Add parallel Print Page Options

10 (A)Nígbà náà ni Judasi Iskariotu, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, láti ṣètò bí yóò ti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́. 11 Inú wọn dùn láti gbọ́ èyí, wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì ṣe ìlérí láti fún un ní owó. Nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ àkókò tí ó rọrùn tí òun yóò fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.

Read full chapter

Satani sì wọ inú Judasi, tí à ń pè ní Iskariotu, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá. Ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, ó lọ láti bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ gbèrò pọ̀, bí òun yóò tí fi í lé wọn lọ́wọ́. (A)Wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì bá a dá májẹ̀mú láti fún un ní owó. Ó sì gbà; ó sì ń wá àkókò tí ó wọ̀, láti fi í lé wọn lọ́wọ́ láìsí ariwo.

Read full chapter