Lefitiku 25:36
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
36 (A)Ẹ kò gbọdọ̀ gba èlé kankan lọ́wọ́ rẹ̀: ẹ bẹ̀rù Olúwa kí arákùnrin yín le è máa gbé láàrín yín.
Read full chapter
Lefitiku 25:37
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
37 Ẹ má ṣe gba èlé lórí owó tí ẹ yá a bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ èrè lórí oúnjẹ tí ẹ tà fún un.
Read full chapter
Deuteronomi 23:19
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
19 (A)Ìwọ kò gbọdọ̀ ka èlé sí arákùnrin rẹ lọ́rùn, bóyá lórí owó tàbí oúnjẹ tàbí ohunkóhun mìíràn tí ó lè mú èlé wá.
Read full chapter
Deuteronomi 23:20
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
20 Ìwọ lè ka èlé sí àlejò lọ́rùn, ṣùgbọ́n kì í ṣe arákùnrin ọmọ Israẹli, nítorí kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún ọ nínú ohun gbogbo tí o bá dáwọ́lé ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.