Add parallel Print Page Options

(A)(B) “Èmí sì wí fún yín, ẹ béèrè, a ó sì fi fún un yín; ẹ wá kiri, ẹ̀yin ó sì rí; ẹ kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín. 10 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá béèrè, ó rí gbà; ẹni tí ó sì ń wá kiri, ó rí; àti ẹni tí ó kànkùn ni a ó ṣí i sílẹ̀ fún.

11 “Ta ni baba nínú yín tí ọmọ rẹ̀ yóò béèrè àkàrà lọ́dọ̀ rẹ̀, tí yóò fún un ní òkúta? Tàbí bí ó béèrè ẹja, tí yóò fún un ní ejò? 12 Tàbí bí ó sì béèrè ẹ̀yin, tí yóò fún un ní àkéekèe? 13 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí ó jẹ́ ènìyàn búburú bá mọ bí a ti í fi ẹ̀bùn dáradára fún àwọn ọmọ yín: mélòó mélòó ha ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fún àwọn tí ó béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀!”

Read full chapter

24 (A)Torí náà, mo wí fún yín ohunkóhun tí ẹ bá béèrè fún nínú àdúrà, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé, ó tí tẹ̀ yín lọ́wọ́, yóò sì jẹ́ tiyín.

Read full chapter

(A)Bí ẹ̀yin bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi bá sì gbé inú yín, ẹ ó béèrè ohunkóhun tí ẹ bá fẹ́, a ó sì ṣe é fún yín.

Read full chapter

23 Àti ní ọjọ́ náà ẹ̀yin kì ó bi mí lérè ohunkóhun. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, òhun ó fi fún yín. 24 (A)Títí di ìsinsin yìí ẹ kò tí ì béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi: ẹ béèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí ayọ̀ yín kí ó lè kún.

Read full chapter

Ẹ̀yin béèrè, ẹ kò sì rí gbà, nítorí tí ẹ̀yin ṣì béèrè, kí ẹ̀yin kí ó lè lò ó fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín.

Read full chapter

22 Àti ohunkóhun tí àwa bá béèrè, ni àwa ń rí gbà lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí tí àwa ń pa òfin rẹ̀ mọ́, àwa sì ń ṣe àwọn nǹkan tí ó dára lójú rẹ̀.

Read full chapter

14 (A)Èyí sì ni ìgboyà tí àwa ní níwájú rẹ̀, pé bí àwa bá béèrè ohunkóhun gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tí wa;

Read full chapter