọ́ tí àwọn ara Israẹli ti yà sọ́tọ̀ fún Olúwa, kí ẹ yọ ẹni náà kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà ní iwájú mi. Èmi ni Olúwa.

“ ‘Bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Aaroni bá ní ààrùn ara tí ń ran ni, tàbí ìtújáde nínú ara. Ó lè má jẹ ọrẹ mímọ́ náà títí di ìgbà tí a ó fi wẹ̀ ẹ́ mọ́. Òun tún lè di aláìmọ́ bí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí òkú nǹkan bá sọ di àìmọ́ tàbí bí ó bá farakan ẹnikẹ́ni tí ó ní ìtújáde. Tàbí bí ó bá fọwọ́ kan èyíkéyìí nínú ohun tí ń rákò, tí ó sọ ọ́ di aláìmọ́, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó sọ ọ́ di àìmọ́, ohunkóhun yówù kí àìmọ́ náà jẹ́. Ẹni náà tí ó fọwọ́ kan irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Kò gbọdọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú ọrẹ mímọ́ àyàfi bí ó bá wẹ ara rẹ̀. Bí oòrùn bá wọ̀, ẹni náà di mímọ́, lẹ́yìn náà ni ó tó le jẹ ọrẹ mímọ́, torí pé wọ́n jẹ́ oúnjẹ rẹ̀. Kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó bá ti kú sílẹ̀, tàbí tí ẹranko fàya, kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di aláìmọ́. Èmi ni Olúwa.

“ ‘Kí àwọn àlùfáà pa ìlànà mi mọ́, kí wọn má ba à jẹ̀bi, kí wọn sì kú nítorí pé wọ́n ṣe ọrẹ wọ̀nyí pẹ̀lú fífojútẹ́ńbẹ́lú wọn. Èmi ni Olúwa tí ó sọ wọ́n di mímọ́.

10 “ ‘Kò sí ẹnikẹ́ni lẹ́yìn ìdílé àlùfáà tí ó le jẹ ọrẹ mímọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni, àlejò àlùfáà tàbí alágbàṣe rẹ̀ kò le jẹ ẹ́. 11 Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá ra ẹrú, pẹ̀lú owó, tàbí tí a bí ẹrú kan nínú ìdílé rẹ̀, ẹrú náà lè jẹ oúnjẹ rẹ̀. 12 (A)Bí ọmọbìnrin àlùfáà bá fẹ́ ẹni tí kì í ṣe àlùfáà, kò gbọdọ̀ jẹ nínú èyíkéyìí nínú ohun ọrẹ mímọ́. 13 Ṣùgbọ́n bí ọmọbìnrin àlùfáà bá jẹ́ opó tàbí tí a ti kọ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò lọ́mọ tí ó sì padà sínú ilé baba rẹ̀ láti máa gbé bẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀, ó le jẹ oúnjẹ baba rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, àlejò tí kò lẹ́tọ̀ọ́ (láṣẹ) kò gbọdọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú oúnjẹ náà.

14 “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì jẹ ọrẹ mímọ́ kan, ó gbọdọ̀ ṣe àtúnṣe lórí ẹbọ náà fún àlùfáà, kí ó sì fi ìdámárùn-ún ohun tí ọrẹ náà jẹ́ kún un. 15 Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ sọ ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli mú wá síwájú Olúwa di àìmọ́. 16 Nípa fífi ààyè fún wọn láti jẹ ọrẹ mímọ́ náà, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ẹ̀bi tí wọn yóò san nǹkan fún wá sórí wọn. Èmi ni Olúwa, tí ó sọ wọ́n di mímọ́.’ ”

Àwọn ọrẹ ẹbọ tí kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà

17 Olúwa sọ fún Mose pé, 18 “Sọ fún Aaroni, àwọn ọmọ rẹ̀ àti fún gbogbo Israẹli kí o sì wí fún wọn pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni nínú yín yálà ọmọ Israẹli ni tàbí àlejò tí ń gbé ní Israẹli bá mú ẹ̀bùn wá fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa, yálà láti san ẹ̀jẹ́ tàbí ọrẹ àtinúwá. 19 Ẹ gbọdọ̀ mú akọ láìní àbùkù láti ara màlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́, kí ó ba à lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín. 20 Ẹ má ṣe mú ohunkóhun tí ó ní àbùkù wá, torí pé kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín. 21 Bí ẹnikẹ́ni bá mú ọrẹ àlàáfíà wá láti inú agbo màlúù tàbí ti àgùntàn, fún Olúwa láti san ẹ̀jẹ́ pàtàkì tàbí fún ọrẹ àtinúwá. Ó gbọdọ̀ jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà láìní àbùkù. 22 Ẹ má ṣe fi ẹranko tí ó fọ́jú, tí ó fi ara pa, tí ó yarọ, tí ó ní kókó, tí ó ní èkúkú, èépá àti egbò kíkẹ̀ rú ẹbọ sí Olúwa. Ẹ kò gbọdọ̀ gbé èyíkéyìí nínú wọn sórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bi ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa. 23 Ẹ le mú màlúù tàbí àgùntàn tí ó ní àbùkù tàbí tí ó yọ iké wá fún ọrẹ àtinúwá, ṣùgbọ́n kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọrẹ ẹ̀jẹ́. 24 Ẹ má ṣe fi ẹranko tí kóró ẹpọ̀n rẹ̀ fọ́ tàbí tí a tẹ̀, tàbí tí a yà tàbí tí a là rú ẹbọ sí Olúwa. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí ní ilẹ̀ yín. 25 Ẹ kò gbọdọ̀ gba irú ẹranko bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àlejò kankan láti fi rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ sí Ọlọ́run yín. A kò nígbà wọ́n fún yín nítorí pé wọ́n ní àbùkù, wọ́n sì díbàjẹ́.’ ”

26 Olúwa sọ fún Mose pé, 27 “Nígbà tí màlúù bá bímọ, tí àgùntàn bímọ, tí ewúrẹ́ sì bímọ, ọmọ náà gbọdọ̀ wà pẹ̀lú ìyá rẹ̀ fún ọjọ́ méje. Láti ọjọ́ kẹjọ ni ó ti di ìtẹ́wọ́gbà fún ọrẹ àfinásun sí Olúwa. 28 Ẹ má ṣe pa màlúù àti ọmọ rẹ̀ tàbí àgùntàn àti ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà.

29 “Nígbà tí ẹ bá rú ẹbọ ọpẹ́ sí Olúwa, ẹ rú u ní ọ̀nà tí yóò fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín. 30 Ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ọjọ́ náà gan an: Ẹ má ṣe ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀. Èmi ni Olúwa.

31 “Ẹ pa òfin mi mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n. Èmi ni Olúwa. 32 Ẹ má ṣe ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Àwọn ọmọ Israẹli gbọdọ̀ mọ̀ mí ní mímọ́. Èmi ni Olúwa tí ó sọ yín di mímọ́. 33 Tí ó sì mú yín jáde láti Ejibiti wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín. Èmi ni Olúwa.”

22 The Lord said to Moses, “Tell Aaron and his sons to treat with respect the sacred offerings(A) the Israelites consecrate to me, so they will not profane my holy name.(B) I am the Lord.(C)

“Say to them: ‘For the generations to come, if any of your descendants is ceremonially unclean and yet comes near the sacred offerings that the Israelites consecrate to the Lord,(D) that person must be cut off from my presence.(E) I am the Lord.

“‘If a descendant of Aaron has a defiling skin disease[a] or a bodily discharge,(F) he may not eat the sacred offerings until he is cleansed. He will also be unclean if he touches something defiled by a corpse(G) or by anyone who has an emission of semen, or if he touches any crawling thing(H) that makes him unclean, or any person(I) who makes him unclean, whatever the uncleanness may be. The one who touches any such thing will be unclean(J) till evening.(K) He must not eat any of the sacred offerings unless he has bathed himself with water.(L) When the sun goes down, he will be clean, and after that he may eat the sacred offerings, for they are his food.(M) He must not eat anything found dead(N) or torn by wild animals,(O) and so become unclean(P) through it. I am the Lord.(Q)

“‘The priests are to perform my service(R) in such a way that they do not become guilty(S) and die(T) for treating it with contempt. I am the Lord, who makes them holy.(U)

10 “‘No one outside a priest’s family may eat the sacred offering, nor may the guest of a priest or his hired worker eat it.(V) 11 But if a priest buys a slave with money, or if slaves are born in his household, they may eat his food.(W) 12 If a priest’s daughter marries anyone other than a priest, she may not eat any of the sacred contributions. 13 But if a priest’s daughter becomes a widow or is divorced, yet has no children, and she returns to live in her father’s household as in her youth, she may eat her father’s food. No unauthorized person, however, may eat it.

14 “‘Anyone who eats a sacred offering by mistake(X) must make restitution to the priest for the offering and add a fifth of the value(Y) to it. 15 The priests must not desecrate the sacred offerings(Z) the Israelites present to the Lord(AA) 16 by allowing them to eat(AB) the sacred offerings and so bring upon them guilt(AC) requiring payment.(AD) I am the Lord, who makes them holy.(AE)’”

Unacceptable Sacrifices

17 The Lord said to Moses, 18 “Speak to Aaron and his sons and to all the Israelites and say to them: ‘If any of you—whether an Israelite or a foreigner residing in Israel(AF)—presents a gift(AG) for a burnt offering to the Lord, either to fulfill a vow(AH) or as a freewill offering,(AI) 19 you must present a male without defect(AJ) from the cattle, sheep or goats in order that it may be accepted on your behalf.(AK) 20 Do not bring anything with a defect,(AL) because it will not be accepted on your behalf.(AM) 21 When anyone brings from the herd or flock(AN) a fellowship offering(AO) to the Lord to fulfill a special vow or as a freewill offering,(AP) it must be without defect or blemish(AQ) to be acceptable.(AR) 22 Do not offer to the Lord the blind, the injured or the maimed, or anything with warts or festering or running sores. Do not place any of these on the altar as a food offering presented to the Lord. 23 You may, however, present as a freewill offering an ox[b] or a sheep that is deformed or stunted, but it will not be accepted in fulfillment of a vow. 24 You must not offer to the Lord an animal whose testicles are bruised, crushed, torn or cut.(AS) You must not do this in your own land, 25 and you must not accept such animals from the hand of a foreigner and offer them as the food of your God.(AT) They will not be accepted on your behalf, because they are deformed and have defects.(AU)’”

26 The Lord said to Moses, 27 “When a calf, a lamb or a goat(AV) is born, it is to remain with its mother for seven days.(AW) From the eighth day(AX) on, it will be acceptable(AY) as a food offering presented to the Lord. 28 Do not slaughter a cow or a sheep and its young on the same day.(AZ)

29 “When you sacrifice a thank offering(BA) to the Lord, sacrifice it in such a way that it will be accepted on your behalf. 30 It must be eaten that same day; leave none of it till morning.(BB) I am the Lord.(BC)

31 “Keep(BD) my commands and follow them.(BE) I am the Lord. 32 Do not profane my holy name,(BF) for I must be acknowledged as holy by the Israelites.(BG) I am the Lord, who made you holy(BH) 33 and who brought you out of Egypt(BI) to be your God.(BJ) I am the Lord.”

Footnotes

  1. Leviticus 22:4 The Hebrew word for defiling skin disease, traditionally translated “leprosy,” was used for various diseases affecting the skin.
  2. Leviticus 22:23 The Hebrew word can refer to either male or female.