Add parallel Print Page Options

22 (A)Wọ́n sì mú Jesu wá sí Gọlgọta, (èyí tí ìtumọ̀ rẹ̀ ń jẹ́ Ibi Agbárí) 23 Wọ́n sì fi (myrri) wáìnì tí a dàpọ̀ mọ́ òjìá fún un mu, ṣùgbọ́n òun kò gbà á. 24 (B)Wọ́n sì kàn án mọ́ àgbélébùú. Wọ́n sì pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn, wọ́n dìbò lórí àwọn aṣọ náà ni kí wọn bá à lè mọ èyí tí yóò jẹ́ ti olúkúlùkù.

25 Ní wákàtí kẹta ọjọ́ ni wọ́n kàn án mọ́ àgbélébùú. 26 Àkọlé ìfisùn tí wọ́n kọ sókè orí rẹ̀ ni:

ọba àwọn júù.

27 Wọ́n sì kan àwọn olè méjì mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kan lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀, èkejì lọ́wọ́ òsì rẹ̀. 28 Eléyìí mú àsọtẹ́lẹ̀ ìwé Mímọ́ ṣẹ wí pé, “Wọ́n kà á pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn búburú.” 29 (C)Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n ń mi orí wọn pẹ̀lú, wọ́n sì ké pé, “Háà! Ìwọ tí yóò wó tẹmpili tí yóò sì tún un kọ́ láàrín ọjọ́ mẹ́ta, 30 sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú wá, kí o sì gba ara rẹ là!” 31 (D)Bákan náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin fi í ṣẹ̀sín láàrín ara wọn, wọ́n wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là ṣùgbọ́n, ara rẹ̀ ni kò lè gbàlà. 32 Jẹ́ kí Kristi, ọba Israẹli, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú wá nísinsin yìí kí àwa kí ó lè rí i, kí àwa kí ó sì lè gbàgbọ́.” Bákan náà, àwọn ti a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ sì ń kẹ́gàn rẹ̀.

Read full chapter

33 (A)Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí a ń pè ní Agbárí, níbẹ̀ ni wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn arúfin náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti ọ̀kan ní ọwọ́ òsì. 34 (B)Jesu sì wí pé, “Baba, dáríjì wọ́n; nítorí tí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” Wọ́n di ìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn.

35 (C)Àwọn ènìyàn sì dúró láti wòran. Àti àwọn ìjòyè pẹ̀lú wọn, wọ́n ń yọ ṣùtì sí i, wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kí ó gbara rẹ̀ là, bí ó bá ṣe Kristi, àyànfẹ́ Ọlọ́run.”

36 (D)Àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ń fi ọtí kíkan fún un. 37 Wọ́n sì ń wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe ọba àwọn Júù, gba ara rẹ là.”

38 Wọ́n sì kọ̀wé àkọlé sí ìgbèrí rẹ̀ ní èdè Giriki, àti ti Latin, àti tí Heberu pe:

èyí ni ọba àwọn júù.

39 Àti ọ̀kan nínú àwọn arúfin tí a gbé kọ́ ń fi ṣe ẹlẹ́yà wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Kristi, gba ara rẹ àti àwa náà là.”

Read full chapter

17 (A)Nítorí náà, wọ́n mú Jesu, ó sì jáde lọ, ó ru àgbélébùú fúnrarẹ̀ sí ibi tí à ń pè ní ibi agbárí, ní èdè Heberu tí à ń pè ní Gọlgọta: 18 Níbi tí wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn méjì mìíràn pẹ̀lú rẹ̀, níhà ìhín àti níhà kejì, Jesu sì wà láàrín.

19 Pilatu sì kọ ìwé kan pẹ̀lú, ó sì fi lé e lórí àgbélébùú náà. Ohun tí a sì kọ ni,

jesu ti nasareti ọba àwọn júù.

20 Nítorí náà, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni ó ka ìwé àkọlé yìí: nítorí ibi tí a gbé kan Jesu mọ́ àgbélébùú súnmọ́ etí ìlú: a sì kọ ọ́ ní èdè Heberu àti Latin, àti ti Giriki. 21 Nítorí náà àwọn olórí àlùfáà àwọn Júù wí fún Pilatu pé, “Má ṣe kọ, ‘ọba àwọn Júù;’ ṣùgbọ́n pé ọkùnrin yìí wí pé, èmi ni ọba àwọn Júù.”

22 Pilatu dáhùn pé, ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́.

23 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun, nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ àgbélébùú tán, wọ́n mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì pín wọn sí ipa mẹ́rin, apá kan fún ọmọ-ogun kọ̀ọ̀kan, àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀: ṣùgbọ́n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà kò ní ojúràn-án, wọ́n hun ún láti òkè títí jálẹ̀.

24 (B)Nítorí náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ẹ má jẹ́ kí a fà á ya, ṣùgbọ́n kí a ṣẹ́ gègé nítorí rẹ̀.”

Ti ẹni tí yóò jẹ́: kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ, tí ó wí pé,

“Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn,
    wọ́n sì ṣẹ́ gègé fún aṣọ ìlekè mi.”

Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọmọ-ogun ṣe.

Read full chapter