Add parallel Print Page Options

Ọgbà Getsemane

32 (A)Nígbà tí wọ́n dé ibi kan tí wọ́n ń pè ní ọgbà Getsemane. Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jókòó dè mí níhìn-ín títí n ó fi lọ gbàdúrà.” 33 Ó sì mú Peteru àti Jakọbu àti Johanu lọ pẹ̀lú rẹ̀. Òun sì kún fún ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbànújẹ́ gidigidi. 34 (B)Ó sì wí fún wọn pé, “ọkàn mi ń káàánú gidigidi títí dé ojú ikú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ sì máa bá mi ṣọ́nà.”

35 Ó sì lọ síwájú díẹ̀, ó dojúbo ilẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i gbàdúrà pé, bí ó bá ṣe e ṣe kí wákàtí tí ó bọ̀ náà ré òun kọjá. 36 (C)Ó sì wí pé, “Ábbà, Baba, ìwọ lè ṣe ohun gbogbo, mú ago yìí kúrò lórí mi, ṣùgbọ́n kì í ṣe èyí tí èmi fẹ́, bí kò ṣe èyí tí ìwọ fẹ́.”

37 Nígbà tí ó sì padà dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́ta, ó bá wọn lójú oorun. Ó sì wí fún Peteru pé, “Simoni, o ń sùn ni? Ìwọ kò lè bá mi ṣọ́nà fún wákàtí kan? 38 (D)Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà, ki ẹ má ba à bọ́ sínú ìdánwò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ‘Ẹ̀mí ń fẹ́ ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.’ ”

39 Ó sì tún lọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó sì gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti gbà á ti ìṣáájú. 40 Nígbà tí ó sì tún padà dé, ó bá wọn wọ́n ń sùn, nítorí pé ojú wọn kún fún oorun. Wọn kò sì mọ irú èsì tí wọn ìbá fún un.

41 Ó sì wá nígbà kẹta, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa sùn kí ẹ sì máa sinmi ó tó bẹ́ẹ̀, wákàtí náà ti dé, wò ó, a fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. 42 Ẹ dìde, Ẹ jẹ́ kí a máa lọ. Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mí hàn wà ní tòsí!”

Read full chapter

40 (A)(B)Nígbà tí ó wà níbẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.” 41 Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níwọ̀n ìsọ-òkò kan, ó sì kúnlẹ̀ ó sì ń gbàdúrà. 42 (C)Wí pé, “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, mu ago yìí kúrò lọ́dọ́ mi: ṣùgbọ́n ìfẹ́ ti èmi kọ́, bí kò ṣe tìrẹ ni kí à ṣe.” 43 Angẹli kan sì yọ sí i láti ọ̀run wá, ó ń gbà á ní ìyànjú. 44 Bí ó sì ti wà nínú gbígbóná ara ó ń gbàdúrà sí i kíkankíkan; òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ó ń kán sílẹ̀.

45 Nígbà tí ó sì dìde kúrò ní ibi àdúrà, tí ó sì tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó bá wọn, wọ́n ń sùn nítorí ìbànújẹ́ ti mu kí ó rẹ̀ wọ́n. 46 Ó sì wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ yin ń sùn sí? Ẹ dìde, ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.”

Read full chapter