Add parallel Print Page Options

Jesu àti àwọn ọmọdé

13 (A)Lẹ́yìn èyí, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tọ Jesu wá kí ó lè súre fún wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kígbe mọ́ àwọn tí ń gbé àwọn ọmọdé wọ̀nyí bọ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ yọ Jesu lẹ́nu rárá. 14 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu rí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, inú rẹ̀ kò dùn sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Nítorí náà, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé kékeré wá sọ́dọ̀ mi. Ẹ má ṣe dá wọn lẹ́kun nítorí pé irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run. 15 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò le è wọ inú rẹ̀.” 16 (B)Nígbà náà, Jesu gbé àwọn ọmọ náà lé ọwọ́ rẹ̀, ó gbé ọwọ́ lé orí wọn. Ó sì súre fún wọn.

Read full chapter

Àwọn ọmọdé àti Jesu

15 (A)Wọ́n sì gbé àwọn ọmọ ọwọ́ tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí i, wọ́n ń bá wọn wí. 16 Ṣùgbọ́n Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun: nítorí tí irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run. 17 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbà ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò wọ inú rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí.”

Read full chapter

Jesu sì pe ọmọ kékeré kan sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀. Ó sì mú un dúró láàrín wọn. (A)Ó wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àfi bí ẹ̀yin bá yí padà kí ẹ sì dàbí àwọn ọmọdé, ẹ̀yin kì yóò lè wọ ìjọba ọ̀run.

Read full chapter

20 (A)Ará, ẹ má ṣe jẹ ọmọdé ni òye, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ọmọdé ní àrankàn, ṣùgbọ́n ni òye ẹ jẹ́ àgbà.

Read full chapter