Add parallel Print Page Options

Ìpinnu láti tọ Jesu lẹ́yìn

57 (A)Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ọkùnrin kan wí fún un pé, “Olúwa, Èmi ń fẹ́ láti máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

58 Jesu sì wí fún un pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́; ṣùgbọ́n ọmọ ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”

59 Ó sì wí fún ẹlòmíràn pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

Ṣùgbọ́n èyí wí fún un pé, “Olúwa, jẹ́ kí èmi lọ sìnkú baba mi ná.”

60 Jesu sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn òkú máa sìnkú ara wọn: ṣùgbọ́n ìwọ lọ kí o sì máa wàásù ìjọba Ọlọ́run.”

Read full chapter

Jesu mú afẹ́fẹ́ okun dákẹ́ jẹ́ẹ́

35 (A)Nígbà tí alẹ́ lẹ́, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a rékọjá sí apá kejì.”

Read full chapter

Jesu bá rírú omi okun wí

22 (A)Ní ọjọ́ kan, ó sì wọ ọkọ̀ ojú omi kan lọ òun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. O sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a rékọjá lọ sí ìhà kejì adágún.” Wọ́n sì ṣíkọ̀ láti lọ.

Read full chapter