Add parallel Print Page Options

A bẹ́ Johanu onítẹ̀bọmi lórí

14 (A)Láìpẹ́, ọba Herodu gbọ́ nípa Jesu, nítorí níbi gbogbo ni a ti ń sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Ọba náà rò pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi jíǹde kúrò nínú òkú, nítorí náà ni iṣẹ́ ìyanu ṣe ń ṣe láti ọwọ́ rẹ.”

15 Àwọn mìíràn wí pé, “Elijah ní.”

Àwọn mìíràn wí pé, “Wòlíì bí ọ̀kan lára àwọn àtijọ́ tó ti kú ló tún padà sáyé.”

16 Ṣùgbọ́n nígbà tí Herodu gbọ́ èyí, ó wí pé “Johanu tí mo tí bẹ́ lórí ni ó ti jíǹde kúrò nínú òkú.”

Read full chapter

(A)Herodu tetrarki gbọ́ nǹkan gbogbo èyí tí a ṣe láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá: ó sì dààmú, nítorí tí àwọn ẹlòmíràn ń wí pé, Johanu ni ó jíǹde kúrò nínú òkú; Àwọn ẹlòmíràn sì wí pé Elijah ni ó farahàn; àwọn ẹlòmíràn sì wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde. (B)Herodu sì wí pé, “Johanu ni mo ti bẹ́ lórí: ṣùgbọ́n ta ni èyí tí èmi ń gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí sí?” Ó sì ń fẹ́ láti rí i.

Read full chapter

28 (A)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà dáhùn pé, “Àwọn kan rò pé ìwọ ni Johanu Onítẹ̀bọmi, àwọn mìíràn sọ pé, ìwọ ni Elijah tàbí àwọn wòlíì mìíràn ni ó tún padà wá sáyé.”

Read full chapter